Jóòbù 35:1-16

  • Élíhù sọ àwọn èrò tí kò tọ́ tí Jóòbù ní (1-16)

    • Jóòbù sọ pé òdodo òun ju ti Ọlọ́run lọ (2)

    • Ọlọ́run ga lọ́la, ẹ̀ṣẹ̀ kò sì lè ṣe nǹkan fún un (5, 6)

    • Kí Jóòbù dúró de Ọlọ́run (14)

35  Élíhù ń bá ọ̀rọ̀ rẹ̀ lọ pé:   “Ṣé ó dá ọ lójú pé o jàre tí wàá fi sọ pé,‘Òdodo mi ju ti Ọlọ́run lọ’?+   Torí o sọ pé, ‘Àǹfààní wo nìyẹn ṣe ọ́?* Ṣé mo sàn ju ẹni tó dẹ́ṣẹ̀ lọ ni?’+   Màá fún ọ lésì,Màá sì fún àwọn ọ̀rẹ́ rẹ+ tó wà lọ́dọ̀ rẹ lésì.   Gbé ojú sókè ọ̀run, kí o sì wò,Wo àwọsánmà,*+ tó wà lókè rẹ.   Tí o bá ṣẹ̀, kí lo ṣe tó dùn ún?+ Tí àṣìṣe rẹ bá ń pọ̀ sí i, kí lo ṣe fún un?+   Tí o bá jẹ́ olódodo, kí lo fún un;Kí ló gbà lọ́wọ́ rẹ?+   Èèyàn bíi tìẹ ni ìwà burúkú rẹ lè ṣàkóbá fún,Ọmọ aráyé nìkan sì ni òdodo rẹ wà fún.   Àwọn èèyàn máa ń ké jáde tí ìnira bá mu wọ́n lómi;Wọ́n á kígbe kí wọ́n lè bọ́ lọ́wọ́ alágbára tó ń jẹ gàba lé wọn lórí.+ 10  Àmọ́ ẹnì kankan ò sọ pé, ‘Ọlọ́run mi dà, Aṣẹ̀dá mi Atóbilọ́lá,+Ẹni tó ń mú ká kọrin ní òru?’+ 11  Ó ń kọ́ wa+ ju àwọn ẹranko orí ilẹ̀+ lọ,Ó sì ń mú ká gbọ́n ju àwọn ẹyẹ ojú ọ̀run lọ. 12  Àwọn èèyàn ń ké jáde, àmọ́ kò dáhùn,+Torí ìgbéraga àwọn ẹni burúkú.+ 13  Ó dájú pé Ọlọ́run kì í fetí sí igbe asán;*+Olódùmarè kì í fiyè sí i. 14  Ká má tiẹ̀ wá sọ ti àròyé tí ò ń ṣe pé o kò rí i!+ Ẹjọ́ rẹ wà níwájú rẹ̀, torí náà dúró dè é, kí o sì máa retí rẹ̀.+ 15  Torí kò fi ìbínú pè ọ́ láti wá jíhìn;Bẹ́ẹ̀ ni kò ka ìwàǹwára rẹ tó le gan-an sí.+ 16  Jóòbù kàn ń la ẹnu lásán ni;Ó sọ̀rọ̀ púpọ̀ láìní ìmọ̀.”+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé

Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ Ọlọ́run ló ń tọ́ka sí.
Tàbí “ìkùukùu.”
Tàbí “irọ́.”