Jóòbù 32:1-22
32 Àwọn ọkùnrin mẹ́ta yìí kò fún Jóòbù lésì mọ́, torí ó dá a lójú pé òun jẹ́ olódodo.*+
2 Àmọ́ inú ti bí Élíhù ọmọ Bárákélì ọmọ Búsì+ láti ìdílé Rámù gan-an. Inú bí i gidigidi sí Jóòbù torí bó ṣe ń gbìyànjú láti fi hàn pé òun* jẹ́ olódodo ju Ọlọ́run lọ.+
3 Inú tún bí i gidigidi sí àwọn ọ̀rẹ́ Jóòbù mẹ́tẹ̀ẹ̀ta torí wọn ò mọ bó ṣe yẹ kí wọ́n fèsì, àmọ́ wọ́n pe Ọlọ́run ní ẹni burúkú.+
4 Élíhù ti ń dúró kó lè dá Jóòbù lóhùn, torí pé wọ́n dàgbà jù ú lọ.+
5 Nígbà tí Élíhù rí i pé àwọn ọkùnrin mẹ́tẹ̀ẹ̀ta ò rí nǹkan kan sọ, inú bí i gidigidi.
6 Élíhù ọmọ Bárákélì ọmọ Búsì wá bẹ̀rẹ̀ sí í sọ̀rọ̀, ó ní:
“Ọmọdé ni mí,*Àgbàlagbà sì ni ẹ̀yin.+
Ìdí nìyẹn tí mi ò fi sọ̀rọ̀ torí mo bọ̀wọ̀ fún yín,+Mi ò sì jẹ́ sọ ohun tí mo mọ̀ fún yín.
7 Mo ronú pé, ‘Kí ọjọ́ orí* sọ̀rọ̀,Kí ọ̀pọ̀ ọdún sì kéde ìmọ̀.’
8 Àmọ́ ẹ̀mí tó wà nínú àwọn èèyàn,Èémí Olódùmarè, ló ń fún wọn ní òye.+
9 Ọjọ́ orí nìkan kọ́ ló ń* sọ èèyàn di ọlọ́gbọ́n,Bẹ́ẹ̀ ni kì í ṣe àwọn àgbà nìkan ló mọ ohun tó tọ́.+
10 Torí náà, mo sọ pé, ‘Ẹ fetí sí mi,Màá sì sọ ohun tí mo mọ̀ fún yín.’
11 Ẹ wò ó! Mo ti dúró de ọ̀rọ̀ yín;Mò ń fetí sí ìfèròwérò yín,+Bí ẹ ṣe ń wá ohun tí ẹ máa sọ.+
12 Mo fara balẹ̀ tẹ́tí sí yín,Àmọ́ ìkankan nínú yín ò lè fi hàn pé Jóòbù ṣàṣìṣe,*Ẹ ò sì lè fún un lésì ọ̀rọ̀ rẹ̀.
13 Torí náà, ẹ má sọ pé, ‘A ti rí ọgbọ́n;Ọlọ́run ló lè fi àṣìṣe rẹ̀ hàn, kì í ṣe èèyàn.’
14 Èmi kọ́ ló ń bá wí,Torí náà, mi ò ní fi ọ̀rọ̀ yín fún un lésì.
15 Ìdààmú bá wọn, wọn ò lè fèsì mọ́;Wọn ò ní ohunkóhun sọ mọ́.
16 Mo ti dúró, àmọ́ wọn ò sọ̀rọ̀ mọ́;Wọ́n kàn dúró síbẹ̀, wọn ò fèsì mọ́.
17 Torí náà, èmi náà máa dáhùn;Èmi náà máa sọ ohun tí mo mọ̀;
18 Torí nǹkan pọ̀ tí mo fẹ́ sọ;Ẹ̀mí tó wà nínú mi ń fipá mú mi.
19 Inú mi dà bíi wáìnì tí wọ́n dé pa,Bí àwọn ìgò awọ tuntun tó ti fẹ́ bẹ́.+
20 Jẹ́ kí n sọ̀rọ̀, kí ara lè tù mí!
Màá la ẹnu mi, màá sì fèsì.
21 Mi ò ní ṣe ojúsàájú sí ẹnikẹ́ni;+Mi ò sì ní fi ọ̀rọ̀ dídùn pọ́n ẹnikẹ́ni,*
22 Torí mi ò mọ bí wọ́n ṣe ń fi ọ̀rọ̀ dídùn pọ́n èèyàn;Tí mo bá ṣe bẹ́ẹ̀, Ẹni tó dá mi máa yára mú mi kúrò.
Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé
^ Tàbí “ó jẹ́ olódodo lójú ara rẹ̀.”
^ Tàbí “ọkàn òun.”
^ Ní Héb., “Mo kéré ní ọjọ́.”
^ Ní Héb., “àwọn ọjọ́.”
^ Tàbí “Ọ̀pọ̀ ọjọ́ nìkan kì í.”
^ Tàbí “bá Jóòbù wí.”
^ Tàbí “fún ẹnikẹ́ni ní orúkọ oyè.”