Àkọsílẹ̀ Jòhánù 6:1-71
6 Lẹ́yìn náà, Jésù gbéra lọ sí òdìkejì Òkun Gálílì tàbí Tìbéríà.+
2 Èrò rẹpẹtẹ ń tẹ̀ lé e ṣáá,+ torí wọ́n ń kíyè sí àwọn iṣẹ́ ìyanu tó ń ṣe, bó ṣe ń wo àwọn aláìsàn sàn.+
3 Torí náà, Jésù lọ sórí òkè kan, òun àti àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ sì jókòó síbẹ̀.
4 Ìrékọjá,+ tó jẹ́ àjọyọ̀ àwọn Júù, ti sún mọ́lé.
5 Nígbà tí Jésù gbójú sókè, tó sì rí i pé èrò rẹpẹtẹ ń bọ̀ lọ́dọ̀ òun, ó sọ fún Fílípì pé: “Ibo la ti máa ra búrẹ́dì táwọn èèyàn yìí máa jẹ?”+
6 Àmọ́ ó ń sọ èyí kó lè dán an wò, torí ó mọ ohun tí òun máa tó ṣe.
7 Fílípì dá a lóhùn pé: “Búrẹ́dì igba (200) owó dínárì* ò lè tó wọn, ká tiẹ̀ ní díẹ̀ ni ẹnì kọ̀ọ̀kan wọn máa jẹ.”
8 Ọ̀kan lára àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀, Áńdérù arákùnrin Símónì Pétérù, sọ fún un pé:
9 “Ọmọdékùnrin kan nìyí tó ní búrẹ́dì ọkà báálì márùn-ún àti ẹja kéékèèké méjì. Àmọ́ kí ni èyí já mọ́ láàárín àwọn tó pọ̀ tó yìí?”+
10 Jésù sọ pé: “Ẹ ní kí àwọn èèyàn náà jókòó.” Torí pé koríko pọ̀ gan-an níbẹ̀, àwọn èèyàn náà jókòó, wọ́n jẹ́ nǹkan bí ẹgbẹ̀rún márùn-ún (5,000).+
11 Jésù mú búrẹ́dì náà, lẹ́yìn tó dúpẹ́, ó pín in fún àwọn tó jókòó síbẹ̀; ó ṣe ohun kan náà sí àwọn ẹja kéékèèké náà, wọ́n sì rí oúnjẹ tó pọ̀ tó bí wọ́n ṣe fẹ́.
12 Àmọ́ nígbà tí wọ́n yó, ó sọ fún àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ pé: “Ẹ kó àwọn ohun tó ṣẹ́ kù jọ, kí ohunkóhun má bàa ṣòfò.”
13 Torí náà, lẹ́yìn tí àwọn tó jẹ látinú búrẹ́dì ọkà báálì márùn-ún náà jẹun tán, wọ́n kó ohun tó ṣẹ́ kù jọ, ó sì kún apẹ̀rẹ̀ méjìlá (12).
14 Nígbà tí àwọn èèyàn rí iṣẹ́ àmì tó ṣe, wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí í sọ pé: “Ó dájú pé Wòlíì tí wọ́n ní ó máa wá sí ayé nìyí.”+
15 Jésù mọ̀ pé wọ́n máa tó wá mú òun láti fi òun jẹ ọba, torí náà, ó tún kúrò níbẹ̀,+ ó sì lọ sórí òkè lóun nìkan.+
16 Nígbà tó di ìrọ̀lẹ́, àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ lọ sí òkun,+
17 wọ́n wọ ọkọ̀ ojú omi, wọ́n sì forí lé Kápánáúmù. Ilẹ̀ ti wá ṣú báyìí, Jésù ò sì tíì wá bá wọn.+
18 Bákan náà, òkun ti ń ru gùdù torí pé ìjì líle kan ń fẹ́.+
19 Àmọ́ lẹ́yìn tí wọ́n ti tukọ̀ tó nǹkan bíi máìlì mẹ́ta sí mẹ́rin,* wọ́n rí Jésù tó ń rìn lórí òkun, tó sì ń sún mọ́ ọkọ̀ ojú omi náà, ẹ̀rù sì bà wọ́n.
