Jóòbù 22:1-30
22 Élífásì+ ará Témánì fèsì pé:
2 “Ṣé èèyàn wúlò fún Ọlọ́run?
Ṣé ẹni tó ní ìjìnlẹ̀ òye lè ṣe é láǹfààní?+
3 Tí o bá jẹ́ olódodo, kí ló kan Olódùmarè,*Àbí ó jèrè kankan torí pé o rìn ní ọ̀nà ìwà títọ́?+
4 Ṣé ó máa fìyà jẹ ọ́,Kó sì bá ọ ṣe ẹjọ́ torí pé o bẹ̀rù rẹ̀?
5 Ṣé kì í ṣe torí pé ìwà burúkú rẹ pọ̀ jù ni,Tí àwọn ẹ̀ṣẹ̀ rẹ ò sì lópin?+
6 Torí o gba ohun ìdúró lọ́wọ́ àwọn arákùnrin rẹ láìnídìí,O sì bọ́ aṣọ lára àwọn èèyàn, o wá fi wọ́n sílẹ̀ ní ìhòòhò.*+
7 O ò fún ẹni tó ti rẹ̀ lómi mu,O ò sì fún ẹni tí ebi ń pa lóúnjẹ.+
8 Alágbára ọkùnrin + ló ni ilẹ̀,Ẹni tó rí ojúure sì ń gbé ibẹ̀.
9 Àmọ́, o ní kí àwọn opó máa lọ lọ́wọ́ òfo,O sì ṣẹ́ apá àwọn ọmọ aláìníbaba.*
10 Ìdí nìyẹn tí pańpẹ́*+ fi yí ọ ká,Tí jìnnìjìnnì sì ṣàdédé bá ọ;
11 Ìdí nìyẹn tí òkùnkùn fi bò ọ́ débi pé o ò lè ríran,Tí àkúnya omi sì bò ọ́ mọ́lẹ̀.
12 Ṣebí Ọlọ́run wà lókè nínú ọ̀run?
Tún wo bí gbogbo ìràwọ̀ ṣe ga tó.
13 Àmọ́, o sọ pé: ‘Kí ni Ọlọ́run tiẹ̀ mọ̀?
Ṣé ó lè ṣèdájọ́ látinú ìṣúdùdù tó kàmàmà?
14 Àwọsánmà* bò ó lójú, kò jẹ́ kó ríran,Ó sì ń rìn kiri ní ìsálú* ọ̀run.’
15 Ṣé o máa gba ọ̀nà àtijọ́Tí àwọn èèyàn burúkú rìn,
16 Àwọn èèyàn tí a yára mú lọ,* kí àkókò wọn tó pé,Tí àkúnya omi* gbé ìpìlẹ̀ wọn lọ?+
17 Wọ́n ń sọ fún Ọlọ́run tòótọ́ pé: ‘Fi wá sílẹ̀!’
Àti pé, ‘Kí ni Olódùmarè lè ṣe fún wa?’
18 Síbẹ̀, òun ni Ó fi ohun rere kún àwọn ilé wọn.
(Irú èrò burúkú bẹ́ẹ̀ jìnnà sí tèmi.)
19 Olódodo máa rí èyí, á sì yọ̀,Aláìmọwọ́-mẹsẹ̀ máa fi wọ́n ṣe yẹ̀yẹ́, á sì sọ pé:
20 ‘Àwọn ọ̀tá wa ti pa run,Iná sì máa jó ohun tó bá ṣẹ́ kù lára wọn.’
21 Wá mọ̀ Ọ́n, wàá sì ní àlàáfíà;Ohun rere á wá máa ṣẹlẹ̀ sí ọ.
22 Gba òfin láti ẹnu rẹ̀,Kí o sì fi ọ̀rọ̀ rẹ̀ sínú ọkàn rẹ.+
23 Tí o bá pa dà sọ́dọ̀ Olódùmarè, wàá pa dà sí àyè rẹ;+Tí o bá mú àìṣòdodo kúrò ní àgọ́ rẹ,
24 Tí o bá ju wúrà* rẹ sínú iyẹ̀pẹ̀,Tí o sì ju wúrà Ófírì+ sínú àwọn àfonífojì àárín àpáta,
25 Olódùmarè á wá di wúrà* rẹ,Ó sì máa di fàdákà rẹ tó dáa jù.
26 Ìgbà yẹn ni Olódùmarè máa múnú rẹ dùn,Wàá sì yíjú sí Ọlọ́run lókè.
27 O máa bẹ̀ ẹ́, ó sì máa gbọ́ ọ;Wàá sì san àwọn ẹ̀jẹ́ rẹ.
28 Ohunkóhun tí o bá pinnu pé o fẹ́ ṣe máa yọrí sí rere,Ìmọ́lẹ̀ sì máa tàn sí ọ̀nà rẹ.
29 Torí ó máa rẹ̀ ọ́ wálẹ̀ tí o bá fi ìgbéraga sọ̀rọ̀,Àmọ́ ó máa gba onírẹ̀lẹ̀* là.
30 Ó máa gba àwọn aláìṣẹ̀;Torí náà, ó dájú pé tí ọwọ́ rẹ bá mọ́, ó máa gbà ọ́ sílẹ̀.”
Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé
^ Tàbí “ṣé ó ń múnú Olódùmarè dùn.”
^ Ní Héb., “bọ́ aṣọ àwọn tó wà ní ìhòòhò.”
^ Tàbí “aláìlóbìí.”
^ Ní Héb., “páńpẹ́ ẹyẹ.”
^ Tàbí “Ìkùukùu.”
^ Tàbí “òbìrìkìtì.”
^ Tàbí “tí a ké ẹ̀mí wọn kúrú.”
^ Ní Héb., “odò.”
^ Tàbí “wúrà kéékèèké.”
^ Tàbí “wúrà kéékèèké.”
^ Tàbí “ẹni tí ìbànújẹ́ dorí rẹ̀ kodò.”