Jẹ́nẹ́sísì 11:1-32
11 Èdè kan ni gbogbo ayé ń sọ, wọ́n sì ń lo àwọn ọ̀rọ̀ kan náà.*
2 Bí wọ́n ṣe ń rìnrìn àjò lọ sí apá ìlà oòrùn, wọ́n rí pẹ̀tẹ́lẹ̀ kan ní ilẹ̀ Ṣínárì,+ wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí í gbé ibẹ̀.
3 Wọ́n wá sọ fún ara wọn pé: “Ó yá! Ẹ jẹ́ ká mọ bíríkì, ká fi sínú iná.” Torí náà, wọ́n lo bíríkì dípò òkúta, wọ́n sì fi ọ̀dà bítúmẹ́nì ṣe àpòrọ́.
4 Wọ́n wá sọ pé: “Ó yá! Ẹ jẹ́ ká kọ́ ìlú kan fún ara wa, ká kọ́ ilé gogoro tó ga dé ọ̀run, ká mú kí orúkọ wa lókìkí, ká má bàa tú ká sí gbogbo ayé.”+
5 Ni Jèhófà bá lọ wo ìlú náà àti ilé gogoro tí àwọn ọmọ èèyàn kọ́.
6 Jèhófà sì sọ pé: “Wò ó! Èèyàn kan ni wọ́n, èdè kan+ ni wọ́n ń sọ, ohun tí wọ́n sì dáwọ́ lé nìyí. Kò ní sí ohun tí wọ́n ní lọ́kàn tí kò ní ṣeé ṣe fún wọn.
7 Wá! Jẹ́ ká+ lọ síbẹ̀ ká sì da èdè wọn rú, kí wọ́n má bàa gbọ́ èdè ara wọn mọ́.”
8 Torí náà, Jèhófà tú wọn ká láti ibẹ̀ lọ sí gbogbo ayé,+ kẹ̀rẹ̀kẹ̀rẹ̀, wọ́n fi ìlú tí wọ́n ń kọ́ sílẹ̀.
9 Ìdí nìyẹn tí wọ́n fi ń pe ibẹ̀ ní Bábélì,*+ torí ibẹ̀ ni Jèhófà ti da èdè gbogbo ayé rú, ibẹ̀ sì ni Jèhófà ti tú wọn ká sí gbogbo ayé.
10 Ìtàn Ṣémù+ nìyí.
Ẹni ọgọ́rùn-ún (100) ọdún ni Ṣémù nígbà tó bí Ápákíṣádì+ ní ọdún kejì lẹ́yìn Ìkún Omi.
11 Lẹ́yìn tó bí Ápákíṣádì, Ṣémù tún lo ọgọ́rùn-ún márùn-ún (500) ọdún. Ó sì bí àwọn ọmọ lọ́kùnrin àti lóbìnrin.+
12 Ápákíṣádì pé ẹni ọdún márùndínlógójì (35), ó wá bí Ṣélà.+
13 Lẹ́yìn tó bí Ṣélà, Ápákíṣádì tún lo ọgọ́rùn-ún mẹ́rin ọdún ó lé mẹ́ta (403). Ó sì bí àwọn ọmọ lọ́kùnrin àti lóbìnrin.
14 Ṣélà pé ẹni ọgbọ̀n (30) ọdún, ó wá bí Ébérì.+
15 Lẹ́yìn tó bí Ébérì, Ṣélà tún lo ọgọ́rùn-ún mẹ́rin ọdún ó lé mẹ́ta (403). Ó sì bí àwọn ọmọ lọ́kùnrin àti lóbìnrin.
16 Ébérì pé ẹni ọdún mẹ́rìnlélọ́gbọ̀n (34), ó wá bí Pélégì.+
17 Lẹ́yìn tó bí Pélégì, Ébérì tún lo ọgọ́rùn-ún mẹ́rin ó lé ọgbọ̀n (430) ọdún. Ó sì bí àwọn ọmọ lọ́kùnrin àti lóbìnrin.
18 Pélégì pé ẹni ọgbọ̀n (30) ọdún, ó wá bí Réù.+
19 Lẹ́yìn tó bí Réù, Pélégì tún lo igba ọdún ó lé mẹ́sàn-án (209). Ó sì bí àwọn ọmọ lọ́kùnrin àti lóbìnrin.
20 Réù pé ẹni ọdún méjìlélọ́gbọ̀n (32), ó wá bí Sérúgù.
21 Lẹ́yìn tó bí Sérúgù, Réù tún lo igba ọdún ó lé méje (207). Ó sì bí àwọn ọmọ lọ́kùnrin àti lóbìnrin.
22 Sérúgù pé ẹni ọgbọ̀n (30) ọdún, ó wá bí Náhórì.
23 Lẹ́yìn tó bí Náhórì, Sérúgù tún lo igba (200) ọdún. Ó sì bí àwọn ọmọ lọ́kùnrin àti lóbìnrin.
24 Náhórì pé ẹni ọdún mọ́kàndínlọ́gbọ̀n (29), ó wá bí Térà.+
25 Lẹ́yìn tó bí Térà, Náhórì tún lo ọdún mọ́kàndínlọ́gọ́fà (119). Ó sì bí àwọn ọmọ lọ́kùnrin àti lóbìnrin.
26 Térà pé ẹni àádọ́rin (70) ọdún, ó sì bí Ábúrámù,+ Náhórì+ àti Háránì.
27 Ìtàn Térà nìyí.
Térà bí Ábúrámù, Náhórì àti Háránì; Háránì sì bí Lọ́ọ̀tì.+
28 Háránì kú nígbà tí Térà bàbá rẹ̀ ṣì wà láàyè, ní ilẹ̀ tí wọ́n ti bí i, ní Úrì+ ti àwọn ará Kálídíà.+
29 Ábúrámù àti Náhórì fẹ́ ìyàwó. Orúkọ ìyàwó Ábúrámù ni Sáráì,+ orúkọ ìyàwó Náhórì sì ni Mílíkà,+ ọmọbìnrin Háránì, bàbá Mílíkà àti Ísíkà.
30 Àmọ́ àgàn+ ni Sáráì; kò ní ọmọ kankan.
31 Térà wá mú Ábúrámù ọmọ rẹ̀ àti Lọ́ọ̀tì tó jẹ́ ọmọ ọmọ rẹ̀,+ ọmọ Háránì, ó sì mú Sáráì, ìyàwó Ábúrámù ọmọ rẹ̀, wọ́n sì tẹ̀ lé e nígbà tó kúrò ní Úrì ti àwọn ará Kálídíà láti lọ sí ilẹ̀ Kénáánì.+ Nígbà tó yá, wọ́n dé Háránì,+ wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí í gbé ibẹ̀.
32 Gbogbo ọjọ́ ayé Térà jẹ́ igba ọdún ó lé márùn-ún (205). Térà wá kú ní Háránì.