Jeremáyà 38:1-28
38 Ìgbà náà ni Ṣẹfatáyà ọmọ Mátánì, Gẹdaláyà ọmọ Páṣúrì, Júkálì+ ọmọ Ṣelemáyà àti Páṣúrì + ọmọ Málíkíjà gbọ́ ọ̀rọ̀ tí Jeremáyà ń sọ fún gbogbo àwọn èèyàn náà pé:
2 “Ohun tí Jèhófà sọ nìyí, ‘Ẹni tó bá dúró sí ìlú yìí ni idà, ìyàn àti àjàkálẹ̀ àrùn* yóò pa.+ Àmọ́, ẹni tó bá fi ara rẹ̀ lé* ọwọ́ àwọn ará Kálídíà á máa wà láàyè, á jèrè ẹ̀mí rẹ̀, á sì wà láàyè.’*+
3 Ohun tí Jèhófà sọ nìyí, ‘Ó dájú pé ìlú yìí ni a ó fà lé ọwọ́ àwọn ọmọ ogun ọba Bábílónì, yóò sì gbà á.’”+
4 Àwọn ìjòyè sọ fún ọba pé: “Jọ̀wọ́, ní kí wọ́n pa ọkùnrin yìí,+ torí bó ṣe máa ń kó ìrẹ̀wẹ̀sì bá ọkàn* àwọn ọmọ ogun tó ṣẹ́ kù nínú ìlú yìí àti gbogbo àwọn èèyàn náà nìyẹn, tó ń sọ irú ọ̀rọ̀ bẹ́ẹ̀ fún wọn. Nítorí kì í ṣe àlàáfíà àwọn èèyàn yìí ni ọkùnrin yìí ń wá, bí kò ṣe àjálù wọn.”
5 Ọba Sedekáyà dáhùn pé: “Ẹ wò ó! Ọwọ́ yín ni ọkùnrin náà wà, torí kò sí nǹkan kan tí ọba lè ṣe láti dá yín dúró.”
6 Torí náà, wọ́n mú Jeremáyà, wọ́n sì jù ú sínú kòtò omi Málíkíjà ọmọ ọba, èyí tó wà ní Àgbàlá Ẹ̀ṣọ́.+ Wọ́n fi okùn sọ Jeremáyà kalẹ̀. Nígbà yẹn, kò sí omi nínú kòtò omi náà, àfi ẹrẹ̀ nìkan, Jeremáyà sì bẹ̀rẹ̀ sí í rì sínú ẹrẹ̀ náà.
7 Ebedi-mélékì+ ará Etiópíà, tó jẹ́ ìwẹ̀fà* ní ilé* ọba gbọ́ pé wọ́n ti ju Jeremáyà sínú kòtò omi. Lásìkò yìí, ọba wà níbi tó jókòó sí ní Ẹnubodè Bẹ́ńjámínì,+
8 torí náà, Ebedi-mélékì jáde kúrò ní ilé* ọba, ó sì sọ fún ọba pé:
9 “Olúwa mi ọba, ìwà ìkà gbáà ni àwọn ọkùnrin yìí hù sí wòlíì Jeremáyà! Wọ́n ti jù ú sínú kòtò omi, ibẹ̀ ló sì máa kú sí nítorí ìyàn, torí kò sí búrẹ́dì mọ́ ní ìlú yìí.”+
10 Ìgbà náà ni ọba pàṣẹ fún Ebedi-mélékì ará Etiópíà pé: “Mú ọgbọ̀n (30) ọkùnrin pẹ̀lú rẹ láti ibí yìí, kí o sì gbé wòlíì Jeremáyà gòkè láti inú kòtò omi kí ó tó kú.”
11 Torí náà, Ebedi-mélékì kó àwọn ọkùnrin náà, ó sì lọ sí ilé* ọba, sí apá kan lábẹ́ ibi ìṣúra,+ wọ́n sì kó àwọn àkísà àti àwọn àjákù aṣọ níbẹ̀, wọ́n sì fi okùn sọ̀ wọ́n sísàlẹ̀ sí Jeremáyà nínú kòtò omi náà.
12 Ni Ebedi-mélékì ará Etiópíà bá sọ fún Jeremáyà pé: “Jọ̀wọ́, fi àwọn àkísà náà àti àwọn àjákù aṣọ náà tẹ́ abíyá rẹ lórí okùn náà.” Jeremáyà sì ṣe bẹ́ẹ̀,
13 wọ́n fi okùn náà fa Jeremáyà jáde, wọ́n sì gbé e gòkè kúrò nínú kòtò omi náà. Jeremáyà sì wà ní Àgbàlá Ẹ̀ṣọ́.+
14 Ọba Sedekáyà ránṣẹ́ sí wòlíì Jeremáyà pé kó wá sọ́dọ̀ òun ní àbáwọlé kẹta, tó wà ní ilé Jèhófà, ọba sì sọ fún Jeremáyà pé: “Ohun kan wà tí mo fẹ́ bi ọ́. Má fi ohunkóhun pa mọ́ fún mi.”
