Jóòbù 5:1-27
5 “Jọ̀ọ́ pè! Ṣé ẹnikẹ́ni dá ọ lóhùn?
Èwo nínú àwọn ẹni mímọ́ lo máa yíjú sí?
2 Ìbínú tí òmùgọ̀ dì sínú ló máa pa á,Ìlara ló sì máa pa ẹni tí kò láròjinlẹ̀.
3 Mo ti rí i tí òmùgọ̀ ta gbòǹgbò,Àmọ́ lójijì, wọ́n gégùn-ún fún ibi tó ń gbé.
4 Àwọn ọmọ rẹ̀ jìnnà sí ààbò,Wọ́n sì tẹ̀ wọ́n rẹ́ ní ẹnubodè+ ìlú láìsí ẹni tó máa gbà wọ́n sílẹ̀.
5 Ẹni tí ebi ń pa jẹ ohun tó kórè,Àárín àwọn ẹ̀gún pàápàá ló ti mú un,Wọ́n dẹkùn mú àwọn ohun ìní wọn.
6 Torí ohun tó léwu kì í hù látinú iyẹ̀pẹ̀,Wàhálà kì í sì í hù látinú ilẹ̀.
7 Torí inú wàhálà ni wọ́n ń bí èèyàn sí,Bó ṣe dájú pé iná máa ń ta pàrà sókè.
8 Àmọ́ màá mú ọ̀rọ̀ mi tọ Ọlọ́run lọ,Ọlọ́run sì ni màá gbé ẹjọ́ mi lọ bá,
9 Sọ́dọ̀ Ẹni tó ń ṣe àwọn ohun ńlá àtàwọn ohun àwámáridìí,Àwọn ohun àgbàyanu tí kò níye.
10 Ó ń rọ òjò sí ayé,Ó sì ń bomi rin oko.
11 Ó ń gbé ẹni tó rẹlẹ̀ ga,Ó sì ń gbé ẹni tí inú rẹ̀ bà jẹ́ sókè fún ìgbàlà.
12 Ó ń sọ ohun tí àwọn ọlọ́gbọ́n ẹ̀wẹ́ ń hùmọ̀ di asán,Kí iṣẹ́ ọwọ́ wọn má bàa yọrí sí rere.
13 Ó ń mú àwọn ọlọ́gbọ́n nínú ọgbọ́n ẹ̀wẹ́ wọn,+Kó lè da ète àwọn ọlọ́gbọ́n rú.
14 Wọ́n rí òkùnkùn ní ọ̀sán,Wọ́n sì ń táràrà kiri ní ọ̀sán gangan bíi pé òru ni.
15 Ó ń gbani lọ́wọ́ idà ẹnu wọn,Ó ń gba aláìní lọ́wọ́ alágbára,
16 Kí ẹni tó rẹlẹ̀ lè ní ìrètí,Àmọ́ a pa àìṣòdodo lẹ́nu mọ́.
17 Wò ó! Aláyọ̀ ni ẹni tí Ọlọ́run bá wí;Torí náà, má ṣe kọ ìbáwí Olódùmarè!
18 Torí ó ń fa ìrora, àmọ́ ó ń di ọgbẹ́;Ó ń fọ́ nǹkan sí wẹ́wẹ́, àmọ́ ó ń fi ọwọ́ ara rẹ̀ ṣe ìwòsàn.
19 Ó máa gbà ọ́ lọ́wọ́ àjálù mẹ́fà,Ìkeje pàápàá kò ní ṣe ọ́ lọ́ṣẹ́.
20 Ó máa rà ọ́ pa dà lọ́wọ́ ikú lásìkò ìyànÀti lọ́wọ́ agbára idà nígbà ogun.
21 Ó máa dáàbò bò ọ́ lọ́wọ́ pàṣán ahọ́n,+O ò sì ní bẹ̀rù ìparun nígbà tó bá dé.
22 O máa fi ìparun àti ebi rẹ́rìn-ín,O ò sì ní bẹ̀rù àwọn ẹran inú igbó.
23 Torí àwọn òkúta inú pápá kò ní ṣe ọ́ léṣe,*Àwọn ẹranko sì máa wà ní àlàáfíà pẹ̀lú rẹ.
24 O máa mọ̀ pé kò sí ewu ní àgọ́ rẹ,*O ò sì ní wá ohunkóhun ní àwátì tí o bá ń yẹ ibi ìjẹko rẹ wò.
25 O máa bí ọmọ tó pọ̀,Àwọn àtọmọdọ́mọ rẹ á sì pọ̀ bí ewéko ilẹ̀.
26 Ara rẹ ṣì máa le koko nígbà tí o bá lọ sínú sàréè,Bí ìtí ọkà tí wọ́n kó jọ ní àkókò wọn.
27 Wò ó! A ti wádìí èyí, bẹ́ẹ̀ ló sì rí.
Fetí sílẹ̀, kí o sì fara mọ́ ọn.”