Jẹ́nẹ́sísì 5:1-32
5 Ìwé ìtàn Ádámù nìyí. Ní ọjọ́ tí Ọlọ́run dá Ádámù, ó dá a ní àwòrán Ọlọ́run.+
2 Ó dá wọn ní akọ àti abo.+ Ní ọjọ́ tó dá wọn,+ ó súre fún wọn, ó sì pè wọ́n ní Èèyàn.*
3 Ádámù pé ẹni àádóje (130) ọdún, ó wá bí ọmọkùnrin kan tó jọ ọ́, tó jẹ́ àwòrán rẹ̀, ó sì pe orúkọ rẹ̀ ní Sẹ́ẹ̀tì.+
4 Lẹ́yìn tó bí Sẹ́ẹ̀tì, Ádámù tún lo ọgọ́rùn-ún mẹ́jọ (800) ọdún. Ó sì bí àwọn ọmọ lọ́kùnrin àti lóbìnrin.
5 Gbogbo ọjọ́ ayé Ádámù jẹ́ ọgọ́rùn-ún mẹ́sàn-án ó lé ọgbọ̀n (930) ọdún, ó sì kú.+
6 Sẹ́ẹ̀tì pé ẹni ọdún márùnlélọ́gọ́rùn-ún (105), ó wá bí Énọ́ṣì.+
7 Lẹ́yìn tó bí Énọ́ṣì, Sẹ́ẹ̀tì tún lo ọgọ́rùn-ún mẹ́jọ ọdún ó lé méje (807). Ó sì bí àwọn ọmọ lọ́kùnrin àti lóbìnrin.
8 Gbogbo ọjọ́ ayé Sẹ́ẹ̀tì jẹ́ ọgọ́rùn-ún mẹ́sàn-án ọdún ó lé méjìlá (912), ó sì kú.
9 Énọ́ṣì pé ẹni àádọ́rùn-ún (90) ọdún, ó wá bí Kénánù.
10 Lẹ́yìn tó bí Kénánù, Énọ́ṣì tún lo ọgọ́rùn-ún mẹ́jọ ọdún ó lé mẹ́ẹ̀ẹ́dógún (815). Ó sì bí àwọn ọmọ lọ́kùnrin àti lóbìnrin.
11 Gbogbo ọjọ́ ayé Énọ́ṣì jẹ́ ọgọ́rùn-ún mẹ́sàn-án ọdún ó lé márùn-ún (905), ó sì kú.
12 Kénánù pé ẹni àádọ́rin (70) ọdún, ó wá bí Máhálálélì.+
13 Lẹ́yìn tó bí Máhálálélì, Kénánù tún lo ọgọ́rùn-ún mẹ́jọ ó lé ogójì (840) ọdún. Ó sì bí àwọn ọmọ lọ́kùnrin àti lóbìnrin.
14 Gbogbo ọjọ́ ayé Kénánù jẹ́ ọgọ́rùn-ún mẹ́sàn-án ọdún ó lé mẹ́wàá (910), ó sì kú.
15 Máhálálélì pé ẹni ọdún márùndínláàádọ́rin (65), ó wá bí Járédì.+
16 Lẹ́yìn tó bí Járédì, Máhálálélì tún lo ọgọ́rùn-ún mẹ́jọ ó lé ọgbọ̀n (830) ọdún. Ó sì bí àwọn ọmọ lọ́kùnrin àti lóbìnrin.
17 Gbogbo ọjọ́ ayé Máhálálélì jẹ́ ọgọ́rùn-ún mẹ́sàn-án ọdún ó dín márùn-ún (895), ó sì kú.
18 Járédì pé ẹni ọdún méjìlélọ́gọ́jọ (162), ó wá bí Énọ́kù.+
19 Lẹ́yìn tó bí Énọ́kù, Járédì tún lo ọgọ́rùn-ún mẹ́jọ (800) ọdún. Ó sì bí àwọn ọmọ lọ́kùnrin àti lóbìnrin.
20 Gbogbo ọjọ́ ayé Járédì jẹ́ ọgọ́rùn-ún mẹ́sàn-án àti méjìlélọ́gọ́ta (962) ọdún, ó sì kú.
21 Énọ́kù pé ẹni ọdún márùndínláàádọ́rin (65), ó wá bí Mètúsélà.+
22 Lẹ́yìn tó bí Mètúsélà, Énọ́kù ń bá Ọlọ́run tòótọ́* rìn fún ọgọ́rùn-ún mẹ́ta (300) ọdún. Ó sì bí àwọn ọmọ lọ́kùnrin àti lóbìnrin.
23 Gbogbo ọjọ́ ayé Énọ́kù jẹ́ ọgọ́rùn-ún mẹ́ta àti márùndínláàádọ́rin (365) ọdún.
24 Énọ́kù ń bá Ọlọ́run tòótọ́+ rìn. Nígbà tó yá, Énọ́kù ò sí mọ́, torí Ọlọ́run mú un lọ.+
25 Mètúsélà pé ẹni ọgọ́sàn-án ọdún ó lé méje (187), ó wá bí Lámékì.+
26 Lẹ́yìn tó bí Lámékì, Mètúsélà tún lo ọgọ́rùn-ún méje àti méjìlélọ́gọ́rin (782) ọdún. Ó sì bí àwọn ọmọ lọ́kùnrin àti lóbìnrin.
27 Gbogbo ọjọ́ ayé Mètúsélà jẹ́ ọgọ́rùn-ún mẹ́sàn-án àti mọ́kàndínláàádọ́rin (969) ọdún, ó sì kú.
28 Lámékì pé ẹni ọdún méjìlélọ́gọ́sàn-án (182), ó wá bí ọmọkùnrin kan.
29 Ó pe orúkọ rẹ̀ ní Nóà,*+ ó sọ pé: “Ọmọ yìí á tù wá nínú* nídìí iṣẹ́ wa àti làálàá tí a ṣe torí ilẹ̀ tí Jèhófà ti fi gégùn-ún.”+
30 Lẹ́yìn tó bí Nóà, Lámékì tún lo ọgọ́rùn-ún mẹ́fà ọdún ó dín márùn-ún (595). Ó sì bí àwọn ọmọ lọ́kùnrin àti lóbìnrin.
31 Gbogbo ọjọ́ ayé Lámékì jẹ́ ọgọ́rùn-ún méje àti mẹ́tàdínlọ́gọ́rin (777) ọdún, ó sì kú.
32 Lẹ́yìn tí Nóà pé ẹni ọgọ́rùn-ún márùn-ún (500) ọdún, ó bí Ṣémù,+ Hámù+ àti Jáfẹ́tì.+
Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé
^ Tàbí “Ádámù; Aráyé.”
^ Ní Héb., “Ọlọ́run náà.” Wo Àlàyé Ọ̀rọ̀.
^ Ó ṣeé ṣe kó túmọ̀ sí “Ìsinmi; Ìtùnú.”
^ Tàbí “tù wá lára.”