Lẹ́tà Jémíìsì 4:1-17
4 Ibo ni ogun àti àwọn ìjà tó wà láàárín yín ti wá? Ṣebí inú ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ ara tó ń bá yín* fínra ló ti wá?+
2 Ó ń wù yín, síbẹ̀ ẹ ò ní in. Ẹ̀ ń pààyàn, ẹ ò sì yéé ṣojúkòkòrò, síbẹ̀ ọwọ́ yín ò tẹ̀ ẹ́. Ẹ̀ ń jà, ẹ sì ń jagun.+ Ẹ ò ní torí pé ẹ ò béèrè.
3 Nígbà tí ẹ sì béèrè, ẹ ò rí gbà torí ohun tí kò dáa lẹ fẹ́ fi ṣe, ṣe lẹ fẹ́ lò ó fún ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ ara yín.
4 Ẹ̀yin alágbèrè,* ṣé ẹ ò mọ̀ pé bíbá ayé ṣọ̀rẹ́ ń sọni di ọ̀tá Ọlọ́run ni? Torí náà, ẹnikẹ́ni tó bá fẹ́ jẹ́ ọ̀rẹ́ ayé ń sọ ara rẹ̀ di ọ̀tá Ọlọ́run.+
5 Àbí ẹ rò pé lásán ni ìwé mímọ́ sọ pé: “Ẹ̀mí tó ń gbé inú wa ń mú ká máa jowú ṣáá”?+
6 Àmọ́ inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí tí Ó ń fi hàn tóbi ju èyí lọ. Ìdí nìyẹn tí ìwé mímọ́ fi sọ pé: “Ọlọ́run dojú ìjà kọ àwọn agbéraga,+ àmọ́ ó ń fi inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí hàn sí àwọn onírẹ̀lẹ̀.”+
7 Torí náà, ẹ fi ara yín sábẹ́ Ọlọ́run;+ àmọ́ ẹ dojú ìjà kọ Èṣù,+ ó sì máa sá kúrò lọ́dọ̀ yín.+
8 Ẹ sún mọ́ Ọlọ́run, á sì sún mọ́ yín.+ Ẹ wẹ ọwọ́ yín mọ́, ẹ̀yin ẹlẹ́ṣẹ̀,+ kí ẹ sì wẹ ọkàn yín mọ́,+ ẹ̀yin aláìnípinnu.
9 Ẹ banú jẹ́, ẹ ṣọ̀fọ̀, kí ẹ sì sunkún.+ Kí ẹ̀rín yín di ọ̀fọ̀, kí ayọ̀ yín sì di ìbànújẹ́.
10 Ẹ rẹ ara yín sílẹ̀ ní ojú Jèhófà,*+ ó sì máa gbé yín ga.+
11 Ẹ̀yin ará, ẹ má sọ̀rọ̀ tí kò dáa nípa ara yín mọ́.+ Ẹnikẹ́ni tó bá ń sọ̀rọ̀ tí kò dáa nípa arákùnrin kan tàbí tó ń dá arákùnrin rẹ̀ lẹ́jọ́, ó ń sọ̀rọ̀ tí kò dáa nípa òfin, ó sì ń dá òfin lẹ́jọ́. Tí o bá wá ń dá òfin lẹ́jọ́, o ò pa òfin mọ́, kàkà bẹ́ẹ̀ onídàájọ́ ni ọ́.
12 Ẹnì kan ṣoṣo ni Afúnnilófin àti Onídàájọ́ wa,+ ẹni tó lè gbà là, tó sì lè pa run.+ Àmọ́ ìwọ, ta ni ọ́ tí o fi ń dá ọmọnìkejì rẹ lẹ́jọ́?+
13 Ẹ gbọ́, ẹ̀yin tí ẹ̀ ń sọ pé: “Lónìí tàbí lọ́la, a máa rìnrìn àjò lọ sí ìlú yìí, a máa lo ọdún kan níbẹ̀, a máa ṣòwò, a sì máa jèrè,”+
14 bẹ́ẹ̀ sì rèé, ẹ ò mọ ohun tó máa ṣẹlẹ̀ sí yín lọ́la.+ Torí ìkùukùu ni yín, tó máa ń wà fúngbà díẹ̀, lẹ́yìn náà tí á pòórá.+
15 Kàkà bẹ́ẹ̀, ó yẹ kí ẹ sọ pé: “Tí Jèhófà* bá fẹ́,+ a máa wà láàyè, a sì máa ṣe tibí tàbí tọ̀hún.”
16 Àmọ́ ẹ̀ ń gbéra ga, ẹ sì ń fọ́nnu. Gbogbo ìfọ́nnu bẹ́ẹ̀ burú.
17 Torí náà, tí ẹnì kan bá mọ bí a ṣe ń ṣe ohun tó tọ́, síbẹ̀ tí kò ṣe é, ẹ̀ṣẹ̀ ni.+