Jóòbù 42:1-17

  • Jóòbù dá Jèhófà lóhùn (1-6)

  • Ọlọ́run bínú sí àwọn ọ̀rẹ́ Jóòbù mẹ́tẹ̀ẹ̀ta (7-9)

  • Jèhófà pa dà bù kún Jóòbù (10-17)

    • Àwọn ọmọ Jóòbù lọ́kùnrin àti lóbìnrin (13-15)

42  Lẹ́yìn náà, Jóòbù dá Jèhófà lóhùn pé:   “Mo ti wá mọ̀ pé o lè ṣe ohun gbogboÀti pé kò sí ohun tó wà lọ́kàn rẹ tí kò ní ṣeé ṣe fún ọ.+   O sọ pé, ‘Ta lẹni yìí tí kò jẹ́ kí ìmọ̀ràn mi ṣe kedere, tí kò ní ìmọ̀?’+ Torí náà, mo sọ̀rọ̀, àmọ́ mi ò lóye,Nípa àwọn ohun tó yà mí lẹ́nu gidigidi, tí mi ò mọ̀.+   O sọ pé, ‘Jọ̀ọ́ fetí sílẹ̀, màá sì sọ̀rọ̀. Màá bi ọ́ ní ìbéèrè, kí o sì dá mi lóhùn.’+   Etí mi ti gbọ́ nípa rẹ,Àmọ́ ní báyìí, mo ti fi ojú mi rí ọ.   Ìdí nìyẹn tí mo fi kó ọ̀rọ̀ mi jẹ,*+Mo sì ronú pìwà dà nínú iyẹ̀pẹ̀ àti eérú.”+  Lẹ́yìn tí Jèhófà bá Jóòbù sọ àwọn ọ̀rọ̀ yìí, Jèhófà sọ fún Élífásì ará Témánì pé: “Inú ń bí mi gidigidi sí ìwọ àtàwọn ọ̀rẹ́ rẹ méjèèjì,+ torí ẹ ò sọ òtítọ́ nípa mi,+ bí ìránṣẹ́ mi Jóòbù ṣe sọ òtítọ́.  Ó yá, ẹ mú akọ màlúù méje àti àgbò méje, kí ẹ lọ bá Jóòbù ìránṣẹ́ mi, kí ẹ sì rú ẹbọ sísun fún ara yín. Jóòbù ìránṣẹ́ mi sì máa gbàdúrà fún yín.+ Ó dájú pé màá gbọ́ ẹ̀bẹ̀ rẹ̀* pé kí n má fìyà jẹ yín nítorí ìwà òmùgọ̀ yín, torí ẹ ò sọ òtítọ́ nípa mi, bí ìránṣẹ́ mi Jóòbù ṣe sọ òtítọ́.”  Nítorí náà, Élífásì ará Témánì, Bílídádì ọmọ Ṣúáhì àti Sófárì ọmọ Náámà lọ ṣe ohun tí Jèhófà sọ fún wọn pé kí wọ́n ṣe. Jèhófà sì gbọ́ àdúrà Jóòbù. 10  Lẹ́yìn tí Jóòbù gbàdúrà fún àwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀,+ Jèhófà mú kí ìpọ́njú Jóòbù kúrò,+ ó sì dá ọlá rẹ̀ pa dà.* Jèhófà fún un ní ìlọ́po méjì ohun tó ní tẹ́lẹ̀.+ 11  Gbogbo àwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin rẹ̀ àti gbogbo àwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀ tẹ́lẹ̀+ wá sọ́dọ̀ rẹ̀, wọ́n sì bá a jẹun nínú ilé rẹ̀. Wọ́n bá a kẹ́dùn, wọ́n sì tù ú nínú torí gbogbo àjálù tí Jèhófà fàyè gbà kó dé bá a. Ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn fún un ní ẹyọ owó àti òrùka wúrà. 12  Jèhófà wá bù kún ìgbẹ̀yìn ayé Jóòbù ju ti ìbẹ̀rẹ̀ lọ,+ Jóòbù wá ní ẹgbẹ̀rún mẹ́rìnlá (14,000) àgùntàn, ẹgbẹ̀rún mẹ́fà (6,000) ràkúnmí, màlúù méjì-méjì lọ́nà ẹgbẹ̀rún (1,000) àti ẹgbẹ̀rún (1,000) abo kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́.+ 13  Ó tún wá bí ọmọkùnrin méje míì àti ọmọbìnrin mẹ́ta míì.+ 14  Ó pe orúkọ ọmọbìnrin àkọ́kọ́ ní Jẹ̀mímà, ìkejì ní Kẹsáyà àti ìkẹta ní Kereni-hápúkì. 15  Ní gbogbo ilẹ̀ náà, kò sí obìnrin kankan tó rẹwà bí àwọn ọmọbìnrin Jóòbù, bàbá wọn sì fún wọn ní ogún pẹ̀lú àwọn arákùnrin wọn. 16  Lẹ́yìn èyí, Jóòbù lo ogóje (140) ọdún sí i láyé, ó sì rí àwọn ọmọ rẹ̀ àti àwọn ọmọ ọmọ rẹ̀, dé ìran kẹrin. 17  Nígbẹ̀yìn-gbẹ́yín, Jóòbù kú. Ó pẹ́ láyé, ayé rẹ̀ sì dáa.*

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé

Tàbí “yíhùn pa dà.”
Ní Héb., “Ó dájú pé màá gbé ojú rẹ̀ sókè.”
Ní Héb., “Jèhófà mú ìdè Jóòbù kúrò.”
Ní Héb., “Ó darúgbó, ó sì lọ́jọ́ lórí.”