Jẹ́nẹ́sísì 21:1-34
21 Jèhófà rántí Sérà gẹ́gẹ́ bí ó ṣe sọ, Jèhófà sì ṣe ohun tó ṣèlérí+ fún Sérà.
2 Sérà lóyún,+ ó sì bí ọmọkùnrin kan fún Ábúráhámù ní ọjọ́ ogbó rẹ̀ ní àkókò tí Ọlọ́run ṣèlérí fún un.+
3 Ábúráhámù pe orúkọ ọmọ tuntun tí Sérà bí fún un ní Ísákì.+
4 Ábúráhámù sì dádọ̀dọ́* Ísákì ọmọ rẹ̀ nígbà tó pé ọmọ ọjọ́ mẹ́jọ, bí Ọlọ́run ṣe pa á láṣẹ fún un.+
5 Ẹni ọgọ́rùn-ún (100) ọdún ni Ábúráhámù nígbà tó bí Ísákì ọmọ rẹ̀.
6 Sérà wá sọ pé: “Ọlọ́run ti pa mí lẹ́rìn-ín; gbogbo ẹni tó bá gbọ́ nípa rẹ̀ á bá mi rẹ́rìn-ín.”*
7 Ó fi kún un pé: “Ta ni ì bá sọ fún Ábúráhámù pé, ‘Ó dájú pé Sérà yóò di ìyá ọlọ́mọ’? Síbẹ̀ mo bímọ fún un ní ọjọ́ ogbó rẹ̀.”
8 Ọmọ náà wá dàgbà, wọ́n sì gba ọmú lẹ́nu rẹ̀, Ábúráhámù sì se àsè ńlá ní ọjọ́ tí wọ́n gba ọmú lẹ́nu Ísákì.
9 Àmọ́ Sérà ń kíyè sí i pé ọmọ tí Hágárì+ ará Íjíbítì bí fún Ábúráhámù ń fi Ísákì ṣe yẹ̀yẹ́.+
10 Ó wá sọ fún Ábúráhámù pé: “Lé ẹrúbìnrin yìí àti ọmọkùnrin rẹ̀ jáde, nítorí ọmọ ẹrúbìnrin yìí kò ní bá Ísákì ọmọ mi pín ogún!”+
11 Àmọ́ ohun tó sọ nípa ọmọ yìí kò dùn mọ́ Ábúráhámù+ nínú rárá.
12 Ọlọ́run wá sọ fún Ábúráhámù pé: “Má ṣe jẹ́ kí ohun tí Sérà ń sọ fún ọ nípa ọmọ náà àti ẹrúbìnrin rẹ bà ọ́ nínú jẹ́. Fetí sí ohun tó sọ,* torí látọ̀dọ̀ Ísákì+ ni ọmọ* rẹ yóò ti wá.
13 Ní ti ọmọ ẹrúbìnrin+ náà, màá mú kí òun náà di orílẹ̀-èdè kan,+ torí ọmọ* rẹ ni.”
14 Ábúráhámù wá jí ní àárọ̀ kùtù, ó mú búrẹ́dì àti ìgò omi tí wọ́n fi awọ ṣe, ó sì fún Hágárì. Ó gbé e lé èjìká rẹ̀, ó sì ní kí òun àti ọmọ+ náà máa lọ. Hágárì kúrò níbẹ̀, ó sì ń rìn kiri nínú aginjù Bíá-ṣébà.+
15 Nígbà tó yá, omi inú ìgò awọ náà tán, ó sì gbé ọmọ náà sábẹ́ igi kan nínú igbó.
16 Lẹ́yìn náà, ó lọ dá jókòó sí ìwọ̀n ibi tí ọfà lè dé téèyàn bá ta á, torí ó sọ pé: “Mi ò fẹ́ kí ọmọ náà kú níṣojú mi.” Torí náà, ó jókòó sí ọ̀ọ́kán, ó bẹ̀rẹ̀ sí í ké, ó sì ń sunkún.
17 Ọlọ́run gbọ́ igbe ọmọ+ náà, áńgẹ́lì Ọlọ́run sì pe Hágárì láti ọ̀run, ó sì sọ fún un+ pé: “Ṣé kò sí o, Hágárì? Má bẹ̀rù, torí Ọlọ́run ti gbọ́ igbe ọmọ náà níbi tó wà yẹn.
