Jóṣúà 13:1-33

  • Àwọn ilẹ̀ tí wọn ò tíì gbà (1-7)

  • Wọ́n pín ilẹ̀ tó wà ní ìlà oòrùn Jọ́dánì (8-14)

  • Ogún Rúbẹ́nì (15-23)

  • Ogún Gádì (24-28)

  • Ogún Mánásè ní ìlà oòrùn (29-32)

  • Jèhófà ni ogún àwọn ọmọ Léfì (33)

13  Ní báyìí, Jóṣúà ti darúgbó, ó sì ti lọ́jọ́ lórí.+ Jèhófà sọ fún un pé: “O ti darúgbó, o sì ti lọ́jọ́ lórí; àmọ́ ẹ ò tíì gba* èyí tó pọ̀ jù nínú ilẹ̀ náà.  Àwọn ilẹ̀ tó ṣẹ́ kù nìyí:+ gbogbo ilẹ̀ àwọn Filísínì àti ti gbogbo àwọn ará Géṣúrì+  (láti ẹ̀ka odò Náílì* tó wà ní ìlà oòrùn* Íjíbítì títí dé ààlà Ẹ́kírónì lọ sí àríwá, tí wọ́n máa ń pè ní ilẹ̀ àwọn ọmọ Kénáánì)+ pẹ̀lú ilẹ̀ àwọn alákòóso Filísínì márààrún,+ ìyẹn àwọn ará Gásà, àwọn ará Áṣídódì,+ àwọn ará Áṣíkẹ́lónì,+ àwọn ará Gátì+ àti àwọn ará Ẹ́kírónì;+ ilẹ̀ àwọn Áfímù+  lọ sí apá gúúsù; gbogbo ilẹ̀ àwọn ọmọ Kénáánì; Méárà, tó jẹ́ ti àwọn ọmọ Sídónì,+ títí lọ dé Áfékì, dé ààlà àwọn Ámórì;  ilẹ̀ àwọn ará Gébálì+ àti gbogbo Lẹ́bánónì lápá ìlà oòrùn, láti Baali-gádì ní ìsàlẹ̀ Òkè Hámónì títí dé Lebo-hámátì;*+  gbogbo àwọn tó ń gbé agbègbè olókè láti Lẹ́bánónì+ lọ dé Misirefoti-máímù;+ àti gbogbo àwọn ọmọ Sídónì.+ Mo máa lé wọn kúrò* níwájú àwọn ọmọ Ísírẹ́lì.+ Kí o ṣáà rí i pé o pín in fún Ísírẹ́lì pé kó jẹ́ ogún wọn, bí mo ṣe pa á láṣẹ fún ọ.+  Kí o pín ilẹ̀ yìí fún ẹ̀yà mẹ́sàn-án àti ààbọ̀ ẹ̀yà Mánásè pé kó jẹ́ ogún wọn.”+  Àwọn ọmọ Rúbẹ́nì, àwọn ọmọ Gádì àti ààbọ̀ ẹ̀yà tó kù, wá gba ogún wọn tí Mósè fún wọn lápá ìlà oòrùn Jọ́dánì, bí Mósè ìránṣẹ́ Jèhófà ṣe fún wọn:+  láti Áróérì,+ tó wà létí Àfonífojì Áánónì+ àti ìlú tó wà láàárín àfonífojì náà àti gbogbo ilẹ̀ tó tẹ́jú* ní Médébà títí dé Díbónì; 10  àti gbogbo ìlú Síhónì ọba àwọn Ámórì, tó jọba ní Hẹ́ṣíbónì, títí dé ààlà àwọn ọmọ Ámónì;+ 11  pẹ̀lú Gílíádì àti ilẹ̀ àwọn ará Géṣúrì àti tàwọn ará Máákátì+ àti gbogbo Òkè Hámónì pẹ̀lú gbogbo Báṣánì+ títí lọ dé Sálékà;+ 12  gbogbo ilẹ̀ ọba Ógù ní Báṣánì, tó jọba ní Áṣítárótì àti Édíréì. (Ó jẹ́ ọ̀kan lára àwọn Réfáímù+ tó kẹ́yìn.) Mósè ṣẹ́gun wọn, ó sì lé wọn kúrò.*+ 13  Àmọ́ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì kò lé+ àwọn ará Géṣúrì àti àwọn ará Máákátì kúrò,* torí àwọn Géṣúrì àti Máákátì ṣì wà láàárín Ísírẹ́lì títí di òní yìí. 14  Ẹ̀yà àwọn ọmọ Léfì nìkan ni kò pín ogún fún.+ Àwọn ọrẹ àfinásun sí Jèhófà Ọlọ́run Ísírẹ́lì ni ogún wọn,+ bó ṣe ṣèlérí fún wọn.