Lẹ́tà Jémíìsì 1:1-27
1 Jémíìsì,+ ẹrú Ọlọ́run àti ti Jésù Kristi Olúwa, sí ẹ̀yà méjìlá (12) tó wà káàkiri:
Mo kí yín!
2 Ẹ̀yin ará mi, tí oríṣiríṣi àdánwò bá dé bá yín, ẹ ka gbogbo rẹ̀ sí ayọ̀,+
3 kí ẹ mọ̀ pé ìgbàgbọ́ yín tí a dán wò ní ti bó ṣe jẹ́ ojúlówó tó máa mú kí ẹ ní ìfaradà.+
4 Àmọ́ ẹ jẹ́ kí ìfaradà ṣe iṣẹ́ rẹ̀ láṣeparí, kí ẹ lè pé pérépéré, kí ẹ sì máa ṣe ohun tó tọ́ nínú ohun gbogbo, láìkù síbì kan.+
5 Torí náà, tí ẹnikẹ́ni nínú yín ò bá ní ọgbọ́n, kó máa béèrè lọ́wọ́ Ọlọ́run,+ ó sì máa fún un,+ torí ó lawọ́ sí gbogbo èèyàn, kì í sì í pẹ̀gàn*+ tó bá ń fúnni.
6 Àmọ́ kó máa fi ìgbàgbọ́ béèrè,+ kó má ṣiyèméjì rárá,+ torí ẹni tó ń ṣiyèméjì dà bí ìgbì òkun tí atẹ́gùn ń fẹ́ káàkiri.
7 Kódà, kí ẹni náà má rò pé òun máa rí ohunkóhun gbà lọ́dọ̀ Jèhófà;*
8 aláìnípinnu ni onítọ̀hún,+ kò sì dúró sójú kan ní gbogbo ọ̀nà rẹ̀.
9 Àmọ́ kí arákùnrin tó rẹlẹ̀ máa yọ̀* torí a gbé e ga,+
10 àti ọlọ́rọ̀ torí a ti rẹ̀ ẹ́ sílẹ̀,+ torí ó máa kọjá lọ bí òdòdó inú pápá.
11 Bí oòrùn ṣe máa ń mú ooru tó ń jóni jáde tó bá yọ, tó sì máa mú kí ewéko rọ, tí òdòdó rẹ̀ á já bọ́, tí ẹwà rẹ̀ tó tàn sì máa ṣègbé, bẹ́ẹ̀ náà ni ọlọ́rọ̀ máa pa rẹ́ bó ṣe ń lépa ọrọ̀.+
12 Aláyọ̀ ni ẹni tó ń fara da àdánwò,+ torí tó bá rí ìtẹ́wọ́gbà, ó máa gba adé ìyè,+ tí Jèhófà* ṣèlérí pé òun máa fún àwọn tí ò yéé nífẹ̀ẹ́ Rẹ̀.+
13 Tí àdánwò bá dé bá ẹnikẹ́ni, kó má ṣe sọ pé: “Ọlọ́run ló ń dán mi wò.” Torí a ò lè fi ibi dán Ọlọ́run wò, òun náà kì í sì í dán ẹnikẹ́ni wò.
14 Àmọ́ àdánwò máa ń dé bá kálukú nígbà tí ìfẹ́ ọkàn rẹ̀ bá fà á mọ́ra, tó sì tàn án jẹ.*+
15 Tí ìfẹ́ ọkàn náà bá ti gbilẹ̀,* ó máa bí ẹ̀ṣẹ̀; tí ẹ̀ṣẹ̀ náà bá sì ti wáyé, ó máa yọrí sí ikú.+
16 Ẹ̀yin ará mi ọ̀wọ́n, ẹ má ṣe jẹ́ kí ẹnikẹ́ni ṣì yín lọ́nà.
17 Gbogbo ẹ̀bùn rere àti gbogbo ọrẹ pípé wá láti òkè,+ ó ń wá látọ̀dọ̀ Baba àwọn ìmọ́lẹ̀ àtọ̀runwá,+ ẹni tí kì í yí pa dà, tí kì í sì í sún kiri bí òjìji.*+
18 Ìfẹ́ rẹ̀ ni pé kó fi ọ̀rọ̀ òtítọ́ mú wa wá,+ ká lè di oríṣi àkọ́so kan nínú àwọn ohun tó dá.+
19 Ẹ̀yin ará mi ọ̀wọ́n, ẹ mọ èyí: Ó yẹ kí gbogbo èèyàn yára láti gbọ́rọ̀, kí wọ́n lọ́ra láti sọ̀rọ̀,+ kí wọ́n má sì tètè máa bínú,+
20 torí ìbínú èèyàn kì í mú òdodo Ọlọ́run wá.+
21 Torí náà, ẹ mú gbogbo èérí àti gbogbo ohun tó jẹ mọ́ ìwà burúkú* kúrò,+ kí ìwà tútù yín sì mú kí ọ̀rọ̀ tó lè gbà yín là* fìdí múlẹ̀ nínú yín.
22 Àmọ́, ẹ máa ṣe ohun tí ọ̀rọ̀ náà sọ,+ ẹ má kàn máa gbọ́ ọ lásán, kí ẹ wá máa fi èrò èké tan ara yín jẹ.
23 Torí tí ẹnikẹ́ni bá ń gbọ́ ọ̀rọ̀ náà, àmọ́ tí kò ṣe é,+ ẹni yìí dà bí èèyàn tó ń wo ojú ara rẹ̀* nínú dígí.
24 Torí ó wo ara rẹ̀, ó lọ, ó sì gbàgbé irú ẹni tí òun jẹ́ lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀.
25 Àmọ́ ẹni tó bá ń fara balẹ̀ wo inú òfin pípé+ tó jẹ́ ti òmìnira, tí kò sì yéé wò ó, kì í ṣe olùgbọ́ tó ń gbàgbé, àmọ́ ó ti di olùṣe iṣẹ́ náà; ohun tó ń ṣe á sì máa múnú rẹ̀ dùn.+
26 Tí ẹnikẹ́ni bá rò pé òun ń jọ́sìn Ọlọ́run,* àmọ́ tí kò ṣọ́ ahọ́n rẹ̀ gidigidi,*+ ṣe ló ń tan ọkàn ara rẹ̀ jẹ, asán sì ni ìjọsìn rẹ̀.
27 Ìjọsìn* tó mọ́, tí kò sì ní ẹ̀gbin lójú Ọlọ́run àti Baba wa nìyí: láti máa bójú tó àwọn ọmọ aláìlóbìí+ àti àwọn opó+ nínú ìpọ́njú wọn,+ ká sì máa pa ara wa mọ́ láìní àbààwọ́n nínú ayé.+
Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé
^ Tàbí “dáni lẹ́bi.”
^ Ní Grk., “yangàn.”
^ Tàbí “mú un bí ìdẹ.”
^ Ní Grk., “lóyún.”
^ Tàbí “ẹni tí kò sí ìyípadà òjìji lọ́dọ̀ rẹ̀.”
^ Tàbí kó jẹ́, “ọ̀pọ̀ rẹpẹtẹ ìwà burúkú.”
^ Tàbí “gba ọkàn yín là.”
^ Tàbí “ojú àdánidá rẹ̀.”
^ Tàbí “òun gba Ọlọ́run gbọ́.”
^ Tàbí “kó ahọ́n rẹ̀ níjàánu.”
^ Tàbí “Ẹ̀sìn.”