Jeremáyà 18:1-23

  • Amọ̀ tó wà lọ́wọ́ amọ̀kòkò (1-12)

  • Jèhófà kẹ̀yìn sí Ísírẹ́lì (13-17)

  • Wọ́n gbìmọ̀ ibi sí Jeremáyà; ó ké pe Ọlọ́run (18-23)

18  Ọ̀rọ̀ tí Jèhófà bá Jeremáyà sọ nìyí, ó ní:  “Dìde, kí o sì lọ sí ilé amọ̀kòkò,+ ibẹ̀ sì ni màá ti jẹ́ kí o gbọ́ ọ̀rọ̀ mi.”  Torí náà, mo lọ sí ilé amọ̀kòkò, ó sì ń ṣiṣẹ́ lórí àgbá kẹ̀kẹ́ amọ̀kòkò.  Àmọ́, ohun tí amọ̀kòkò ń fi amọ̀ ṣe bà jẹ́ lọ́wọ́ rẹ̀. Amọ̀kòkò náà wá fi ṣe ohun míì, bó ṣe dáa lójú rẹ̀.*  Ìgbà náà ni Jèhófà bá mi sọ̀rọ̀, ó ní:  “‘Ṣé mi ò lè ṣe yín bí amọ̀kòkò yìí ti ṣe ni, ẹ̀yin ilé Ísírẹ́lì?’ ni Jèhófà wí. ‘Wò ó! Bí amọ̀ ṣe rí lọ́wọ́ amọ̀kòkò, bẹ́ẹ̀ ni ẹ rí lọ́wọ́ mi, ẹ̀yin ilé Ísírẹ́lì.+  Nígbà tí mo bá sọ pé màá fa orílẹ̀-èdè kan tàbí ìjọba kan tu, tí mo sọ pé màá ya á lulẹ̀, tí màá sì pa á run,+  bí orílẹ̀-èdè náà bá jáwọ́ nínú ìwà burúkú rẹ̀ tí mo kìlọ̀ fún un, èmi náà á pèrò dà* lórí àjálù tí mo ti sọ pé màá jẹ́ kó dé bá a.+  Àmọ́, tí mo bá sọ pé màá kọ́ orílẹ̀-èdè kan tàbí ìjọba kan, tí mo sọ pé màá gbìn ín, 10  tó bá ṣe ohun tó burú lójú mi, tí kò sì ṣègbọràn sí ohùn mi, ńṣe ni màá pèrò dà* nípa ohun rere tí mo sọ pé màá ṣe fún un.’ 11  “Ní báyìí, jọ̀wọ́ sọ fún àwọn èèyàn Júdà àti àwọn tó ń gbé ní Jerúsálẹ́mù pé, ‘Ohun tí Jèhófà sọ nìyí: “Wò ó, mò ń ṣètò àjálù kan fún yín, mo sì ń pète ohun kan fún yín. Torí náà, ẹ jọ̀wọ́, ẹ yí pa dà kúrò ní ọ̀nà búburú yín, kí ẹ sì tún ọ̀nà yín àti ìwà yín ṣe.”’”+ 12  Àmọ́ wọ́n sọ pé: “Kò sí ìrètí!+ Torí pé tinú wa la máa ṣe, ẹnì kọ̀ọ̀kan wa máa ya alágídí, tí á sì máa ṣe ohun tí ọkàn burúkú rẹ̀ ń sọ.”+ 13  Nítorí náà, ohun tí Jèhófà sọ nìyí: “Ẹ jọ̀wọ́, ẹ béèrè lọ́wọ́ àwọn orílẹ̀-èdè. Ta ló ti gbọ́ irú èyí rí? Wúńdíá Ísírẹ́lì ti ṣe ohun tó burú jù lọ.+ 14  Ṣé yìnyín lè yọ́ kúrò lára àwọn àpáta tó wà ní gẹ̀rẹ́gẹ̀rẹ́ Lẹ́bánónì? Tàbí ṣé omi tútù tó ń ṣàn bọ̀ láti ibi tó jìnnà lè gbẹ? 15  Àmọ́ àwọn èèyàn mi ti gbàgbé mi.