Jẹ́nẹ́sísì 33:1-20
33 Jékọ́bù bá wòkè, ó sì rí Ísọ̀ tó ń bọ̀ pẹ̀lú ọgọ́rùn-ún mẹ́rin (400) ọkùnrin.+ Torí náà, ó pín àwọn ọmọ sọ́dọ̀ Líà, Réṣẹ́lì àti àwọn ìránṣẹ́bìnrin+ méjèèjì.
2 Ó fi àwọn ìránṣẹ́bìnrin náà àti àwọn ọmọ wọn síwájú,+ Líà àti àwọn ọmọ rẹ̀ tẹ̀ lé wọn,+ Réṣẹ́lì+ àti Jósẹ́fù sì wà lẹ́yìn wọn.
3 Òun fúnra rẹ̀ wá ṣíwájú wọn, ó sì tẹrí ba mọ́lẹ̀ lẹ́ẹ̀meje bó ṣe ń sún mọ́ ẹ̀gbọ́n rẹ̀.
4 Àmọ́ Ísọ̀ sáré pàdé rẹ̀, ó gbá a mọ́ra, ó fi ẹnu kò ó lẹ́nu, wọ́n sì bú sẹ́kún.
5 Nígbà tó gbójú sókè, tó sì rí àwọn obìnrin àti àwọn ọmọ náà, ó bi í pé: “Àwọn wo ló wà pẹ̀lú rẹ yìí?” Ó fèsì pé: “Àwọn ọmọ tí Ọlọ́run fi bù kún ìránṣẹ́+ rẹ ni.”
6 Àwọn ìránṣẹ́bìnrin náà wá bọ́ síwájú pẹ̀lú àwọn ọmọ wọn, wọ́n sì tẹrí ba,
7 Líà náà bọ́ síwájú pẹ̀lú àwọn ọmọ rẹ̀, wọ́n sì tẹrí ba. Lẹ́yìn náà, Jósẹ́fù bọ́ síwájú pẹ̀lú Réṣẹ́lì, wọ́n sì tẹrí ba.+
8 Ísọ̀ bi Jékọ́bù pé: “Kí ni gbogbo àwùjọ àwọn arìnrìn-àjò tí mo pàdé+ yìí wà fún?” Ó fèsì pé: “Kí n lè rí ojúure olúwa+ mi ni.”
9 Ísọ̀ wá sọ pé: “Àbúrò mi,+ mo ní àwọn ohun tó pọ̀ gan-an. Máa mú àwọn nǹkan rẹ lọ.”
10 Àmọ́ Jékọ́bù sọ pé: “Jọ̀ọ́, má ṣe bẹ́ẹ̀. Tí mo bá rí ojúure rẹ, wàá gba ẹ̀bùn tí mo fún ọ lọ́wọ́ mi, torí kí n lè rí ojú rẹ ni mo ṣe mú un wá. Mo sì ti rí ojú rẹ, ó dà bí ìgbà tí mo rí ojú Ọlọ́run, torí o gbà mí tayọ̀tayọ̀.+
11 Jọ̀ọ́, gba ẹ̀bùn tí mo mú wá fún ọ+ láti bù kún ọ, torí Ọlọ́run ti ṣojúure sí mi, mo sì ní gbogbo ohun tí mo nílò.”+ Ó sì ń rọ̀ ọ́ títí ó fi gbà á.
12 Nígbà tó yá, Ísọ̀ sọ pé: “Jẹ́ ká ṣí kúrò, ká sì máa lọ. Jẹ́ kí n máa lọ níwájú rẹ.”
13 Àmọ́ ó sọ fún un pé: “Olúwa mi mọ̀ pé àwọn ọmọ ò fi bẹ́ẹ̀ lágbára,+ mo sì ní àwọn àgùntàn àti màlúù tó ń tọ́mọ lọ́wọ́. Tí mo bá yára dà wọ́n jù láàárín ọjọ́ kan, gbogbo ẹran ló máa kú.
14 Jọ̀ọ́, jẹ́ kí olúwa mi máa lọ níwájú ìránṣẹ́ rẹ̀, èmi á rọra máa bọ̀ bí agbára àwọn ẹran ọ̀sìn mi àti àwọn ọmọ mi bá ṣe gbé e, títí màá fi dé ọ̀dọ̀ olúwa mi ní Séírì.”+
15 Ísọ̀ wá sọ pé: “Jọ̀ọ́, jẹ́ kí n fi díẹ̀ lára àwọn èèyàn mi sílẹ̀ lọ́dọ̀ rẹ.” Ó fèsì pé: “Má ṣèyọnu, jẹ́ kí n ṣáà rí ojúure olúwa mi.”
16 Ísọ̀ sì pa dà sí Séírì ní ọjọ́ yẹn.
17 Jékọ́bù wá lọ sí Súkótù,+ ó kọ́ ilé fún ara rẹ̀, ó sì ṣe àtíbàbà fún agbo ẹran rẹ̀. Ìdí nìyẹn tó fi pe orúkọ ibẹ̀ ní Súkótù.*
18 Jékọ́bù rìnrìn àjò wá láti Padani-árámù,+ ó sì dé sí ìlú Ṣékémù+ ní ilẹ̀ Kénáánì+ ní àlàáfíà, ó wá pàgọ́ sí tòsí ìlú náà.
19 Ó ra apá kan lára ilẹ̀ tó pa àgọ́ rẹ̀ sí lọ́wọ́ àwọn ọmọ Hámórì, bàbá Ṣékémù, ó rà á ní ọgọ́rùn-ún (100) ẹyọ owó.+
20 Ó mọ pẹpẹ kan síbẹ̀, ó sì pè é ní Ọlọ́run, Ọlọ́run Ísírẹ́lì.+
Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé
^ Ó túmọ̀ sí “Àwọn Àtíbàbà; Ibi Ààbò.”