Lẹ́tà Jémíìsì 2:1-26

  • Ojúsàájú jẹ́ ẹ̀ṣẹ̀ (1-13)

    • Ìfẹ́ ni ọba òfin (8)

  • Ìgbàgbọ́ láìsí àwọn iṣẹ́ jẹ́ òkú (14-26)

    • Àwọn ẹ̀mí èṣù gbà, jìnnìjìnnì sì bò wọ́n (19)

    • A pe Ábúráhámù ní ọ̀rẹ́ Jèhófà (23)

2  Ẹ̀yin ará mi, bí ẹ ṣe di ìgbàgbọ́ Jésù Kristi, Olúwa wa ológo mú, ṣé kì í ṣe pé ẹ tún ń ṣe ojúsàájú?+  Tí ẹnì kan bá wá sí ìpàdé yín, tó wọ àwọn òrùka wúrà sí ìka rẹ̀, tó sì wọ aṣọ tó dáa gan-an, àmọ́ tí tálákà kan tó wọ aṣọ tó dọ̀tí náà wọlé wá,  ṣé ẹ máa fi ojúure wo ẹni tó wọ aṣọ tó dáa gan-an, tí ẹ máa sọ pé, “Jókòó síbi tó dáa yìí,” tí ẹ sì máa wá sọ fún tálákà náà pé, “Ìwọ wà lórí ìdúró” tàbí, “Jókòó síbẹ̀ yẹn lábẹ́ àpótí ìtìsẹ̀ mi”?+  Tí ẹ bá ń ṣe bẹ́ẹ̀, ṣé kì í ṣe pé kẹ́lẹ́gbẹ́mẹgbẹ́ ti wà láàárín yín nìyẹn,+ tí ẹ sì ti di adájọ́ tó ń dá ẹjọ́ burúkú?+  Ẹ fetí sílẹ̀, ẹ̀yin ará mi ọ̀wọ́n. Ṣebí àwọn tí aráyé kà sí tálákà ni Ọlọ́run yàn pé kí wọ́n jẹ́ ọlọ́rọ̀ nínú ìgbàgbọ́+ àti ajogún Ìjọba náà, èyí tó ṣèlérí fún àwọn tó nífẹ̀ẹ́ rẹ̀?+  Síbẹ̀, ẹ ti tàbùkù sí tálákà. Ṣebí àwọn ọlọ́rọ̀ ló ń ni yín lára,+ tí wọ́n sì ń fà yín lọ sí ilé ẹjọ́?  Ṣebí wọ́n máa ń sọ̀rọ̀ òdì sí orúkọ rere tí ẹ̀ ń jẹ́?  Tí ẹ bá ń mú ọba òfin ṣẹ bó ṣe wà nínú ìwé mímọ́ pé, “Kí o nífẹ̀ẹ́ ọmọnìkejì rẹ bí ara rẹ,”+ ẹ̀ ń ṣe dáadáa gan-an ni.  Àmọ́ tí ẹ bá ṣì ń ṣe ojúsàájú,+ ẹ̀ṣẹ̀ lẹ̀ ń dá, òfin sì ti dá yín lẹ́bi* pé ẹlẹ́ṣẹ̀ ni yín.+ 10  Torí tí ẹnikẹ́ni bá ń pa gbogbo Òfin mọ́ àmọ́ tó ṣi ẹsẹ̀ gbé nínú ọ̀kan, ó ti rú gbogbo òfin.+ 11  Torí ẹni tó sọ pé, “O ò gbọ́dọ̀ ṣe àgbèrè,”+ ló tún sọ pé, “O ò gbọ́dọ̀ pààyàn.”+ Nígbà náà, tí o ò bá ṣe àgbèrè àmọ́ tí o pààyàn, o ti di arúfin. 12  Ẹ máa sọ̀rọ̀ kí ẹ sì máa hùwà bí àwọn tí a máa fi òfin àwọn tó wà lómìnira* dá lẹ́jọ́.+ 13  Torí ẹni tí kì í ṣàánú kò ní rí àánú gbà nígbà ìdájọ́.+ Àánú máa ń borí ìdájọ́. 14  Ẹ̀yin ará mi, kí ni àǹfààní rẹ̀, tí ẹnì kan bá sọ pé òun ní ìgbàgbọ́ àmọ́ tí kò ní àwọn iṣẹ́?+ Ìgbàgbọ́ yẹn ò lè gbà á là, àbí ó lè gbà á?+ 15  Tí arákùnrin tàbí arábìnrin èyíkéyìí ò bá láṣọ,* tí wọn ò sì ní oúnjẹ tó máa tó wọn jẹ lóòjọ́, 16  síbẹ̀ tí ẹnì kan nínú yín sọ fún wọn pé, “Ẹ máa lọ ní àlàáfíà; kí ẹ rí aṣọ fi bora, kí ẹ sì yó dáadáa,” àmọ́ tí ẹ ò fún wọn ní ohun tí ara wọn nílò, àǹfààní kí ló jẹ́?+ 17  Bákan náà, ìgbàgbọ́ nìkan láìsí àwọn iṣẹ́ jẹ́ òkú.+ 18  Àmọ́ ẹnì kan lè sọ pé: “Ìwọ́ ní ìgbàgbọ́, èmí sì ní àwọn iṣẹ́. Fi ìgbàgbọ́ rẹ hàn mí láìsí àwọn iṣẹ́, màá sì fi ìgbàgbọ́ mi hàn ọ́ nípa àwọn iṣẹ́ mi.” 19  O gbà pé Ọlọ́run kan ló wà, àbí? O ṣe dáadáa gan-an ni. Àwọn ẹ̀mí èṣù pàápàá gbà, jìnnìjìnnì sì bò wọ́n.+ 20  Àmọ́ ṣé o tiẹ̀ mọ̀ pé ìgbàgbọ́ kò wúlò láìsí iṣẹ́, ìwọ èèyàn lásánlàsàn? 21  Ṣebí a ka Ábúráhámù bàbá wa sí olódodo nípa àwọn iṣẹ́ lẹ́yìn tó mú Ísákì ọmọ rẹ̀ lọ sórí pẹpẹ?+ 22  Ẹ rí i pé ìgbàgbọ́ rẹ̀ hàn kedere nínú àwọn iṣẹ́ rẹ̀, àwọn iṣẹ́ rẹ̀ sì sọ ìgbàgbọ́ rẹ̀ di pípé,+ 23  a sì mú ìwé mímọ́ náà ṣẹ tó sọ pé: “Ábúráhámù ní ìgbàgbọ́ nínú Jèhófà,* a sì kà á sí òdodo fún un,”+ a sì wá ń pè é ní ọ̀rẹ́ Jèhófà.*+ 24  Ṣé ẹ wá rí i pé àwọn iṣẹ́ la fi ń ka èèyàn sí olódodo, kì í ṣe ìgbàgbọ́ nìkan. 25  Bákan náà, ṣebí àwọn iṣẹ́ ló mú kí á ka Ráhábù aṣẹ́wó pẹ̀lú sí olódodo, lẹ́yìn tó gba àwọn òjíṣẹ́ lálejò, tó sì ní kí wọ́n gba ọ̀nà míì jáde?+ 26  Lóòótọ́, bí ara láìsí ẹ̀mí* ṣe jẹ́ òkú,+ bẹ́ẹ̀ ni ìgbàgbọ́ láìsí àwọn iṣẹ́ jẹ́ òkú.+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé

Tàbí “bá yín wí.”
Ní Grk., “òfin òmìnira.”
Ní Grk., “bá wà níhòòhò.”
Tàbí “èémí.”