18 Dìde, gbé ọmọ náà, kí o sì fi ọwọ́ rẹ dì í mú, torí màá mú kí ó di orílẹ̀-èdè ńlá.”+
19 Ọlọ́run wá ṣí i lójú, ló bá rí kànga omi kan, ó wá lọ rọ omi kún ìgò awọ náà, ó sì fún ọmọ náà ní omi mu.
20 Ọlọ́run wà pẹ̀lú ọmọ+ náà bó ṣe ń dàgbà. Ó ń gbé inú aginjù, ó sì wá di tafàtafà.
21 Ó ń gbé inú aginjù Páránì,+ ìyá rẹ̀ sì fẹ́ ìyàwó fún un láti ilẹ̀ Íjíbítì.
22 Nígbà yẹn, Ábímélékì àti Fíkólì olórí àwọn ọmọ ogun rẹ̀ sọ fún Ábúráhámù pé: “Ọlọ́run wà pẹ̀lú rẹ nínú gbogbo ohun tí ò ń ṣe.+
23 Torí náà, fi Ọlọ́run búra fún mi báyìí, pé o ò ní hùwà ọ̀dàlẹ̀ sí èmi àti àwọn ọmọ mi àti àtọmọdọ́mọ mi àti pé o máa fi ìfẹ́ tí kì í yẹ̀ hàn sí èmi àti ilẹ̀ tí ò ń gbé bí mo ṣe fi hàn sí ọ.”+
24 Torí náà, Ábúráhámù sọ pé: “Mo búra.”
25 Àmọ́ Ábúráhámù fẹjọ́ sun Ábímélékì nípa kànga omi tí àwọn ìránṣẹ́ Ábímélékì fipá gbà.+
26 Ábímélékì fèsì pé: “Mi ò mọ ẹni tó ṣe èyí; o ò sọ ọ́ létí mi rí, òní yìí ni mo ṣẹ̀ṣẹ̀ ń gbọ́.”
27 Ni Ábúráhámù bá mú àgùntàn àti màlúù, ó kó o fún Ábímélékì, àwọn méjèèjì sì jọ dá májẹ̀mú.
28 Nígbà tí Ábúráhámù ya abo ọ̀dọ́ àgùntàn méje sọ́tọ̀ kúrò lára agbo ẹran,
29 Ábímélékì bi Ábúráhámù pé: “Kí nìdí tí o fi ya abo ọ̀dọ́ àgùntàn méje yìí sọ́tọ̀?”
30 Ó fèsì pé: “Gba abo ọ̀dọ́ àgùntàn méje náà lọ́wọ́ mi, kó jẹ́ ẹ̀rí pé èmi ni mo gbẹ́ kànga yìí.”
31 Ìdí nìyẹn tó fi pe ibẹ̀ ní Bíá-ṣébà,*+ torí pé àwọn méjèèjì búra níbẹ̀.
32 Torí náà, wọ́n dá májẹ̀mú+ ní Bíá-ṣébà, lẹ́yìn náà, Ábímélékì àti Fíkólì olórí àwọn ọmọ ogun rẹ̀ gbéra, wọ́n sì pa dà sí ilẹ̀ àwọn Filísínì.+
33 Lẹ́yìn náà, ó gbin igi támáríkì kan sí Bíá-ṣébà, ó sì ké pe orúkọ Jèhófà,+ Ọlọ́run ayérayé+ níbẹ̀.
34 Ábúráhámù sì ń gbé ní ilẹ̀ àwọn Filísínì,* ó pẹ́ gan-an*+ níbẹ̀.
Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé
^ Tàbí “kọlà.”
^ Tàbí kó jẹ́, “á fi mí rẹ́rìn-ín.”
^ Ní Héb., “ohùn rẹ̀.”
^ Ní Héb., “èso.”
^ Ní Héb., “èso.”
^ Ó túmọ̀ sí “Kànga Ìbúra; Kànga Ohun Méje.”
^ Tàbí “gbé ní ilẹ̀ àwọn Filísínì bí àjèjì.”
^ Ní Héb., “ó lo ọjọ́ tó pọ̀.”