20 Àmọ́ ó sọ fún wọn pé: “Èmi ni; ẹ má bẹ̀rù!”+
21 Ìgbà yẹn ni wọ́n wá fẹ́ kó wọnú ọkọ̀ ojú omi náà, ọkọ̀ ojú omi náà sì dé ilẹ̀ tí wọ́n forí lé+ lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀.
22 Lọ́jọ́ kejì, àwọn èrò tó wà ní òdìkejì òkun rí i pé kò sí ọkọ̀ ojú omi míì níbẹ̀ àfi kékeré kan àti pé Jésù ò bá àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ wọ ọkọ̀, àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ nìkan ló lọ.
23 Àmọ́, àwọn ọkọ̀ ojú omi láti Tìbéríà dé sí tòsí ibi tí wọ́n ti jẹ búrẹ́dì lẹ́yìn tí Olúwa dúpẹ́.
24 Torí náà, nígbà tí àwọn èrò náà rí i pé Jésù àti àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ ò sí níbẹ̀, wọ́n wọ àwọn ọkọ̀ ojú omi wọn wá sí Kápánáúmù láti wá Jésù.
25 Nígbà tí wọ́n rí i ní òdìkejì òkun, wọ́n bi í pé: “Rábì,+ ìgbà wo lo débí?”
26 Jésù dá wọn lóhùn pé: “Lóòótọ́-lóòótọ́ ni mo sọ fún yín, kì í ṣe torí àwọn àmì tí ẹ rí lẹ ṣe ń wá mi, àmọ́ torí pé ẹ jẹ nínú àwọn búrẹ́dì náà, ẹ sì yó.+
27 Ẹ má ṣiṣẹ́ fún oúnjẹ tó ń ṣègbé, àmọ́ ẹ ṣiṣẹ́ fún oúnjẹ tó wà fún ìyè àìnípẹ̀kun,+ èyí tí Ọmọ èèyàn máa fún yín; torí pé Baba, ìyẹn Ọlọ́run fúnra rẹ̀, ti gbé èdìdì ìtẹ́wọ́gbà rẹ̀ lé ẹni yìí.”+
28 Torí náà, wọ́n bi í pé: “Kí la gbọ́dọ̀ ṣe láti ṣe àwọn iṣẹ́ Ọlọ́run?”
29 Jésù dá wọn lóhùn pé: “Iṣẹ́ Ọlọ́run ni pé, kí ẹ ní ìgbàgbọ́ nínú ẹni tó rán.”+
30 Torí náà, wọ́n sọ fún un pé: “Iṣẹ́ àmì wo lo máa ṣe,+ ká lè rí i, ká sì gbà ọ́ gbọ́? Iṣẹ́ wo lo máa ṣe?
31 Àwọn baba ńlá wa jẹ mánà ní aginjù,+ bí a ṣe kọ ọ́ pé: ‘Ó fún wọn ní oúnjẹ láti ọ̀run kí wọ́n lè jẹ.’”+
32 Jésù wá sọ fún wọn pé: “Lóòótọ́-lóòótọ́ ni mo sọ fún yín, Mósè ò fún yín ní oúnjẹ láti ọ̀run, àmọ́ Baba mi fún yín ní oúnjẹ tòótọ́ láti ọ̀run.
33 Torí pé oúnjẹ Ọlọ́run ni ẹni tó sọ̀ kalẹ̀ láti ọ̀run, tó sì fún ayé ní ìyè.”
34 Wọ́n wá sọ fún un pé: “Olúwa, máa fún wa ní oúnjẹ yìí.”
35 Jésù sọ fún wọn pé: “Èmi ni oúnjẹ ìyè. Ẹnikẹ́ni tó bá wá sọ́dọ̀ mi, ebi ò ní pa á rárá, ẹnikẹ́ni tó bá sì ní ìgbàgbọ́ nínú mi, òùngbẹ ò ní gbẹ ẹ́ láé.+
36 Àmọ́ bí mo ṣe sọ fún yín, àní ẹ ti rí mi, síbẹ̀ ẹ ò gbà gbọ́.+
37 Gbogbo àwọn tí Baba fún mi máa wá sọ́dọ̀ mi, mi ò sì ní lé ẹni tó bá wá sọ́dọ̀ mi kúrò láé;+
38 torí mi ò sọ̀ kalẹ̀ wá láti ọ̀run+ kí n lè ṣe ìfẹ́ ara mi, ṣùgbọ́n láti ṣe ìfẹ́ ẹni tó rán mi.+
39 Ìfẹ́ ẹni tó rán mi ni pé kí n má pàdánù ìkankan nínú gbogbo àwọn tó fún mi, àmọ́ kí n jí wọn dìde + ní ọjọ́ ìkẹyìn.
