Jóòbù 30:1-31

  • Jóòbù sọ bí nǹkan ṣe wá yí pa dà fún òun (1-31)

    • Àwọn tí kò ní láárí ń fi ṣe yẹ̀yẹ́ (1-15)

    • Ó jọ pé Ọlọ́run kò ràn án lọ́wọ́ (20, 21)

    • “Awọ ara mi ti dúdú” (30)

30  “Wọ́n ti ń fi mí rẹ́rìn-ín báyìí,+Àwọn ọkùnrin tí kò tó mi lọ́jọ́ orí,Àwọn tí mi ò lè gbà kí bàbá wọnDúró lẹ́gbẹ̀ẹ́ àwọn ajá tó ń ṣọ́ agbo ẹran mi.   Àǹfààní wo ni agbára ọwọ́ wọn ṣe mí? Okun wọn ti ṣègbé.   Àìní àti ebi ti tán wọn lókun;Wọ́n ń họ ilẹ̀ gbígbẹ jẹ,Ilẹ̀ tó ti pa run, tó sì ti di ahoro.   Wọ́n ń kó ewé iyọ̀ jọ látinú igbó;Gbòǹgbò igi wíwẹ́ ni oúnjẹ wọn.   Wọ́n lé wọn kúrò ní ìlú;+Àwọn èèyàn kígbe mọ́ wọn bí ẹni ń kígbe mọ́ olè.   Wọ́n ń gbé ní gẹ̀rẹ́gẹ̀rẹ́ àfonífojì tó jin kòtò,Nínú àwọn ihò inú ilẹ̀ àti inú àpáta.   Wọ́n ń ké jáde látinú igbó,Wọ́n sì kó ara wọn jọ sí àárín èsìsì.   A ti lé wọn kúrò* ní ilẹ̀ náà,Bí àwọn ọmọ òpònú àti àwọn tí kò lórúkọ.   Àmọ́ wọ́n ń fi mí ṣe yẹ̀yẹ́ báyìí kódà nínú orin wọn;+Mo ti di ẹni ẹ̀gàn* lójú wọn.+ 10  Wọ́n kórìíra mi, wọ́n sì jìnnà sí mi;+Ó yá wọn lára láti tutọ́ sí mi lójú.+ 11  Torí Ọlọ́run ti gba ohun ìjà mi,* ó sì rẹ̀ mí sílẹ̀,Wọn ò kóra wọn níjàánu rárá* níwájú mi. 12  Wọ́n dìde ní ọwọ́ ọ̀tún mi bí àwọn jàǹdùkú;Wọ́n mú kí n sá lọ,Wọ́n sì fi àwọn ohun ìdènà tó ń fa ìparun sí ojú ọ̀nà mi. 13  Wọ́n ya àwọn ọ̀nà mi lulẹ̀,Wọ́n sì mú kí àjálù tó dé bá mi le sí i,+Láìsí ẹnikẹ́ni tó dá wọn dúró.* 14  Wọ́n wá bí ẹni pé ihò tó fẹ̀ lára ògiri ni wọ́n gbà kọjá;Wọ́n ya wọlé nígbà ìṣòro. 15  Ìbẹ̀rù bò mí;Wọ́n lé iyì mi lọ bí atẹ́gùn,Ìgbàlà mi sì pòórá bí ìkùukùu. 16  Ní báyìí, ẹ̀mí* mi ń lọ kúrò nínú mi;+Àwọn ọjọ́ ìpọ́njú+ gbá mi mú. 17  Egungun ń ro mí gan-an* ní òru,+Ìrora tó ń já mi jẹ ò dáwọ́ dúró.+ 18  A fi agbára ńlá sọ ẹ̀wù mi di ìdàkudà;*Ó ń fún mọ́ mi lọ́rùn bí ọrùn aṣọ mi. 19  Ọlọ́run ti jù mí sínú ẹrọ̀fọ̀;Ó ti mú kí n dà bí iyẹ̀pẹ̀ àti eérú. 20  Mo ké pè ọ́ pé kí o ràn mí lọ́wọ́, àmọ́ o ò dá mi lóhùn;+Mo dìde dúró, àmọ́ ńṣe lo kàn ń wò mí. 21  O ṣe mí níkà, o sì kẹ̀yìn sí mi;+O fi gbogbo agbára ọwọ́ rẹ gbéjà kò mí. 22  O gbé mi sókè, o sì fi atẹ́gùn gbé mi lọ;O wá ń fi ìjì jù mí kiri.* 23  Torí mo mọ̀ pé wàá mú kí n kú,Kí n lọ sí ibi tí gbogbo alààyè á ti pàdé. 24  Àmọ́ kò sẹ́ni tó máa lu ẹni tí ìbànújẹ́ bá,*+Bó ṣe ń kígbe fún ìrànlọ́wọ́ nígbà tí àjálù bá a. 25  Ṣé mi ò sunkún torí àwọn tí ìṣòro dé bá?* Ṣebí mo* banú jẹ́ torí aláìní?+ 26  Bó tiẹ̀ jẹ́ pé ire ni mò ń retí, ibi ló ṣẹlẹ̀;Mo retí ìmọ́lẹ̀, àmọ́ òkùnkùn ló dé. 27  Inú mi tó ń dà rú kò dáwọ́ dúró;Ọjọ́ ìpọ́njú dé bá mi. 28  Mò ń rìn káàkiri nínú ìbànújẹ́;+ kò sí ìmọ́lẹ̀. Mo dìde nínú àpéjọ, mo sì kígbe fún ìrànlọ́wọ́. 29  Mo ti di arákùnrin àwọn ajáko*Àti ọ̀rẹ́ àwọn abo ọmọ ògòǹgò.+ 30  Awọ ara mi ti dúdú, ó sì ti re dà nù;+Ooru* ti mú kí egungun mi gbóná. 31  Ọ̀fọ̀ nìkan ni háàpù mi wúlò fún,Igbe ẹkún sì ni fèrè* mi wà fún.

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé

Ní Héb., “nà wọ́n kúrò.”
Ní Héb., “àfipòwe.”
Ní Héb., “tú okùn ọrun mi.”
Tàbí “Wọ́n tú ìjánu kúrò.”
Tàbí kó jẹ́, “Láìsí ẹnikẹ́ni tó ń ràn wọ́n lọ́wọ́.”
Tàbí “ọkàn.”
Ní Héb., “Wọ́n dá egungun mi lu.”
Tàbí kó jẹ́, “Ìyà tó ń jẹ mí pọ̀ gan-an débi pé ó sọ mí dìdàkudà.”
Tàbí kó jẹ́, “fọ́ mi yángá.”
Ní Héb., “àwókù.”
Tàbí “tí ìnira ń bá lójúmọ́?”
Tàbí “ọkàn mi.”
Tàbí “akátá.”
Tàbí kó jẹ́, “Ibà.”
Tàbí “fèrè ape.”