Àkọsílẹ̀ Jòhánù 13:1-38

  • Jésù fọ ẹsẹ̀ àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ (1-20)

  • Jésù fi hàn pé Júdásì ló máa da òun (21-30)

  • Àṣẹ tuntun (31-35)

    • “Tí ìfẹ́ bá wà láàárín yín” (35)

  • Ó sọ tẹ́lẹ̀ pé Pétérù máa sẹ́ òun (36-38)

13  Torí pé Jésù ti mọ̀ ṣáájú àjọyọ̀ Ìrékọjá pé wákàtí òun ti tó+ láti kúrò ní ayé yìí lọ sọ́dọ̀ Baba,+ ó nífẹ̀ẹ́ àwọn tirẹ̀ tó wà ní ayé, ó sì nífẹ̀ẹ́ wọn dé òpin.+  Wọ́n ń jẹ oúnjẹ alẹ́ lọ́wọ́, Èṣù sì ti fi sínú ọkàn Júdásì Ìsìkáríọ́tù,+ ọmọ Símónì, pé kó dà á.+  Jésù mọ̀ pé Baba ti fi ohun gbogbo lé òun lọ́wọ́ àti pé ọ̀dọ̀ Ọlọ́run ni òun ti wá, ọ̀dọ̀ Ọlọ́run ni òun sì ń lọ,+  torí náà, ó dìde nídìí oúnjẹ alẹ́, ó sì fi aṣọ àwọ̀lékè rẹ̀ sílẹ̀ lẹ́gbẹ̀ẹ́ kan. Ó wá mú aṣọ ìnura, ó sì so ó mọ́ ìbàdí.*+  Lẹ́yìn náà, ó bu omi sínú bàsíà kan, ó bẹ̀rẹ̀ sí í fọ ẹsẹ̀ àwọn ọmọ ẹ̀yìn, ó sì ń fi aṣọ ìnura tó so mọ́ ìbàdí* nù ún gbẹ.  Ó wá dé ọ̀dọ̀ Símónì Pétérù. Ó bi í pé: “Olúwa, ṣé o fẹ́ fọ ẹsẹ̀ mi ni?”  Jésù dá a lóhùn pé: “Ohun tí mò ń ṣe ò tíì yé ọ báyìí, àmọ́ lẹ́yìn àwọn nǹkan yìí, ó máa yé ọ.”  Pétérù sọ fún un pé: “O ò ní fọ ẹsẹ̀ mi láéláé.” Jésù dá a lóhùn pé: “Láìjẹ́ pé mo fọ ẹsẹ̀ rẹ,+ o ò ní ìpín kankan lọ́dọ̀ mi.”  Símónì Pétérù bá sọ fún un pé: “Olúwa, kì í ṣe ẹsẹ̀ mi nìkan lo máa fọ̀, tún fọ ọwọ́ mi àti orí mi.” 10  Jésù sọ fún un pé: “Ẹnikẹ́ni tó bá ti wẹ̀, kò nílò ju ká fọ ẹsẹ̀ rẹ̀ lọ, torí ó mọ́ látòkè délẹ̀. Ẹ̀yin mọ́, àmọ́ kì í ṣe gbogbo yín.” 11  Torí ó mọ ẹni tó máa da òun.+ Ìdí nìyí tó fi sọ pé: “Kì í ṣe gbogbo yín lẹ mọ́.” 12  Lẹ́yìn tó fọ ẹsẹ̀ wọn tán, tó sì wọ aṣọ àwọ̀lékè rẹ̀, ó pa dà jókòó* sídìí tábìlì, ó sì sọ fún wọn pé: “Ṣé ohun tí mo ṣe fún yín yé yín? 13  Ẹ̀ ń pè mí ní ‘Olùkọ́’ àti ‘Olúwa,’ òótọ́ lẹ sì sọ, torí ohun tí mo jẹ́ nìyẹn.+ 14  Torí náà, tí èmi, tí mo jẹ́ Olúwa àti Olùkọ́, bá fọ ẹsẹ̀ yín,+ ó yẹ* kí ẹ̀yin náà máa fọ ẹsẹ̀ ara yín.+ 15  Torí mo fi àpẹẹrẹ lélẹ̀ fún yín pé, bí mo ṣe ṣe fún yín gẹ́lẹ́ ni kí ẹ̀yin náà máa ṣe.+ 16  Lóòótọ́-lóòótọ́ ni mo sọ fún yín, ẹrú ò tóbi ju ọ̀gá rẹ̀ lọ, ẹni tí a rán jáde kò sì tóbi ju ẹni tó rán an. 17  Tí ẹ bá mọ àwọn nǹkan yìí, aláyọ̀ ni yín tí ẹ bá ń ṣe wọ́n.+ 18  Gbogbo yín kọ́ ni mò ń bá wí; mo mọ àwọn tí mo ti yàn. Àmọ́ èyí jẹ́ torí kí ìwé mímọ́ lè ṣẹ+ pé: ‘Ẹni tí a jọ ń jẹun ti jìn mí lẹ́sẹ̀.’*+ 19  Láti ìsinsìnyí lọ, mò ń sọ fún yín kó tó ṣẹlẹ̀, kó lè jẹ́ pé tó bá ṣẹlẹ̀, ẹ máa lè gbà gbọ́ pé èmi ni ẹni náà.+ 20  Lóòótọ́-lóòótọ́ ni mo sọ fún yín, ẹnikẹ́ni tó bá gba ẹni yòówù tí mo rán gba èmi náà,+ ẹnikẹ́ni tó bá sì gbà mí gba Ẹni tó rán mi pẹ̀lú.”