40 Torí ìfẹ́ Baba mi ni pé kí gbogbo ẹni tó mọ Ọmọ, tó sì ní ìgbàgbọ́ nínú rẹ̀ ní ìyè àìnípẹ̀kun,+ màá sì jí i dìde+ ní ọjọ́ ìkẹyìn.”
41 Àwọn Júù wá bẹ̀rẹ̀ sí í kùn sí i torí ó sọ pé: “Èmi ni oúnjẹ tó sọ̀ kalẹ̀ wá láti ọ̀run.”+
42 Wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí í sọ pé: “Ṣebí Jésù ọmọ Jósẹ́fù nìyí, tí a mọ bàbá àti ìyá rẹ̀?+ Kí ló dé tó wá sọ pé, ‘Mo sọ̀ kalẹ̀ wá láti ọ̀run’?”
43 Jésù dá wọn lóhùn pé: “Ẹ má kùn láàárín ara yín mọ́.
44 Kò sí èèyàn tó lè wá sọ́dọ̀ mi láìjẹ́ pé Baba tó rán mi fà á,+ màá sì jí i dìde ní ọjọ́ ìkẹyìn.+
45 A kọ ọ́ sínú àwọn Wòlíì pé: ‘Jèhófà* máa kọ́ gbogbo wọn.’+ Gbogbo ẹni tó bá ti gbọ́ ti Baba, tó sì ti kẹ́kọ̀ọ́ ń wá sọ́dọ̀ mi.
46 Kì í ṣe pé èèyàn kankan ti rí Baba,+ àfi ẹni tó wá látọ̀dọ̀ Ọlọ́run; ẹni yìí ti rí Baba.+
47 Lóòótọ́-lóòótọ́ ni mo sọ fún yín, ẹnikẹ́ni tó bá gbà gbọ́ ní ìyè àìnípẹ̀kun.+
48 “Èmi ni oúnjẹ ìyè.+
49 Àwọn baba ńlá yín jẹ mánà ní aginjù, síbẹ̀ wọ́n kú.+
50 Oúnjẹ tó sọ̀ kalẹ̀ wá láti ọ̀run nìyí, kí ẹnikẹ́ni tó bá jẹ nínú rẹ̀ má bàa kú.
51 Èmi ni oúnjẹ ààyè tó sọ̀ kalẹ̀ wá láti ọ̀run. Tí ẹnikẹ́ni bá jẹ nínú oúnjẹ yìí, ó máa wà láàyè títí láé; àti pé ní tòótọ́, ẹran ara mi ni oúnjẹ tí màá fúnni nítorí ìyè ayé.”+
52 Torí náà, àwọn Júù bẹ̀rẹ̀ sí í bára wọn jiyàn pé: “Báwo ni ọkùnrin yìí ṣe máa fún wa ní ẹran ara rẹ̀ jẹ?”
53 Jésù wá sọ fún wọn pé: “Lóòótọ́-lóòótọ́ ni mo sọ fún yín, láìjẹ́ pé ẹ jẹ ẹran ara Ọmọ èèyàn, tí ẹ sì mu ẹ̀jẹ̀ rẹ̀, ẹ ò ní ìyè kankan nínú ara yín.+
54 Ẹnikẹ́ni tó bá ń jẹ ẹran ara mi, tó sì ń mu ẹ̀jẹ̀ mi máa ní ìyè àìnípẹ̀kun, màá sì jí i dìde+ ní ọjọ́ ìkẹyìn;
55 torí pé oúnjẹ tòótọ́ ni ẹran ara mi, ohun mímu tòótọ́ sì ni ẹ̀jẹ̀ mi.
