Jónà 1:1-17
1 Jèhófà bá Jónà*+ ọmọ Ámítáì sọ̀rọ̀, ó ní:
2 “Gbéra, lọ sí Nínéfè+ ìlú ńlá náà, kí o sì kéde ìdájọ́ mi fún wọn, torí mo ti rí gbogbo ìwà burúkú wọn.”
3 Àmọ́ Jónà fẹ́ lọ sí Táṣíṣì, kó lè sá fún Jèhófà. Torí náà, ó gbéra, ó lọ sí Jópà, ó sì rí ọkọ̀ òkun kan tó ń lọ sí Táṣíṣì. Ó san owó ọkọ̀, ó sì wọlé láti bá wọn lọ sí Táṣíṣì, kó lè sá fún Jèhófà.
4 Lẹ́yìn náà, Jèhófà mú kí ìjì kan tó lágbára jà lórí òkun, ìjì náà sì le débi pé ọkọ̀ náà fẹ́rẹ̀ẹ́ ya.
5 Ẹ̀rù ba àwọn atukọ̀ òkun náà gan-an, kálukú wọn sì bẹ̀rẹ̀ sí í ké pe ọlọ́run rẹ̀ pé kó ran òun lọ́wọ́. Ni wọ́n bá ń ju àwọn nǹkan tó wà nínú ọkọ̀ náà sínú òkun, kó lè fúyẹ́.+ Àmọ́ Jónà ti lọ dùbúlẹ̀ sí ìsàlẹ̀ ọkọ̀* náà, ó sì ti sùn lọ fọnfọn.
6 Lẹ́yìn náà, ọ̀gá àwọn atukọ̀ lọ bá a, ó sì sọ fún un pé: “Kí ló dé tí ò ń sùn? Dìde, ké pe ọlọ́run rẹ! Bóyá Ọlọ́run tòótọ́ á tiẹ̀ ṣàánú wa, ká má bàa ṣègbé.”+
7 Wọ́n wá sọ fún ara wọn pé: “Ẹ wá, ẹ jẹ́ ká ṣẹ́ kèké,+ ká lè mọ ẹni tó fa àjálù yìí.” Ni wọ́n bá ṣẹ́ kèké, kèké sì mú Jónà.+
8 Torí náà, wọ́n bi í pé: “Jọ̀ọ́ sọ fún wa, ta ló fa àjálù yìí? Iṣẹ́ wo lò ń ṣe, ibo lo ti wá? Ọmọ orílẹ̀-èdè wo ni ọ́, ẹ̀yà wo lo sì ti wá?”
9 Jónà fèsì pé: “Hébérù ni mí. Jèhófà Ọlọ́run ọ̀run, Ẹni tó dá òkun àti ilẹ̀ gbígbẹ ni mò ń sìn.”*
10 Èyí dẹ́rù ba àwọn ọkùnrin náà gan-an, wọ́n sì bí i pé: “Kí lo ṣe?” (Àwọn ọkùnrin náà ti mọ̀ pé ó ń sá fún Jèhófà, torí ó ti sọ fún wọn.)
11 Wọ́n wá bi í pé: “Kí ni ká ṣe sí ọ, kí òkun bàa lè pa rọ́rọ́ fún wa?” Torí ìjì náà túbọ̀ ń le sí i.
12 Ó fèsì pé: “Ẹ gbé mi, kí ẹ sì jù mí sínú òkun, òkun yóò sì pa rọ́rọ́ fún yín; torí mo mọ̀ pé èmi ni mo fa ìjì líle tó dé bá yín.”
13 Àmọ́ àwọn ọkùnrin náà fi gbogbo okun wọn tukọ̀ náà* kí wọ́n lè ṣẹ́rí rẹ̀ pa dà sí etíkun, ṣùgbọ́n wọn ò rí i ṣe, torí ìjì náà ń le sí i níbi tí wọ́n wà.
14 Ni wọ́n bá ké pe Jèhófà, wọ́n sì sọ pé: “Jèhófà, jọ̀ọ́, má ṣe jẹ́ ká ṣègbé nítorí ọkùnrin yìí!* Jèhófà, jọ̀ọ́ má ka ẹ̀jẹ̀ aláìṣẹ̀ sí wa lọ́rùn, torí o ti ṣe ohun tí o fẹ́.”
15 Lẹ́yìn náà, wọ́n gbé Jónà, wọ́n sì jù ú sínú òkun; bí òkun náà ṣe pa rọ́rọ́ nìyẹn.
16 Èyí mú kí àwọn ọkùnrin náà bẹ̀rù Jèhófà gan-an,+ torí náà, wọ́n rúbọ sí Jèhófà, wọ́n sì jẹ́ ẹ̀jẹ́.
17 Jèhófà wá mú kí ẹja ńlá kan gbé Jónà mì, ọjọ́ mẹ́ta* sì ni Jónà fi wà nínú ikùn ẹja náà.+
Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé
^ Ó túmọ̀ sí “Àdàbà.”
^ Tàbí “ọkọ̀ òkun alájà òkè.”
^ Ní Héb., “bẹ̀rù.”
^ Tàbí “wá bí wọ́n ṣe máa kọjá.”
^ Tàbí “nítorí ọkàn ọkùnrin yìí!”
^ Ní Héb., “ọ̀sán mẹ́ta àti òru mẹ́ta.”