Jóòbù 26:1-14
26 Jóòbù wá fèsì pé:
2 “Wo bí o ṣe ran ẹni tí kò lágbára lọ́wọ́!
Wo bí o ṣe gba apá tí kò lókun là!+
3 Wo ìmọ̀ràn tó dáa gan-an tí o fún ẹni tí kò gbọ́n!+
Wo bí o ṣe fi ọgbọ́n rẹ tó gbéṣẹ́* hàn ní fàlàlà!*
4 Ta lò ń gbìyànjú láti bá sọ̀rọ̀,Ta ló sì mí sí ọ tí o fi ń sọ àwọn nǹkan bẹ́ẹ̀?*
5 Jìnnìjìnnì bá àwọn tí ikú ti pa;*Wọ́n tiẹ̀ tún rẹlẹ̀ ju omi àtàwọn tó ń gbénú wọn.
6 Ìhòòhò ni Isà Òkú* wà níwájú Ọlọ́run,*+Ibi ìparun* sì wà láìfi ohunkóhun bò ó.
7 Ó na òfúrufú apá àríwá* sórí ibi tó ṣófo,*+Ó fi ayé rọ̀ sórí òfo;
8 Ó wé omi mọ́ inú àwọsánmà* rẹ̀,+Débi pé àwọsánmà ò bẹ́, bí wọ́n tiẹ̀ wúwo;
9 Ó bo ìtẹ́ rẹ̀ ká má bàa rí i,Ó na sánmà rẹ̀ bò ó.+
10 Ó pààlà* sójú òfúrufú àti omi;+Ó fi ààlà sáàárín ìmọ́lẹ̀ àti òkùnkùn.
11 Àní àwọn òpó ọ̀run mì tìtì;Ìbáwí rẹ̀ mú wọn wárìrì.
12 Ó fi agbára rẹ̀ ru òkun sókè,+Ó sì fi òye rẹ̀ fọ́ ẹran ńlá inú òkun* sí wẹ́wẹ́.+
13 Ó fi èémí* rẹ̀ mú kí ojú ọ̀run mọ́ lóló;Ọwọ́ rẹ̀ ń gún ejò tó ń yọ́ bọ́rọ́.*
14 Wò ó! Bíńtín lèyí jẹ́ lára àwọn ọ̀nà rẹ̀;+Ọ̀rọ̀ kẹ́lẹ́kẹ́lẹ́ lásán ló ta sí wa létí nípa rẹ̀!
Ta ló wá lè lóye ààrá ńlá rẹ̀?”+
Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé
^ Tàbí “làákàyè rẹ.”
^ Tàbí “lọ́pọ̀ yanturu.”
^ Ní Héb., “Èémí (ẹ̀mí) ta ló sì ti ọ̀dọ̀ rẹ jáde?”
^ Tàbí “ti sọ di aláìlágbára.”
^ Tàbí “Ṣìọ́ọ̀lù,” ìyẹn ibojì aráyé. Wo Àlàyé Ọ̀rọ̀.
^ Ní Héb., “rẹ̀.”
^ Tàbí “Ábádónì.”
^ Ní Héb., “òfìfo.”
^ Ní Héb., “àríwá.”
^ Tàbí “ìkùukùu.”
^ Ní Héb., “Ó ṣe òbìrìkìtì.”
^ Ní Héb., “Ráhábù.”
^ Tàbí “atẹ́gùn.”
^ Tàbí “tó ń yára lọ.”