56 Ẹnikẹ́ni tó bá ń jẹ ẹran ara mi, tó sì ń mu ẹ̀jẹ̀ mi wà ní ìṣọ̀kan pẹ̀lú mi, èmi náà sì wà ní ìṣọ̀kan pẹ̀lú rẹ̀.+
57 Bí Baba tó wà láàyè ṣe rán mi, tí mo sì wà láàyè nítorí Baba, bẹ́ẹ̀ náà ni ẹni tó bá ń fi mí ṣe oúnjẹ máa wà láàyè nítorí mi.+
58 Oúnjẹ tó sọ̀ kalẹ̀ wá láti ọ̀run nìyí. Kò dà bí ìgbà tí àwọn baba ńlá yín jẹun, síbẹ̀ tí wọ́n kú. Ẹnikẹ́ni tó bá ń jẹ oúnjẹ yìí máa wà láàyè títí láé.”+
59 Ó sọ àwọn nǹkan yìí nígbà tó ń kọ́ni nínú sínágọ́gù kan* ní Kápánáúmù.
60 Nígbà tí wọ́n gbọ́ èyí, ọ̀pọ̀ lára àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ sọ pé: “Ọ̀rọ̀ yìí ń dẹ́rù bani; kò ṣeé gbọ́ sétí!”
61 Àmọ́ Jésù mọ̀ nínú ara rẹ̀ pé àwọn ọmọ ẹ̀yìn òun ń kùn nípa èyí, ó wá sọ fún wọn pé: “Ṣé ó mú yín kọsẹ̀ ni?
62 Tí ẹ bá wá rí Ọmọ èèyàn tó ń gòkè lọ sí ibi tó wà tẹ́lẹ̀ ńkọ́?+
63 Ẹ̀mí ló ń fúnni ní ìyè;+ ẹran ara ò wúlò rárá. Ẹ̀mí àti ìyè ni àwọn ọ̀rọ̀ tí mo sọ fún yín.+
64 Àmọ́ àwọn kan wà nínú yín tí kò gbà gbọ́.” Torí pé láti ìbẹ̀rẹ̀ ni Jésù ti mọ àwọn tí kò gbà gbọ́ àti ẹni tó máa dà á.+
65 Ó ń bá ọ̀rọ̀ rẹ̀ lọ pé: “Ìdí nìyí tí mo fi sọ fún yín pé, kò sí ẹni tó lè wá sọ́dọ̀ mi láìjẹ́ pé Baba yọ̀ǹda fún un.”+
66 Nítorí èyí, ọ̀pọ̀ lára àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ pa dà sídìí àwọn nǹkan tí wọ́n ti fi sílẹ̀,+ wọn ò sì bá a rìn mọ́.
67 Jésù wá sọ fún àwọn Méjìlá náà pé: “Ẹ̀yin ò fẹ́ lọ ní tiyín, àbí ẹ fẹ́ lọ?”
68 Símónì Pétérù dá a lóhùn pé: “Olúwa, ọ̀dọ̀ ta la máa lọ?+ Ìwọ lo ní àwọn ọ̀rọ̀ ìyè àìnípẹ̀kun.+
69 A ti gbà gbọ́, a sì ti mọ̀ pé ìwọ ni Ẹni Mímọ́ Ọlọ́run.”+
70 Jésù sọ fún wọn pé: “Ẹ̀yin méjìlá (12) yìí ni mo yàn, àbí bẹ́ẹ̀ kọ́?+ Síbẹ̀, abanijẹ́* ni ọ̀kan nínú yín.”+
71 Ní tòótọ́, ọ̀rọ̀ Júdásì ọmọ Símónì Ìsìkáríọ́tù ló ń sọ, torí pé ẹni yìí máa dà á, bó tiẹ̀ jẹ́ pé ó wà lára àwọn Méjìlá náà.+
Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé
^ Wo Àfikún B14.
^ Nǹkan bíi kìlómítà márùn-ún sí mẹ́fà. Ní Grk., “nǹkan bíi sítédíọ̀mù 25 sí 30.” Wo Àfikún B14.
^ Tàbí “níbi táwọn èèyàn pé jọ sí.”
^ Tàbí “èṣù.”