Jeremáyà 33:1-26
33 Jèhófà bá Jeremáyà sọ̀rọ̀ lẹ́ẹ̀kejì, nígbà tó ṣì wà ní àhámọ́ ní Àgbàlá Ẹ̀ṣọ́,+ pé:
2 “Ohun tí Jèhófà, Aṣẹ̀dá ayé sọ nìyí, Jèhófà tó dá ayé tó sì fìdí rẹ̀ múlẹ̀ gbọn-in gbọn-in; Jèhófà ni orúkọ rẹ̀,
3 ‘Ké pè mí, màá sì dá ọ lóhùn, mo ṣe tán láti sọ nípa àwọn ohun ńlá tí kò ṣeé lóye fún ọ, àwọn ohun tí ìwọ kò tíì mọ̀.’”+
4 “Ohun tí Jèhófà Ọlọ́run Ísírẹ́lì sọ nìyí nípa àwọn ilé tó wà ní ìlú yìí àti ilé àwọn ọba Júdà tí wọ́n wó lulẹ̀ nípasẹ̀ àwọn òkìtì tí wọ́n mọ láti dó ti ìlú yìí àti nípasẹ̀ idà,+
5 nípa àwọn tó ń bọ̀ wá bá àwọn ará Kálídíà jà, tí wọ́n á fi òkú àwọn èèyàn tí mo ti pa nínú ìbínú àti ìrunú mi kún gbogbo ibí yìí, àwọn tí ìwà ibi wọn ti mú kí n fi ojú mi pa mọ́ kúrò lára ìlú yìí:
6 ‘Wò ó, màá mú kí ara rẹ̀ kọ́fẹ, màá sì fún un ní ìlera,+ màá mú wọn lára dá, màá sì fún wọn ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ àlàáfíà àti òtítọ́.+
7 Màá mú àwọn ará Júdà àti àwọn ọmọ Ísírẹ́lì tó wà lóko ẹrú pa dà,+ màá sì fún wọn lókun bí mo ti ṣe ní ìbẹ̀rẹ̀.+
8 Ṣe ni màá wẹ̀ wọ́n mọ́ kúrò nínú ẹ̀bi gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ tí wọ́n dá sí mi,+ màá sì dárí gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ wọn jì wọ́n àti àwọn àṣìṣe wọn.+
9 Orúkọ ìlú yìí máa gbé mi ga, á sì mú kí wọ́n máa yìn mí, kí wọ́n sì máa fi ògo fún mi láàárín gbogbo orílẹ̀-èdè ayé tó máa gbọ́ nípa gbogbo oore tí mo ṣe fún ìlú náà.+ Ẹ̀rù á bà wọ́n, wọ́n á sì máa gbọ̀n+ nítorí gbogbo oore àti àlàáfíà tí màá mú bá ìlú náà.’”+
10 “Ohun tí Jèhófà sọ nìyí, ‘Ní ibí yìí tí ẹ̀ ń sọ pé ó jẹ́ aṣálẹ̀, tí kò sí èèyàn tàbí ẹran ọ̀sìn níbẹ̀, ní àwọn ìlú Júdà àti àwọn ojú ọ̀nà Jerúsálẹ́mù tó ti di ahoro, tí kò sí èèyàn tàbí ẹni tó ń gbé ibẹ̀ àti ẹran ọ̀sìn, ibẹ̀ ni a ó tún ti pa dà gbọ́
11 ìró ayọ̀ àti ìró ìdùnnú,+ ohùn ọkọ ìyàwó àti ohùn ìyàwó, ohùn àwọn tó ń sọ pé: “Ẹ fi ọpẹ́ fún Jèhófà Ọlọ́run àwọn ọmọ ogun, nítorí Jèhófà jẹ́ ẹni rere;+ ìfẹ́ rẹ̀ tí kì í yẹ̀ sì wà títí láé!”’+
“‘Wọ́n á mú ẹbọ ìdúpẹ́ wá sínú ilé Jèhófà,+ nítorí màá mú àwọn tí wọ́n kó lọ sí oko ẹrú láti ilẹ̀ náà pa dà wá bíi ti ìbẹ̀rẹ̀,’ ni Jèhófà wí.”