+ Torí pé wọ́n ń rú ẹbọ* sí àwọn ohun tí kò ní láárí,+Wọ́n ń mú kí àwọn èèyàn fẹsẹ̀ kọ ní ọ̀nà wọn, àwọn ojú ọ̀nà àtijọ́,+Láti rìn ní ọ̀nà gbágungbàgun, ọ̀nà tí kò dán, tí kò sì tẹ́jú,* 16  Láti sọ ilẹ̀ wọn di ohun àríbẹ̀rù+Tí á sì di ohun àrísúfèé títí láé.+ Gbogbo ẹni tó bá ń gba ibẹ̀ kọjá á wò ó, ẹ̀rù á bà á, á sì mi orí rẹ̀.+ 17  Màá tú wọn ká níwájú ọ̀tá bí ẹ̀fúùfù láti ìlà oòrùn. Ẹ̀yìn ni màá kọ sí wọn, mi ò ní kọ ojú sí wọn, ní ọjọ́ àjálù wọn.”+ 18  Wọ́n sì sọ pé: “Ẹ wá, ẹ jẹ́ kí a gbìmọ̀ ibi sí Jeremáyà,+ nítorí òfin* kò ní kúrò lọ́dọ̀ àwọn àlùfáà, ìmọ̀ràn kò sì ní kúrò lọ́dọ̀ àwọn amòye, bẹ́ẹ̀ ni ọ̀rọ̀ Ọlọ́run kò ní kúrò lọ́dọ̀ àwọn wòlíì. Ẹ wá, ẹ jẹ́ kí a sọ̀rọ̀ burúkú sí i,* kí a má sì fiyè sí ohun tó ń sọ.” 19  Fiyè sí mi, Jèhófà,Sì fetí sí ohun tí àwọn alátakò mi ń sọ. 20  Ṣé ó yẹ kéèyàn fi ibi san ire? Nítorí wọ́n ti gbẹ́ kòtò fún ẹ̀mí* mi.+ Rántí bí mo ṣe dúró níwájú rẹ láti sọ ohun tó dáa nípa wọn,Kí o lè yí ìbínú rẹ kúrò lórí wọn. 21  Torí náà, fi àwọn ọmọ wọn fún ìyàn,Sì fi àwọn fúnra wọn fún idà.+ Kí àwọn ìyàwó wọn ṣòfò ọmọ, kí wọ́n sì di opó.+ Kí àjàkálẹ̀ àrùn pa àwọn ọkùnrin wọn,Kí idà sì pa àwọn ọ̀dọ́kùnrin wọn lójú ogun.+ 22  Jẹ́ kí a gbọ́ igbe ẹkún láti inú ilé wọnNígbà tí o bá mú àwọn jàǹdùkú* wá bá wọn lójijì. Nítorí wọ́n ti gbẹ́ kòtò láti fi mú miWọ́n sì ti dẹ pańpẹ́ fún ẹsẹ̀ mi.+ 23  Ṣùgbọ́n, ìwọ Jèhófà,O mọ gbogbo ètekéte wọn dáadáa, bí wọ́n ṣe fẹ́ pa mí.+ Má bo àṣìṣe wọn,Má sì pa ẹ̀ṣẹ̀ wọn rẹ́ kúrò níwájú rẹ. Jẹ́ kí wọ́n fẹsẹ̀ kọ níwájú rẹ+Nígbà tí o bá dojú ìjà kọ wọ́n nínú ìbínú rẹ.+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé

Ní Héb., “bó ṣe tọ́ ní ojú amọ̀kòkò náà láti ṣe.”
Tàbí “yí ìpinnu mi pa dà.”
Tàbí “yí ìpinnu mi pa dà.”
Tàbí “mú ẹbọ rú èéfín.”
Tàbí “tí wọn kò ṣe.”
Tàbí “ìtọ́ni.”
Ní Héb., “fi ahọ́n lù ú.”
Tàbí “ọkàn.”
Tàbí “akónilẹ́rù.”