Àkọsílẹ̀ Jòhánù 10:1-42

  • Olùṣọ́ àgùntàn àti ọgbà àgùntàn (1-21)

    • Jésù ni olùṣọ́ àgùntàn àtàtà (11-15)

    • “Mo ní àwọn àgùntàn mìíràn” (16)

  • Àwọn Júù ta ko Jésù níbi Àjọyọ̀ Ìyàsímímọ́ (22-39)

    • Ọ̀pọ̀ àwọn Júù ò gbà gbọ́ (24-26)

    • “Àwọn àgùntàn mi máa ń fetí sí ohùn mi” (27)

    • Ọmọ wà ní ìṣọ̀kan pẹ̀lú Baba (30, 38)

  • Ọ̀pọ̀ àwọn tó wà ní òdìkejì Jọ́dánì gbà gbọ́ (40-42)

10  “Lóòótọ́-lóòótọ́ ni mo sọ fún yín, ẹni tí kò bá gba ẹnu ọ̀nà wọ ọgbà àgùntàn, àmọ́ tó gba ibòmíì gòkè wọlé, olè àti akónilẹ́rù ni ẹni yẹn.+  Àmọ́ ẹni tó bá gba ẹnu ọ̀nà wọlé ni olùṣọ́ àgùntàn.+  Aṣọ́nà ṣílẹ̀kùn fún ẹni yìí,+ àwọn àgùntàn sì fetí sí ohùn rẹ̀.+ Ó ń fi orúkọ pe àwọn àgùntàn rẹ̀, ó sì ń kó wọn jáde.  Tó bá ti kó gbogbo àwọn tirẹ̀ jáde, ó máa ń lọ níwájú wọn, àwọn àgùntàn á sì tẹ̀ lé e, torí wọ́n mọ ohùn rẹ̀.  Ó dájú pé wọn ò ní tẹ̀ lé àjèjì, ṣe ni wọ́n máa sá fún un, torí wọn ò mọ ohùn àwọn àjèjì.”  Jésù sọ àfiwé yìí fún wọn, àmọ́ ohun tó ń sọ fún wọn ò yé wọn.  Torí náà, Jésù tún sọ pé: “Lóòótọ́-lóòótọ́ ni mo sọ fún yín, èmi ni ẹnu ọ̀nà fún àwọn àgùntàn.+  Olè àti akónilẹ́rù ni gbogbo àwọn tó wá dípò mi; àmọ́ àwọn àgùntàn ò fetí sí wọn.  Èmi ni ẹnu ọ̀nà; ẹnikẹ́ni tó bá gba ọ̀dọ̀ mi wọlé máa rí ìgbàlà, ẹni yẹn máa wọlé, ó máa jáde, ó sì máa rí ibi ìjẹko.+ 10  Olè kì í wá àfi tó bá fẹ́ jalè, kó pani, kó sì pani run.+ Èmi wá, kí wọ́n lè ní ìyè, kí wọ́n sì ní in lọ́pọ̀ rẹpẹtẹ. 11  Èmi ni olùṣọ́ àgùntàn àtàtà;+ olùṣọ́ àgùntàn àtàtà máa ń fi ẹ̀mí* rẹ̀ lélẹ̀ nítorí àwọn àgùntàn.+ 12  Nígbà tí alágbàṣe tí kì í ṣe olùṣọ́ àgùntàn, tí kì í sì í ṣe òun ló ni àwọn àgùntàn, rí ìkookò tó ń bọ̀, ó pa àwọn àgùntàn tì, ó sì sá lọ—ìkookò gbá wọn mú, ó sì tú wọn ká— 13  torí pé alágbàṣe ni, ọ̀rọ̀ àwọn àgùntàn ò sì jẹ ẹ́ lógún. 14  Èmi ni olùṣọ́ àgùntàn àtàtà. Mo mọ àwọn àgùntàn mi, àwọn àgùntàn mi sì mọ̀ mí,+ 15  bí Baba ṣe mọ̀ mí, tí mo sì mọ Baba;+ mo fi ẹ̀mí* mi lélẹ̀ nítorí àwọn àgùntàn.+ 16  “Mo ní àwọn àgùntàn mìíràn, tí kò sí lára ọ̀wọ́ yìí;+ mo gbọ́dọ̀ mú àwọn yẹn náà wá, wọ́n á fetí sí ohùn mi, wọ́n á sì di agbo kan, olùṣọ́ àgùntàn kan.+ 17  Ìdí nìyí tí Baba fi nífẹ̀ẹ́ mi,+ torí pé mo fi ẹ̀mí* mi lélẹ̀,+ kí n lè tún rí i gbà. 18  Kò sí èèyàn kankan tó gbà á lọ́wọ́ mi, èmi ni mo yọ̀ǹda láti fi lélẹ̀. Mo ní àṣẹ láti fi lélẹ̀, mo sì ní àṣẹ láti tún un gbà.