Jóòbù 21:1-34
21 Jóòbù fèsì pé:
2 “Ẹ fara balẹ̀ fetí sí ọ̀rọ̀ mi;Kí èyí jẹ́ ohun tí ẹ fi máa tù mí nínú.
3 Ẹ gba tèmi rò tí mo bá ń sọ̀rọ̀;Tí mo bá sọ̀rọ̀ tán, ẹ lè wá fi mí ṣe yẹ̀yẹ́.+
4 Ṣé èèyàn kan ni mò ń ṣàròyé fún ni?
Tó bá rí bẹ́ẹ̀, ṣé mo* máa lè ní sùúrù?
5 Ẹ wò mí, kí ẹnu sì yà yín;Ẹ fi ọwọ́ bo ẹnu yín.
6 Tí mo bá ń rò ó, ọkàn mi kì í balẹ̀,Gbogbo ara mi sì ń gbọ̀n rìrì.
7 Kí ló dé tí àwọn ẹni burúkú ṣì fi wà láàyè,+Tí wọ́n ń darúgbó, tí wọ́n sì ń di ọlọ́rọ̀?*+
8 Gbogbo ìgbà ni àwọn ọmọ wọn ń wà lọ́dọ̀ wọn,Wọ́n sì ń rí àtọmọdọ́mọ wọn.
9 Ààbò wà lórí ilé wọn, wọn ò bẹ̀rù rárá,+Ọlọ́run ò sì fi ọ̀pá rẹ̀ jẹ wọ́n níyà.
10 Akọ màlúù wọn ń gùn, kì í sì í tàsé;Abo màlúù wọn ń bímọ, oyún ò sì bà jẹ́ lára wọn.
11 Àwọn ọmọkùnrin wọn ń sáré jáde bí agbo ẹran,Àwọn ọmọ wọn sì ń ta pọ́n-ún pọ́n-ún.
12 Wọ́n ń lo ìlù tanboríìnì àti háàpù bí wọ́n ṣe ń kọrin,Ìró fèrè* sì ń múnú wọn dùn.+
13 Ọkàn wọn balẹ̀ bí wọ́n ṣe ń lo ọjọ́ ayé wọn,Wọ́n sì lọ sínú Isà Òkú* ní àlàáfíà.*
14 Àmọ́ wọ́n sọ fún Ọlọ́run tòótọ́ pé, ‘Fi wá sílẹ̀!
Kò wù wá pé ká mọ àwọn ọ̀nà rẹ.+
15 Ta ni Olódùmarè, tí a fi máa sìn ín?+
Èrè wo la máa rí tí a bá mọ̀ ọ́n?’+
16 Àmọ́ mo mọ̀ pé agbára wọn kọ́ ló mú wọn láásìkí.+
Èrò* àwọn ẹni burúkú jìnnà sí mi.+
17 Ìgbà mélòó là ń fẹ́ fìtílà àwọn ẹni burúkú pa?+
Ìgbà mélòó ni àjálù ń dé bá wọn?
Ìgbà mélòó ni Ọlọ́run ń fi ìbínú pa wọ́n run?
18 Ṣé wọ́n dà bíi pòròpórò rí níwájú atẹ́gùnÀti bí ìyàngbò* tí ìjì gbé lọ?
19 Ọlọ́run máa fi ìyà èèyàn pa mọ́ de àwọn ọmọ rẹ̀;Àmọ́ kí Ọlọ́run san án lẹ́san, kó bàa lè mọ̀ ọ́n.+
20 Kó fi ojú ara rẹ̀ rí ìparun rẹ̀,Kí òun fúnra rẹ̀ sì mu nínú ìbínú Olódùmarè.+
21 Torí kí ló ṣe ń ronú ohun tó máa ṣẹlẹ̀ sí ilé rẹ̀ lẹ́yìn rẹ̀,Tí a bá gé iye oṣù rẹ̀ kúrú?*+
22 Ṣé ẹnì kankan lè kọ́ Ọlọ́run ní ohunkóhun,*+Nígbà tó jẹ́ pé Òun ló ń dá ẹjọ́ àwọn ẹni gíga jù pàápàá?+
23 Ẹnì kan kú nígbà tó ṣì lókun,+Nígbà tí ara tù ú gan-an, tí ọkàn rẹ̀ sì balẹ̀,+
24 Nígbà tí ọ̀rá kún itan rẹ̀,Tí egungun rẹ̀ sì le.*
25 Àmọ́ ẹlòmíì kú nínú ìbànújẹ́,*Láì gbádùn ohun rere kankan rí.
26 Wọ́n jọ máa dùbúlẹ̀ sínú erùpẹ̀ ni,+Ìdin sì máa bo àwọn méjèèjì.+
27 Ẹ wò ó! Mo mọ ohun tí ẹ̀ ń rò ganganÀti àwọn ohun tí ẹ̀ ń gbèrò láti fi ṣe mí níkà.*+
28 Torí ẹ sọ pé, ‘Ibo ni ilé ẹni tó gbajúmọ̀ wà,Ibo sì ni àgọ́ tí ẹni burúkú gbé wà?’+
29 Ṣebí ẹ ti béèrè ọ̀rọ̀ lọ́wọ́ àwọn arìnrìn-àjò?
Ṣebí ẹ̀ ń fara balẹ̀ wo àwọn ohun tí wọ́n rí,*
30 Pé à ń dá ẹni ibi sí ní ọjọ́ àjálù,A sì ń gbà á sílẹ̀ ní ọjọ́ ìbínú?
31 Ta ló máa kò ó lójú nípa ọ̀nà rẹ̀,Ta ló sì máa san án lẹ́san ohun tó ṣe?
32 Tí wọ́n bá gbé e lọ sí itẹ́ òkú,Wọ́n máa ṣọ́ ibojì rẹ̀.
33 Iyẹ̀pẹ̀ tó ṣù pọ̀ ní àfonífojì máa dùn mọ́ ọn lẹ́nu,+Gbogbo aráyé sì ń tẹ̀ lé e,*+Bí àìmọye tó ṣáájú rẹ̀.
34 Kí ló dé tí ẹ wá ń fún mi ní ìtùnú tí kò nítumọ̀?+
Ẹ̀tàn ni gbogbo ìdáhùn yín!”
Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé
^ Ní Héb., “ẹ̀mí mi.”
^ Tàbí “alágbára.”
^ Tàbí “fèrè ape.”
^ Tàbí “Ṣìọ́ọ̀lù,” ìyẹn ibojì aráyé. Wo Àlàyé Ọ̀rọ̀.
^ Tàbí “ní ìṣẹ́jú kan,” ìyẹn, ikú ìrọ̀rùn tí kò pẹ́ rárá.
^ Tàbí “Ìmọ̀ràn; Ète.”
^ Ìyẹn, èèpo fúlẹ́fúlẹ́ ara ọkà.
^ Tàbí “gé iye oṣù rẹ̀ sí méjì.”
^ Ní Héb., “fi ìmọ̀ kọ́ Ọlọ́run.”
^ Ní Héb., “Tí mùdùnmúdùn egungun rẹ̀ sì tutù.”
^ Tàbí “ọkàn ẹlòmíì gbọgbẹ́ títí tó fi kú.”
^ Tàbí kó jẹ́, “láti fi hùwà ipá sí mi.”
^ Ní Héb., “àwọn àmì wọn.”
^ Ní Héb., “Ó sì máa wọ́ gbogbo aráyé tẹ̀ lé e.”