+ 21  Lẹ́yìn tí Jésù sọ àwọn nǹkan yìí, ẹ̀dùn ọkàn bá a nínú ẹ̀mí, ó sì jẹ́rìí, ó sọ pé: “Lóòótọ́-lóòótọ́ ni mo sọ fún yín, ọ̀kan nínú yín máa dà mí.”+ 22  Àwọn ọmọ ẹ̀yìn wá bẹ̀rẹ̀ sí í wo ara wọn, torí ọ̀rọ̀ náà rú wọn lójú, wọn ò mọ ẹni tó ń sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀.+ 23  Ọ̀kan nínú àwọn ọmọ ẹ̀yìn, ẹni tí Jésù nífẹ̀ẹ́,+ jókòó* sí tòsí* Jésù. 24  Torí náà, Símónì Pétérù mi orí sí ẹni yìí, ó sì sọ fún un pé: “Sọ ẹni tó ń sọ̀rọ̀ ẹ̀ fún wa.” 25  Ẹni yẹn wá fẹ̀yìn ti àyà Jésù, ó sì bi í pé: “Olúwa, ta ni?”+ 26  Jésù dáhùn pé: “Ẹni tí mo bá fún ní búrẹ́dì tí mo kì bọ inú abọ́ ni.”+ Torí náà, lẹ́yìn tó ki búrẹ́dì bọ inú abọ́, ó mú un fún Júdásì, ọmọ Símónì Ìsìkáríọ́tù. 27  Lẹ́yìn tí Júdásì gba búrẹ́dì náà, Sátánì wọ inú Júdásì.+ Torí náà, Jésù sọ fún un pé: “Tètè ṣe ohun tí ò ń ṣe kíákíá.” 28  Àmọ́ ìkankan nínú àwọn tó jókòó sídìí tábìlì ò mọ ìdí tó fi sọ bẹ́ẹ̀ fún un. 29  Àwọn kan tiẹ̀ ń rò pé torí pé ọwọ́ Júdásì ni àpótí owó wà,+ ṣe ni Jésù ń sọ fún un pé, “Ra àwọn nǹkan tí a máa fi ṣe àjọyọ̀ náà” tàbí pé kó fún àwọn aláìní ní nǹkan. 30  Torí náà, lẹ́yìn tó gba búrẹ́dì náà, ó jáde lọ lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀. Ilẹ̀ sì ti ṣú.+ 31  Torí náà, lẹ́yìn tó jáde, Jésù sọ pé: “Ní báyìí, a ṣe Ọmọ èèyàn lógo,+ a sì tipasẹ̀ rẹ̀ ṣe Ọlọ́run lógo. 32  Ọlọ́run fúnra rẹ̀ máa ṣe é lógo,+ ó sì máa ṣe é lógo lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀. 33  Ẹ̀yin ọmọ kéékèèké, ìgbà díẹ̀ sí i ni màá fi wà pẹ̀lú yín. Ẹ máa wá mi; bí mo sì ṣe sọ fún àwọn Júù pé, ‘Ẹ ò lè wá sí ibi tí mò ń lọ,’+ mò ń sọ fún ẹ̀yin náà báyìí. 34  Mò ń fún yín ní àṣẹ tuntun kan, pé kí ẹ nífẹ̀ẹ́ ara yín; bí mo ṣe nífẹ̀ẹ́ yín,+ kí ẹ̀yin náà nífẹ̀ẹ́ ara yín.+ 35  Èyí ni gbogbo èèyàn máa fi mọ̀ pé ọmọ ẹ̀yìn mi ni yín, tí ìfẹ́ bá wà láàárín yín.”+ 36  Símónì Pétérù sọ fún un pé: “Olúwa, ibo lò ń lọ?” Jésù dáhùn pé: “O ò lè tẹ̀ lé mi lọ síbi tí mò ń lọ báyìí, àmọ́ o máa tẹ̀ lé mi tó bá yá.”+ 37  Pétérù sọ fún un pé: “Olúwa, kí ló dé tí mi ò lè tẹ̀ lé ọ báyìí? Màá fi ẹ̀mí* mi lélẹ̀ nítorí rẹ.”+ 38  Jésù dáhùn pé: “Ṣé o máa fi ẹ̀mí* rẹ lélẹ̀ nítorí mi? Lóòótọ́-lóòótọ́ ni mo sọ fún ọ, ó dájú pé àkùkọ ò ní kọ tí wàá fi sẹ́ mi lẹ́ẹ̀mẹta.”+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé

Tàbí “di ara rẹ̀ lámùrè.”
Tàbí “tó fi di ara rẹ̀ lámùrè.”
Ní Grk., “rọ̀gbọ̀kú.”
Tàbí “ó di dandan.”
Tàbí “ti yíjú pa dà sí mi.”
Ní Grk., “rọ̀gbọ̀kú.”
Ní Grk., “ní oókan àyà.”
Tàbí “ọkàn.”
Tàbí “ọkàn.”