Jẹ́nẹ́sísì 15:1-21
15 Lẹ́yìn èyí, Jèhófà sọ fún Ábúrámù nínú ìran pé: “Ábúrámù, má bẹ̀rù.+ Apata ni mo jẹ́ fún ọ.+ Èrè rẹ yóò pọ̀ gan-an.”+
2 Ábúrámù fèsì pé: “Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ, kí lo máa fún mi, bí o ṣe rí i pé mi ò tíì bímọ, tó sì jẹ́ pé Élíésérì,+ ọkùnrin ará Damásíkù ni yóò jogún ilé mi?”
3 Ábúrámù fi kún un pé: “O ò fún mi ní ọmọ,*+ ará* ilé mi ló sì máa jogún ohun tí mo ní.”
4 Àmọ́, èsì tí Jèhófà fún un ni pé: “Ọkùnrin yìí ò ní jogún rẹ, ọmọ rẹ* ni yóò jogún rẹ.”+
5 Ó wá mú un wá sí ìta, ó sì sọ pé: “Jọ̀ọ́, gbójú sókè wo ọ̀run, kí o sì ka àwọn ìràwọ̀, tí o bá lè kà á.” Ó sì sọ fún un pé: “Bí ọmọ* rẹ á ṣe pọ̀ nìyẹn.”+
6 Ábúrámù ní ìgbàgbọ́ nínú Jèhófà,+ Ó sì kà á sí òdodo fún un.+
7 Ó wá fi kún un pé: “Èmi ni Jèhófà, ẹni tó mú ọ kúrò ní Úrì ti àwọn ará Kálídíà láti fún ọ ní ilẹ̀ yìí kó lè di ohun ìní+ rẹ.”
8 Ó bi í pé: “Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ, báwo ni màá ṣe mọ̀ pé ilẹ̀ yìí máa di ohun ìní mi?”
9 Ó fèsì pé: “Mú abo ọmọ màlúù ọlọ́dún mẹ́ta kan wá fún mi àti abo ewúrẹ́ ọlọ́dún mẹ́ta kan, àgbò ọlọ́dún mẹ́ta kan, ẹyẹ oriri kan àti ọmọ ẹyẹlé kan.”
10 Ó wá kó gbogbo rẹ̀, ó gé wọn sí méjì-méjì, ó sì kọjú wọn síra,* àmọ́ kò gé àwọn ẹyẹ náà.
11 Àwọn ẹyẹ aṣọdẹ wá ń bà lé àwọn òkú ẹran náà, àmọ́ Ábúrámù ń lé wọn.
12 Nígbà tó kù díẹ̀ kí oòrùn wọ̀, Ábúrámù sùn lọ fọnfọn, òkùnkùn biribiri tó ń dẹ́rù bani sì ṣú bò ó.
13 Ó wá sọ fún Ábúrámù pé: “Mọ̀ dájú pé àwọn ọmọ* rẹ máa di àjèjì ní ilẹ̀ tí kì í ṣe tiwọn, àwọn èèyàn ibẹ̀ á fi wọ́n ṣe ẹrú, wọ́n á sì fìyà jẹ wọ́n fún ọgọ́rùn-ún mẹ́rin (400) ọdún.+
14 Àmọ́ màá dá orílẹ̀-èdè tí wọn yóò sìn+ lẹ́jọ́, lẹ́yìn náà, wọ́n á kó ọ̀pọ̀ ẹrù+ jáde.
15 Ní tìrẹ, wàá lọ sọ́dọ̀ àwọn baba ńlá rẹ ní àlàáfíà; wàá dàgbà, wàá darúgbó kí o tó kú.+
16 Àmọ́ ìran wọn kẹrin á pa dà síbí,+ torí ẹ̀ṣẹ̀ àwọn Ámórì kò tíì kún rẹ́rẹ́.”+
17 Nígbà tí oòrùn wọ̀, tí ilẹ̀ sì ti ṣú, iná ìléru tó ń rú èéfín fara hàn, iná ògùṣọ̀ sì kọjá láàárín àwọn ẹran tó gé.
18 Ní ọjọ́ yẹn, Jèhófà bá Ábúrámù dá májẹ̀mú+ kan pé: “Ọmọ* rẹ ni èmi yóò fún ní ilẹ̀ yìí,+ láti odò Íjíbítì dé odò ńlá náà, ìyẹn odò Yúfírétì:+
19 ilẹ̀ àwọn Kénì,+ àwọn ọmọ Kénásì, àwọn Kádímónì,
20 àwọn ọmọ Hétì,+ àwọn Pérísì,+ àwọn Réfáímù,+
21 àwọn Ámórì, àwọn ọmọ Kénáánì, àwọn Gẹ́gáṣì àti àwọn ará Jébúsì.”+
Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé
^ Ní Héb., “èso.”
^ Ní Héb., “ọmọ.”
^ Ní Héb., “ẹni tó wá látinú ara rẹ.”
^ Ní Héb., “èso.”
^ Tàbí “ó sì kọjú wọn síra kí wọ́n lè bára mu.”
^ Ní Héb., “èso.”
^ Ní Héb., “Èso.”