Jóòbù 7:1-21
7 “Ǹjẹ́ ìgbésí ayé ẹni kíkú lórí ilẹ̀ kò dà bí iṣẹ́ àṣekára tó pọn dandan?
Ṣé kì í ṣe bíi ti alágbàṣe ni àwọn ọjọ́ rẹ̀ rí?+
2 Ó ń retí òjìji bíi ti ẹrú,Ó sì ń dúró de owó iṣẹ́ rẹ̀ bíi ti alágbàṣe.+
3 Torí náà, a ti yan àwọn oṣù asán fún mi,Àwọn òru ìbànújẹ́ ni a sì ti kà sílẹ̀ fún mi.+
4 Nígbà tí mo dùbúlẹ̀, mo béèrè pé, ‘Ìgbà wo ni màá dìde?’+
Àmọ́ bí òru náà ṣe ń falẹ̀, ṣe ni mò ń yí kiri títí ilẹ̀ fi mọ́.*
5 Ìdin àti iyẹ̀pẹ̀ tó ṣù pọ̀ bo ara mi;+Gbogbo awọ ara mi ti sé èépá, ó sì ń ṣọyún.+
6 Àwọn ọjọ́ mi ń yára sáré ju ohun èlò tí wọ́n fi ń hun aṣọ,+Wọ́n sì dópin láìnírètí.+
7 Rántí pé afẹ́fẹ́ ni ẹ̀mí mi,+Pé ojú mi kò tún ní rí ayọ̀* mọ́.
8 Ojú tó rí mi báyìí kò ní rí mi mọ́;Ojú rẹ máa wá mi, àmọ́ mi ò ní sí mọ́.+
9 Bí ìkùukùu tó ń pa rẹ́ lọ, tó sì wá pòórá,Ẹni tó lọ sí Isà Òkú* kì í pa dà wá.+
10 Kò ní pa dà sí ilé rẹ̀ mọ́,Ibùgbé rẹ̀ kò sì ní mọ̀ ọ́n mọ́.+
11 Torí náà, mi ò ní pa ẹnu mi mọ́.
Màá sọ̀rọ̀ látinú ìrora ẹ̀mí mi,Màá ṣàròyé látinú ẹ̀dùn ọkàn* tó bá mi!+
12 Ṣé èmi ni òkun tàbí ẹran ńlá inú òkun,Tí o fi máa yan ẹ̀ṣọ́ tì mí?
13 Nígbà tí mo sọ pé, ‘Àga mi máa tù mí nínú;Ibùsùn mi máa bá mi dín ìbànújẹ́ mi kù,’
14 O wá fi àwọn àlá dẹ́rù bà mí,O sì fi àwọn ìran dáyà já mi,
15 Tó fi jẹ́ pé mo* fara mọ́ ọn kí wọ́n sé mi léèémí,Àní, ikú dípò ara mi yìí.*+
16 Mo kórìíra ayé mi gidigidi;+ mi ò fẹ́ wà láàyè mọ́.
Fi mí sílẹ̀, torí àwọn ọjọ́ mi dà bí èémí.+
17 Kí ni ẹni kíkú jẹ́ tí o fi máa rí tiẹ̀ rò,Tí o sì máa fún un ní àfiyèsí?*+
18 Kí ló dé tí ò ń yẹ̀ ẹ́ wò ní àràárọ̀,Tí o sì ń dán an wò ní ìṣẹ́jú-ìṣẹ́jú?+
19 Ṣé o ò ní gbójú kúrò lọ́dọ̀ mi ni,Kí o sì fi mí sílẹ̀ kí n lè ráyè gbé itọ́ mì?+
20 Tí mo bá ṣẹ̀, ṣé mo lè ṣe ọ́ níbi, ìwọ Ẹni tó ń kíyè sí aráyé?+
Kí ló dé tí o dájú sọ mí?
Àbí mo ti di ìnira fún ọ ni?
21 Kí ló dé tí o ò dárí ẹ̀ṣẹ̀ mi jì,Kí o sì gbójú fo àṣìṣe mi?
Torí láìpẹ́, màá dùbúlẹ̀ sínú erùpẹ̀,+O máa wá mi, àmọ́ mi ò ní sí mọ́.”
Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé
^ Tàbí “títí di àfẹ̀mọ́jú.”
^ Ní Héb., “ohun rere.”
^ Tàbí “Ṣìọ́ọ̀lù,” ìyẹn ibojì aráyé. Wo Àlàyé Ọ̀rọ̀.
^ Tàbí “ọgbẹ́ ọkàn.”
^ Tàbí “ọkàn mi.”
^ Ní Héb., “àwọn egungun mi.”
^ Ní Héb., “fi ọkàn rẹ sí i.”