Jẹ́nẹ́sísì 22:1-24

  • Ọlọ́run sọ fún Ábúráhámù pé kó fi Ísákì rúbọ (1-19)

    • Àwọn èèyàn yóò rí ìbùkún gbà torí àtọmọdọ́mọ Ábúráhámù (15-18)

  • Ìdílé Rèbékà (20-24)

22  Lẹ́yìn èyí, Ọlọ́run tòótọ́ dán Ábúráhámù wò,+ ó ní: “Ábúráhámù!” Ó fèsì pé: “Èmi nìyí!”  Ó wá sọ pé: “Jọ̀ọ́, mú ọmọ rẹ, ọmọ rẹ kan ṣoṣo tí o nífẹ̀ẹ́ gidigidi,+ ìyẹn Ísákì,+ kí o sì lọ sí ilẹ̀ Moráyà,+ kí o fi rú ẹbọ sísun níbẹ̀ lórí ọ̀kan nínú àwọn òkè tí màá fi hàn ọ́.”  Torí náà, Ábúráhámù jí ní àárọ̀ kùtù, ó de ohun tí wọ́n fi ń jókòó mọ́ kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ rẹ̀,* ó sì mú méjì nínú àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ dání pẹ̀lú Ísákì ọmọ rẹ̀. Ó la igi tó fẹ́ fi dáná ẹbọ sísun náà, ó gbéra, ó sì lọ síbi tí Ọlọ́run tòótọ́ sọ fún un.  Ní ọjọ́ kẹta, Ábúráhámù gbójú sókè, ó sì rí ibẹ̀ ní ọ̀ọ́kán.  Ábúráhámù wá sọ fún àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ pé: “Ẹ̀yin ẹ dúró ti kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ níbí, àmọ́ èmi àti ọmọ náà máa lọ síbẹ̀ yẹn láti jọ́sìn, a ó sì pa dà wá bá yín.”  Ábúráhámù wá gbé igi tó fẹ́ fi dáná ẹbọ sísun náà, ó sì gbé e ru Ísákì ọmọ rẹ̀. Ó mú iná àti ọ̀bẹ* dání, àwọn méjèèjì sì jọ ń rìn lọ.  Ísákì wá sọ fún Ábúráhámù bàbá rẹ̀ pé: “Bàbá mi!” Ó fèsì pé: “Èmi nìyí, ọmọ mi!” Ó ń bá ọ̀rọ̀ rẹ̀ lọ pé: “Iná àti igi rèé, àmọ́ ibo ni àgùntàn tí a máa fi rú ẹbọ sísun wà?”  Ábúráhámù fèsì pé: “Ọmọ mi, Ọlọ́run fúnra rẹ̀ máa pèsè àgùntàn tí a máa fi rú ẹbọ sísun.”+ Àwọn méjèèjì sì jọ ń rìn lọ.  Níkẹyìn, wọ́n dé ibi tí Ọlọ́run tòótọ́ sọ fún un, Ábúráhámù wá mọ pẹpẹ kan síbẹ̀, ó sì to igi sórí rẹ̀. Ó de Ísákì ọmọ rẹ̀ tọwọ́ tẹsẹ̀, ó sì gbé e sórí igi tó wà lórí pẹpẹ náà.+ 10  Ábúráhámù sì nawọ́ mú ọ̀bẹ* kó lè pa ọmọ+ rẹ̀. 11  Àmọ́ áńgẹ́lì Jèhófà pè é láti ọ̀run, ó sì sọ pé: “Ábúráhámù, Ábúráhámù!” Ó dáhùn pé: “Èmi nìyí!” 12  Ó sì sọ pé: “Má pa ọmọ náà, má sì ṣe ohunkóhun sí i, torí mo ti wá mọ̀ báyìí pé o bẹ̀rù Ọlọ́run, torí o ò kọ̀ láti fún mi+ ní ọmọ rẹ, ọ̀kan ṣoṣo tí o ní.” 13  Ni Ábúráhámù bá wòkè, ó sì rí àgbò kan ní ọ̀ọ́kán tí ìwo rẹ̀ há sínú igbó. Ábúráhámù lọ mú àgbò náà, ó sì fi rú ẹbọ sísun dípò ọmọ rẹ̀. 14  Ábúráhámù sì pe orúkọ ibẹ̀ ní Jèhófà-jirè.* Ìdí nìyẹn tí wọ́n fi ń sọ ọ́ títí dòní pé: “Orí òkè Jèhófà ni a ó ti pèsè.”+ 15  Áńgẹ́lì Jèhófà tún pe Ábúráhámù lẹ́ẹ̀kejì láti ọ̀run, 16  ó sọ pé: “‘Mo fi ara mi búra pé torí ohun tí o ṣe yìí,’ ni Jèhófà+ wí, ‘tí o kò kọ̀ láti fún mi ní ọmọ rẹ, ọ̀kan ṣoṣo+ tí o ní, 17  ó dájú pé màá bù kún ọ, ó sì dájú pé màá mú kí ọmọ* rẹ pọ̀ bí àwọn ìràwọ̀ ojú ọ̀run àti iyanrìn etí òkun,+ ọmọ* rẹ yóò sì gba ẹnubodè* àwọn ọ̀tá+ rẹ̀ lọ́wọ́ wọn. 18  Gbogbo orílẹ̀-èdè tó wà láyé yóò gba ìbùkún fún ara wọn nípasẹ̀ ọmọ*+ rẹ torí pé o fetí sí ohùn+ mi.’” 19  Lẹ́yìn náà, Ábúráhámù pa dà sọ́dọ̀ àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀, wọ́n gbéra, wọ́n sì jọ pa dà sí Bíá-ṣébà;+ Ábúráhámù sì ń gbé ní Bíá-ṣébà. 20  Lẹ́yìn èyí, wọ́n ròyìn fún Ábúráhámù pé: “Mílíkà náà ti bí àwọn ọmọ fún Náhórì arákùnrin+ rẹ: 21  Úsì ni àkọ́bí rẹ̀, Búsì ni àbúrò àti Kémúélì bàbá Árámù, 22  Késédì, Hásò, Pílídáṣì, Jídíláfù àti Bẹ́túẹ́lì.”+ 23  Bẹ́túẹ́lì bí Rèbékà.+ Àwọn mẹ́jọ yìí ni Mílíkà bí fún Náhórì arákùnrin Ábúráhámù. 24  Wáhàrì* rẹ̀ tó ń jẹ́ Réúmà náà bímọ: Tébà, Gáhámù, Táháṣì àti Máákà.

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé

Tàbí “ó di kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ rẹ̀ ní gàárì.”
Tàbí “ọ̀bẹ ìpẹran.”
Tàbí “ọ̀bẹ ìpẹran.”
Ó túmọ̀ sí “Jèhófà Yóò Pèsè; Jèhófà Yóò Rí sí I.”
Ní Héb., “èso.”
Ní Héb., “èso.”
Tàbí “àwọn ìlú.”
Ní Héb., “èso.”
Tàbí “Ìyàwó onípò kejì.” Wo Àlàyé Ọ̀rọ̀, “Wáhàrì.”