+ Ọwọ́ Baba mi ni mo ti gba àṣẹ yìí.” 19  Àwọn Júù tún pínyà síra wọn+ nítorí àwọn ọ̀rọ̀ yìí. 20  Ọ̀pọ̀ nínú wọn ń sọ pé: “Ẹlẹ́mìí èṣù ni, orí rẹ̀ sì ti yí. Kí ló dé tí ẹ̀ ń fetí sí i?” 21  Àwọn míì sọ pé: “Àwọn ọ̀rọ̀ yìí kì í ṣe ti ẹlẹ́mìí èṣù. Ẹ̀mí èṣù ò lè la ojú afọ́jú, àbí ó lè là á?” 22  Ní àkókò yẹn, Àjọyọ̀ Ìyàsímímọ́ wáyé ní Jerúsálẹ́mù. Ìgbà òtútù ni, 23  Jésù sì ń rìn nínú tẹ́ńpìlì ní ọ̀dẹ̀dẹ̀* Sólómọ́nì.+ 24  Ni àwọn Júù bá yí i ká, wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí í sọ fún un pé: “Títí dìgbà wo lo fẹ́ fi wá* sínú òkùnkùn? Tó bá jẹ́ ìwọ ni Kristi náà, sọ fún wa ní tààràtà.” 25  Jésù dá wọn lóhùn pé: “Mo ti sọ fún yín, síbẹ̀ ẹ ò gbà gbọ́. Àwọn iṣẹ́ tí mò ń ṣe ní orúkọ Baba mi ń jẹ́rìí nípa mi.+ 26  Àmọ́ ẹ ò gbà gbọ́, torí ẹ kì í ṣe àgùntàn mi.+ 27  Àwọn àgùntàn mi máa ń fetí sí ohùn mi, mo mọ̀ wọ́n, wọ́n sì ń tẹ̀ lé mi.+ 28  Mo fún wọn ní ìyè àìnípẹ̀kun,+ ó sì dájú pé wọn ò ní pa run láé, ẹnikẹ́ni ò sì ní já wọn gbà kúrò lọ́wọ́ mi.+ 29  Ohun tí Baba mi ti fún mi tóbi ju gbogbo nǹkan míì lọ, kò sì sẹ́ni tó lè já wọn gbà kúrò lọ́wọ́ Baba.+ 30  Èmi àti Baba jẹ́ ọ̀kan.”*+ 31  Ni àwọn Júù bá tún mú òkúta kí wọ́n lè sọ ọ́ lù ú. 32  Jésù sọ fún wọn pé: “Ọ̀pọ̀ iṣẹ́ rere ni mo fi hàn yín látọ̀dọ̀ Baba. Torí èwo nínú àwọn iṣẹ́ yìí lẹ ṣe fẹ́ sọ mí lókùúta?” 33  Àwọn Júù dá a lóhùn pé: “Kì í ṣe torí iṣẹ́ rere la ṣe fẹ́ sọ ọ́ lókùúta, torí ọ̀rọ̀ òdì ni;+ torí pé o ti sọ ara rẹ di ọlọ́run, ìwọ tó jẹ́ pé èèyàn ni ọ́.” 34  Jésù sọ fún wọn pé: “Ṣebí a kọ ọ́ sínú Òfin yín pé, ‘Mo sọ pé: “ọlọ́run* ni yín”’?+ 35  Tó bá pe àwọn tí ọ̀rọ̀ Ọlọ́run sọ̀rọ̀ lòdì sí ní ‘ọlọ́run,’+ síbẹ̀ tí a kò lè wọ́gi lé ìwé mímọ́, 36  ṣé èmi tí Baba sọ di mímọ́, tó sì rán wá sí ayé lẹ wá ń sọ fún pé, ‘O sọ̀rọ̀ òdì,’ torí mo sọ pé, ‘Ọmọ Ọlọ́run ni mí’?+ 37  Tí mi ò bá ṣe àwọn iṣẹ́ Baba mi, ẹ má gbà mí gbọ́. 38  Àmọ́ tí mo bá ń ṣe é, bí ẹ ò tiẹ̀ gbà mí gbọ́, ẹ gba àwọn iṣẹ́ náà gbọ́,+ kí ẹ lè wá mọ̀, kí ẹ sì túbọ̀ máa mọ̀ pé Baba wà ní ìṣọ̀kan pẹ̀lú mi, mo sì wà ní ìṣọ̀kan pẹ̀lú Baba.”+ 39  Ni wọ́n bá tún fẹ́ mú un, àmọ́ ó bọ́ mọ́ wọn lọ́wọ́. 40  Ó tún lọ sí òdìkejì Jọ́dánì, síbi tí Jòhánù ti kọ́kọ́ ń ṣèrìbọmi fún àwọn èèyàn,+ ó sì dúró síbẹ̀. 41  Ọ̀pọ̀ èèyàn wá sọ́dọ̀ rẹ̀, wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí í sọ pé: “Jòhánù ò ṣe iṣẹ́ àmì kankan, àmọ́ òótọ́ ni gbogbo ohun tí Jòhánù sọ nípa ọkùnrin yìí.”+ 42  Ọ̀pọ̀ èèyàn sì gbà á gbọ́ níbẹ̀.

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé

Tàbí “ọkàn.”
Tàbí “ọkàn.”
Tàbí “ọkàn.”
Tàbí “ìloro.”
Tàbí “ọkàn wa.”
Tàbí “wà ní ìṣọ̀kan.”
Tàbí “ẹni bí Ọlọ́run.”