+ 15  Mósè pín ogún fún ẹ̀yà àwọn ọmọ Rúbẹ́nì ní ìdílé-ìdílé, 16  ilẹ̀ wọn bẹ̀rẹ̀ láti Áróérì, tó wà létí Àfonífojì Áánónì àti ìlú tó wà láàárín àfonífojì náà pẹ̀lú gbogbo ilẹ̀ tó tẹ́jú lẹ́gbẹ̀ẹ́ Médébà; 17  Hẹ́ṣíbónì àti gbogbo ìlú rẹ̀+ tó wà lórí ilẹ̀ tó tẹ́jú, Díbónì, Bamoti-báálì, Bẹti-baali-méónì,+ 18  Jáhásì,+ Kédémótì,+ Mẹ́fáátì,+ 19  Kiriátáímù, Síbúmà,+ Sereti-ṣáhà lórí òkè tó wà ní àfonífojì,* 20  Bẹti-péórì, gẹ̀rẹ́gẹ̀rẹ́ Písígà,+ Bẹti-jẹ́ṣímótì,+ 21  gbogbo ìlú tó wà lórí ilẹ̀ tó tẹ́jú àti gbogbo ilẹ̀ Síhónì ọba àwọn Ámórì, tó jọba ní Hẹ́ṣíbónì.+ Mósè ṣẹ́gun òun+ àtàwọn ìjòyè Mídíánì, ìyẹn Éfì, Rékémù, Súúrì, Húrì àti Rébà,+ àwọn ọba tó wà lábẹ́ Síhónì, tí wọ́n ń gbé ilẹ̀ náà. 22  Àwọn ọmọ Ísírẹ́lì fi idà pa Báláámù+ ọmọ Béórì, tó jẹ́ woṣẹ́woṣẹ́+ pẹ̀lú àwọn yòókù tí wọ́n pa. 23  Jọ́dánì ni ààlà àwọn ọmọ Rúbẹ́nì; ilẹ̀ yìí sì ni ogún àwọn ọmọ Rúbẹ́nì ní ìdílé-ìdílé, pẹ̀lú àwọn ìlú náà àtàwọn ìgbèríko wọn. 24  Bákan náà, Mósè pín ogún fún ẹ̀yà Gádì, àwọn ọmọ Gádì ní ìdílé-ìdílé, 25  ara ilẹ̀ wọn sì ni Jásérì+ àti gbogbo ìlú tó wà ní Gílíádì pẹ̀lú ìdajì ilẹ̀ àwọn ọmọ Ámónì+ títí dé Áróérì, èyí tó dojú kọ Rábà;+ 26  láti Hẹ́ṣíbónì+ dé Ramati-mísípè àti Bẹ́tónímù àti láti Máhánáímù+ títí dé ààlà Débírì; 27  àti ní àfonífojì,* Bẹti-hárámù, Bẹti-nímírà,+ Súkótù+ àti Sáfónì, èyí tó kù nínú ilẹ̀ Síhónì ọba Hẹ́ṣíbónì,+ tí Jọ́dánì jẹ́ ààlà rẹ̀ láti apá ìsàlẹ̀ Òkun Kínérétì*+ lápá ìlà oòrùn Jọ́dánì. 28  Ogún àwọn ọmọ Gádì nìyí ní ìdílé-ìdílé, pẹ̀lú àwọn ìlú náà àtàwọn ìgbèríko wọn. 29  Yàtọ̀ síyẹn, Mósè pín ogún fún ààbọ̀ ẹ̀yà Mánásè, ìdajì nínú ẹ̀yà Mánásè ní ìdílé-ìdílé.+ 30  Ilẹ̀ wọn bẹ̀rẹ̀ láti Máhánáímù+ tó fi mọ́ gbogbo Báṣánì, gbogbo ilẹ̀ Ógù ọba Báṣánì àti gbogbo abúlé Jáírì+ tí wọ́n pàgọ́ sí ní Báṣánì, ó jẹ́ ọgọ́ta (60) ìlú. 31  Ìdajì Gílíádì pẹ̀lú Áṣítárótì àti Édíréì,+ àwọn ìlú tó wà ní ilẹ̀ ọba Ógù ní Báṣánì, di ti àwọn ọmọ Mákírù,+ ọmọ Mánásè, ìyẹn ìdajì àwọn ọmọ Mákírù ní ìdílé-ìdílé. 32  Èyí ni ogún tí Mósè pín fún wọn ní aṣálẹ̀ tó tẹ́jú ní Móábù ní ìkọjá Jọ́dánì, lápá ìlà oòrùn Jẹ́ríkò.+ 33  Àmọ́ Mósè ò fún ẹ̀yà àwọn ọmọ Léfì ní ogún kankan.+ Jèhófà Ọlọ́run Ísírẹ́lì ni ogún wọn, bó ṣe ṣèlérí fún wọn.+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé

Tàbí “ṣẹ́gun.”
Ní Héb., “níwájú.”
Tàbí “láti Ṣíhórì.”
Tàbí “àbáwọlé Hámátì.”
Tàbí “mú wọn kúrò lórí ilẹ̀ wọn.”
Tàbí “òkè tí orí rẹ̀ rí pẹrẹsẹ.”
Tàbí “mú wọn kúrò lórí ilẹ̀ wọn.”
Tàbí “kúrò lórí ilẹ̀ wọn.”
Tàbí “pẹ̀tẹ́lẹ̀.”
Ìyẹn, adágún odò Jẹ́nẹ́sárẹ́tì tàbí Òkun Gálílì.
Tàbí “pẹ̀tẹ́lẹ̀.”