12 “Ohun tí Jèhófà Ọlọ́run àwọn ọmọ ogun sọ nìyí: ‘Ní aṣálẹ̀ yìí, tí kò sí èèyàn tàbí ẹran ọ̀sìn nínú rẹ̀ àti ní gbogbo àwọn ìlú rẹ̀, ibi ìjẹko yóò tún pa dà wà fún àwọn olùṣọ́ àgùntàn tí agbo ẹran wọn máa dùbúlẹ̀ sí.’+
13 “‘Ní àwọn ìlú tó wà ní agbègbè olókè àti ní àwọn ìlú tó wà ní pẹ̀tẹ́lẹ̀, ní àwọn ìlú tó wà ní gúúsù àti ní ilẹ̀ Bẹ́ńjámínì, ní agbègbè Jerúsálẹ́mù+ àti ní àwọn ìlú Júdà,+ agbo ẹran yóò tún pa dà kọjá lábẹ́ ọwọ́ ẹni tó ń kà wọ́n,’ ni Jèhófà wí.”
14 “‘Wò ó! Ọjọ́ ń bọ̀,’ ni Jèhófà wí, ‘tí màá mú ìlérí tí mo ṣe nípa ilé Ísírẹ́lì àti ilé Júdà ṣẹ.+
15 Nígbà yẹn àti ní àkókò yẹn, màá mú kí èéhù* òdodo kan hù jáde fún Dáfídì,+ á sì ṣe ìdájọ́ tí ó tọ́ àti òdodo ní ilẹ̀ náà.+
16 Ní àkókò yẹn, a ó gba Júdà là,+ Jerúsálẹ́mù á sì máa wà ní ààbò.+ Ohun tí a ó sì máa pè é ni: Jèhófà Ni Òdodo Wa.’”+
17 “Nítorí ohun tí Jèhófà sọ nìyí: ‘Kò ní ṣàìsí ọkùnrin kan láti ìlà Dáfídì tí yóò máa jókòó sórí ìtẹ́ ilé Ísírẹ́lì,+
18 bẹ́ẹ̀ ni àwọn àlùfáà tó jẹ́ ọmọ Léfì kò ní ṣàìní ọkùnrin kan tí yóò máa dúró níwájú mi láti rú odindi ẹbọ sísun, láti máa sun ọrẹ ọkà àti láti máa rú àwọn ẹbọ.’”
19 Jèhófà sì tún bá Jeremáyà sọ̀rọ̀, pé:
20 “Ohun tí Jèhófà sọ nìyí, ‘Bí ẹ bá lè ba májẹ̀mú mi nípa ọ̀sán àti májẹ̀mú mi nípa òru jẹ́, pé kí ọ̀sán àti òru má ṣe wà ní àkókò wọn+
21 nìkan ni májẹ̀mú tí mo bá Dáfídì ìránṣẹ́ mi dá tó lè bà jẹ́,+ tí kò fi ní máa ní ọmọ tó ń jọba lórí ìtẹ́ rẹ̀,+ bẹ́ẹ̀ náà ni májẹ̀mú tí mo bá àwọn àlùfáà tó jẹ́ ọmọ Léfì dá, àwọn òjíṣẹ́ mi.+
22 Bí a kò ti lè ka àwọn ọmọ ogun ọ̀run, tí a kò sì lè wọn iyanrìn òkun, bẹ́ẹ̀ ni màá sọ àtọmọdọ́mọ* Dáfídì ìránṣẹ́ mi àti àwọn ọmọ Léfì tí wọ́n ń ṣe ìránṣẹ́ fún mi di púpọ̀.’”
23 Jèhófà sì tún bá Jeremáyà sọ̀rọ̀, ó ní:
24 “Ǹjẹ́ o ò kíyè sí ohun tí àwọn èèyàn yìí ń sọ, pé, ‘Jèhófà máa kọ ìdílé méjì tó ti yàn’? Wọn kò bọ̀wọ̀ fún àwọn èèyàn mi, wọn ò sì kà wọ́n sí orílẹ̀-èdè mọ́.
25 “Ohun tí Jèhófà sọ nìyí: ‘Bí mo ṣe fìdí májẹ̀mú mi nípa ọ̀sán àti òru múlẹ̀+ àti òfin* nípa ọ̀run àti ayé,+
26 bẹ́ẹ̀ ni mi ò jẹ́ kọ àtọmọdọ́mọ* Jékọ́bù àti ti Dáfídì ìránṣẹ́ mi, kí n bàa lè máa mú lára ọmọ* rẹ̀ láti jẹ́ alákòóso lórí àtọmọdọ́mọ* Ábúráhámù, Ísákì àti Jékọ́bù. Nítorí màá kó àwọn tó wà ní oko ẹrú lára wọn jọ,+ màá sì ṣàánú wọn.’”+
Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé
^ Tàbí “ajogún.”
^ Ní Héb., “èso.”
^ Tàbí “àṣẹ.”
^ Ní Héb., “èso.”
^ Ní Héb., “èso.”
^ Ní Héb., “èso.”