Jóòbù 27:1-23

  • Jóòbù pinnu pé òun á máa pa ìwà títọ́ òun mọ́ (1-23)

    • “Mi ò ní fi ìwà títọ́ mi sílẹ̀” (5)

    • Ẹni tí kò mọ Ọlọ́run kò nírètí (8)

    • “Kí ló dé tí ọ̀rọ̀ yín kò nítumọ̀ rárá?” (12)

    • Ohunkóhun ò ní ṣẹ́ kù fáwọn ẹni burúkú (13-23)

27  Jóòbù ń bá ọ̀rọ̀* rẹ̀ lọ, ó ní:   “Bó ṣe dájú pé Ọlọ́run wà láàyè, ẹni tó fi ìdájọ́ òdodo dù mí+Àti bí Olódùmarè ti wà, ẹni tó mú kí n banú jẹ́,*+   Tí èémí mi bá ṣì wà nínú mi,Tí ẹ̀mí látọ̀dọ̀ Ọlọ́run sì wà nínú ihò imú mi,+   Ètè mi ò ní sọ̀rọ̀ àìṣòdodo;Ahọ́n mi ò sì ní sọ* ọ̀rọ̀ ẹ̀tàn!   Kò ṣeé gbọ́ pé kí n pe ẹ̀yin ọkùnrin yìí ní olódodo! Títí màá fi kú, mi ò ní fi ìwà títọ́ mi sílẹ̀!*+   Màá rọ̀ mọ́ òdodo mi, mi ò sì ní jẹ́ kó lọ;+Ọkàn mi ò ní dá mi lẹ́bi* tí mo bá ṣì wà láàyè.*   Kó rí fún ọ̀tá mi bí ẹni burúkú,Àwọn tó ń gbógun tì mí, bí aláìṣòdodo.   Torí ìrètí wo ni ẹni tí kò mọ Ọlọ́run* ní tó bá pa run,+Tí Ọlọ́run bá gba ẹ̀mí* rẹ̀?   Ṣé Ọlọ́run máa gbọ́ igbe rẹ̀,Tí wàhálà bá dé bá a?+ 10  Àbí inú rẹ̀ á máa dùn nínú Olódùmarè? Ṣé á máa ké pe Ọlọ́run nígbà gbogbo? 11  Màá kọ́ yín nípa agbára* Ọlọ́run;Mi ò ní fi nǹkan kan pa mọ́ nípa Olódùmarè. 12  Ẹ wò ó! Tó bá jẹ́ pé gbogbo yín ti rí ìran,Kí ló dé tí ọ̀rọ̀ yín kò nítumọ̀ rárá? 13  Èyí ni ìpín èèyàn burúkú látọ̀dọ̀ Ọlọ́run,+Ogún tí àwọn oníwà ìkà gbà látọ̀dọ̀ Olódùmarè. 14  Tí àwọn ọmọ rẹ̀ bá pọ̀, wọ́n á fi idà pa wọ́n,+Àwọn àtọmọdọ́mọ rẹ̀ ò sì ní ní oúnjẹ tó máa tó wọn. 15  Àjàkálẹ̀ àrùn ló máa sin àwọn tó bá gbẹ̀yìn rẹ̀,Àwọn opó wọn ò sì ní sunkún nítorí wọn. 16  Tó bá tiẹ̀ to fàdákà jọ pelemọ bí erùpẹ̀,Tó sì kó aṣọ olówó ńlá jọ bí amọ̀, 17  Bó tiẹ̀ kó o jọ,Olódodo ló máa wọ̀ ọ́,+Aláìṣẹ̀ sì máa pín fàdákà rẹ̀. 18  Ilé tó kọ́ kò lágbára, ó dà bí ilé òólá,*Bí àtíbàbà+ tí ẹ̀ṣọ́ ṣe. 19  Ó máa lọ́rọ̀ nígbà tó bá dùbúlẹ̀, àmọ́ kò ní kó nǹkan kan jọ;Nígbà tó bá la ojú rẹ̀, kò ní sí nǹkan kan níbẹ̀. 20  Ìbẹ̀rù bò ó bí àkúnya omi;Ìjì gbé e lọ ní òru.+ 21  Atẹ́gùn ìlà oòrùn máa gbé e lọ, kò sì ní sí mọ́;Ó gbá a lọ kúrò ní àyè rẹ̀.+ 22  Ó máa kọ lù ú, kò sì ní ṣàánú rẹ̀+Bó ṣe ń gbìyànjú gbogbo ọ̀nà láti sá lọ kúrò lọ́wọ́ agbára rẹ̀.+ 23  Ó pàtẹ́wọ́ sí i,Ó sì súfèé+ sí i láti àyè rẹ̀.*

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé

Ní Héb., “òwe.”
Tàbí “tó mú kí ọkàn mi gbọgbẹ́.”
Ní Héb., “ráhùn.”
Tàbí “Mi ò ní mú ìwà títọ́ mi kúrò lọ́dọ̀ mi; Mi ò ní jáwọ́ nínú ìwà títọ́ mi.”
Tàbí “kẹ́gàn mi.”
Tàbí “ní gbogbo ọjọ́ ayé mi.”
Tàbí “ọkàn.”
Tàbí “apẹ̀yìndà.”
Tàbí kó jẹ́, “nípasẹ̀ ọwọ́.”
Tàbí “kòkòrò.”
Tàbí kó jẹ́, “Wọ́n pàtẹ́wọ́ sí i, wọ́n sì súfèé sí i láti àyè wọn.”