Jẹ́nẹ́sísì 6:1-22

  • Àwọn ọmọ Ọlọ́run fẹ́ ìyàwó ní ayé (1-3)

  • Wọ́n bí àwọn Néfílímù (4)

  • Ìwà búburú èèyàn ba Jèhófà lọ́kàn jẹ́ (5-8)

  • Ọlọ́run ní kí Nóà kan áàkì (9-16)

  • Ọlọ́run kéde pé Ìkún Omi ń bọ̀ (17-22)

6  Nígbà tí àwọn èèyàn bẹ̀rẹ̀ sí í pọ̀ lórí ilẹ̀, tí wọ́n sì ń bí àwọn ọmọbìnrin,  àwọn ọmọ Ọlọ́run tòótọ́*+ wá bẹ̀rẹ̀ sí í kíyè sí i pé àwọn ọmọbìnrin èèyàn rẹwà. Wọ́n sì ń fi gbogbo ẹni tó wù wọ́n ṣe aya.  Jèhófà wá sọ pé: “Ẹ̀mí mi ò ní gba èèyàn láyè títí láé,+ torí ẹlẹ́ran ara ni.* Torí náà, ọgọ́fà (120) ọdún ni ọjọ́ rẹ̀ yóò jẹ́.”+  Àwọn Néfílímù* wà ní ayé nígbà yẹn àti lẹ́yìn ìgbà yẹn. Ní àkókò yẹn, àwọn ọmọ Ọlọ́run tòótọ́ ń bá àwọn ọmọbìnrin èèyàn lò pọ̀, wọ́n sì bí àwọn ọmọ fún wọn. Àwọn ni alágbára ayé ìgbà yẹn, àwọn ọkùnrin olókìkí.  Jèhófà wá rí i pé ìwà burúkú èèyàn pọ̀ gan-an ní ayé, ó sì rí i pé kìkì ohun búburú ló ń rò lọ́kàn ní gbogbo ìgbà.+  Ó dun Jèhófà* pé òun dá èèyàn sáyé, ọkàn rẹ̀ sì bà jẹ́.*+  Torí náà, Jèhófà sọ pé: “Èmi yóò run àwọn èèyàn tí mo ti dá kúrò lórí ilẹ̀, èèyàn àti ẹran ọ̀sìn, ẹran tó ń rákò àti àwọn ẹ̀dá tó ń fò lójú ọ̀run, torí ó dùn mí pé mo dá wọn.”  Àmọ́ Nóà rí ojúure Jèhófà.  Ìtàn Nóà nìyí. Olódodo ni Nóà.+ Ó fi hàn pé òun jẹ́ aláìlẹ́bi* láàárín àwọn tí wọ́n jọ gbé láyé.* Nóà bá Ọlọ́run tòótọ́+ rìn. 10  Nígbà tó yá, Nóà bí ọmọkùnrin mẹ́ta, Ṣémù, Hámù àti Jáfẹ́tì.+ 11  Àmọ́ Ọlọ́run tòótọ́ rí i pé ayé ti bà jẹ́, ìwà ipá sì kún ayé. 12  Ọlọ́run wo ayé, àní ó ti bà jẹ́;+ ìwà ìbàjẹ́ ni gbogbo ẹlẹ́ran ara* ń hù ní ayé.+ 13  Lẹ́yìn náà, Ọlọ́run wá sọ fún Nóà pé: “Mo ti pinnu pé màá run gbogbo ẹlẹ́ran ara, torí wọ́n ti fi ìwà ipá kún ayé, torí náà, màá pa wọ́n run pẹ̀lú ayé.+ 14  Ìwọ fi igi olóje*+ ṣe áàkì* fún ara rẹ. Kí o ṣe àwọn yàrá sínú áàkì náà, kí o sì fi ọ̀dà bítúmẹ́nì+ bo inú àti ìta rẹ̀. 15  Bí o ṣe máa ṣe é nìyí: Kí áàkì náà gùn tó ọgọ́rùn-ún mẹ́ta (300) ìgbọ̀nwọ́,* kó fẹ̀ tó àádọ́ta (50) ìgbọ̀nwọ́, kó sì ga tó ọgbọ̀n (30) ìgbọ̀nwọ́. 16  Kí o ṣe fèrèsé* tí ìmọ́lẹ̀ á máa gbà wọ* inú áàkì náà, kó jẹ́ ìgbọ̀nwọ́ kan láti òkè. Kí o ṣe ẹnu ọ̀nà áàkì náà sí ẹ̀gbẹ́ rẹ̀,+ kí o sì jẹ́ kó ní àjà kìíní, àjà kejì àti àjà kẹta. 17  “Ní tèmi, màá mú kí ìkún omi  + bo ayé kí n lè run gbogbo ẹran ara tó ní ẹ̀mí* lábẹ́ ọ̀run. Gbogbo ohun tó wà ní ayé ló máa pa run.+ 18  Mo sì ń bá ọ dá májẹ̀mú, kí o wọ inú áàkì náà, ìwọ àti àwọn ọmọ rẹ àti ìyàwó rẹ pẹ̀lú ìyàwó àwọn ọmọ rẹ.+ 19  Kí o mú méjì-méjì lára gbogbo oríṣiríṣi ohun alààyè+ wọnú áàkì náà, kí ẹ lè jọ wà láàyè. Kí o mú wọn ní akọ àti abo;+ 20  àwọn ẹ̀dá tó ń fò ní irú tiwọn, àwọn ẹran ọ̀sìn ní irú tiwọn àti gbogbo ẹran tó ń rákò lórí ilẹ̀ ní irú tiwọn, méjì-méjì ni kí o mú wọn wọlé sọ́dọ̀ rẹ kí wọ́n lè wà láàyè.+ 21  Ní tìrẹ, kí o kó oríṣiríṣi oúnjẹ+ jọ, kí o sì gbé wọn dání, òun ni ìwọ àti àwọn ẹran náà á máa jẹ.” 22  Nóà sì ṣe gbogbo ohun tí Ọlọ́run pa láṣẹ fún un. Ó ṣe bẹ́ẹ̀ gẹ́lẹ́.+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé

Àkànlò èdè Hébérù tó ń tọ́ka sí àwọn áńgẹ́lì gẹ́gẹ́ bí ọmọ Ọlọ́run.
Tàbí kó jẹ́, “torí ohun tí ẹran ara ń fẹ́ ló ń ṣe.”
Ó ṣeé ṣe kó túmọ̀ sí “Àwọn Abiniṣubú,” ìyẹn, àwọn tó ń gbé èèyàn ṣubú. Wo Àlàyé Ọ̀rọ̀.
Tàbí “Jèhófà kẹ́dùn.”
Tàbí “ó sì dùn ún dọ́kàn.”
Tàbí “aláìlábùkù.”
Ní Héb., “àwọn ìran rẹ̀.”
Tàbí “gbogbo èèyàn.”
Ní Héb., “àwọn igi góférì,” ó ṣeé ṣe kó jẹ́ igi sípírẹ́sì.
Ní Héb., “àpótí ńlá.”
Ìgbọ̀nwọ́ kan jẹ́ sẹ̀ǹtímítà 44.5 (ínǹṣì 17.5). Wo Àfikún B14.
Lédè Hébérù, tsoʹhar. Yàtọ̀ sí fèrèsé tí ìmọ́lẹ̀ á máa gbà wọlé, tsoʹhar tún lè tọ́ka sí àjà tó ga ní ìgbọ̀nwọ́ kan, tó sì dagun.
Tàbí “wíńdò.”
Tàbí “èémí ìyè.”