15 Jeremáyà wá sọ fún Sedekáyà pé: “Tí mo bá sọ fún ọ, ó dájú pé wàá pa mí. Tí mo bá sì fún ọ nímọ̀ràn, o ò ní fetí sí mi.”
16 Torí náà, Ọba Sedekáyà búra ní bòókẹ́lẹ́ fún Jeremáyà pé: “Bí Jèhófà ti wà láàyè, ẹni tó fún wa ní ẹ̀mí wa,* mi ò ní pa ọ́, mi ò sì ní fà ọ́ lé ọwọ́ àwọn èèyàn tó fẹ́ gba ẹ̀mí rẹ.”*
17 Jeremáyà wá sọ fún Sedekáyà pé: “Ohun tí Jèhófà, Ọlọ́run àwọn ọmọ ogun, Ọlọ́run Ísírẹ́lì sọ nìyí, ‘Bí o bá fi ara rẹ lé* àwọn ìjòyè ọba Bábílónì lọ́wọ́, wọ́n á dá ẹ̀mí rẹ sí,* wọn kò ní dáná sun ìlú yìí, wọn kò sì ní pa ìwọ àti agbo ilé rẹ.+
18 Àmọ́, bí o kò bá fi ara rẹ lé* àwọn ìjòyè ọba Bábílónì lọ́wọ́, a ó fa ìlú yìí lé àwọn ará Kálídíà lọ́wọ́, wọ́n á dáná sun ún,+ o ò sì ní lè sá mọ́ wọn lọ́wọ́.’”+
19 Ìgbà náà ni Ọba Sedekáyà sọ fún Jeremáyà pé: “Ẹ̀rù àwọn Júù tí wọ́n ti sá lọ sọ́dọ̀ àwọn ará Kálídíà ń bà mí, nítorí tí wọ́n bá fà mí lé wọn lọ́wọ́, wọ́n lè ṣe mí ṣúkaṣùka.”
20 Ṣùgbọ́n Jeremáyà sọ pé: “Wọn kò ní fà ọ́ lé wọn lọ́wọ́. Jọ̀wọ́, ṣègbọràn sí ohùn Jèhófà lórí ohun tí mò ń sọ fún ọ, nǹkan á lọ dáadáa fún ọ, wàá* sì máa wà láàyè.
21 Àmọ́, bí o bá kọ̀ láti fi ara rẹ lé* wọn lọ́wọ́, ohun tí Jèhófà fi hàn mí nìyí:
22 Wò ó! Gbogbo obìnrin tó ṣẹ́ kù sí ilé* ọba Júdà ni a mú jáde wá sọ́dọ̀ àwọn ìjòyè ọba Bábílónì,+ wọ́n sì ń sọ pé,‘Àwọn ọkùnrin tí o fọkàn tán* ti tàn ọ́ jẹ, wọ́n sì ti borí rẹ.+
Wọ́n ti mú kí ẹsẹ̀ rẹ rì sínú ẹrọ̀fọ̀.
Ní báyìí, wọ́n ti sá pa dà lẹ́yìn rẹ.’
23 Gbogbo ìyàwó rẹ àti àwọn ọmọ rẹ ni wọ́n á kó wá fún àwọn ará Kálídíà, o ò sì ní lè sá mọ́ wọn lọ́wọ́, àmọ́ ọba Bábílónì+ máa mú ọ, nítorí rẹ sì ni wọ́n á fi dáná sun ìlú yìí.”+
24 Sedekáyà sì sọ fún Jeremáyà pé: “Má ṣe jẹ́ kí ẹnikẹ́ni mọ̀ nípa àwọn nǹkan yìí, kí o má bàa kú.
25 Tí àwọn ìjòyè bá sì gbọ́ pé mo bá ọ sọ̀rọ̀, tí wọ́n wá bá ọ, tí wọ́n sì sọ fún ọ pé, ‘Jọ̀wọ́, sọ fún wa, ohun tí o bá ọba sọ. Má fi ohunkóhun pa mọ́ fún wa, a ò ní pa ọ́.+ Kí ni ọba sọ fún ọ?’
26 kí o fún wọn lésì pé, ‘Ṣe ni mò ń bẹ ọba pé kó má ṣe dá mi pa dà sí ilé Jèhónátánì láti kú sí ibẹ̀.’”+
27 Nígbà tó yá, gbogbo àwọn ìjòyè wọlé wá bá Jeremáyà, wọ́n sì bi í ní ìbéèrè. Ó sọ gbogbo ohun tí ọba pa láṣẹ fún un pé kó sọ fún wọn. Torí náà, wọn kò bá a sọ̀rọ̀ mọ́, nítorí ẹnikẹ́ni kò mọ ohun tí òun àti ọba jọ sọ.
28 Jeremáyà kò kúrò ní Àgbàlá Ẹ̀ṣọ́+ títí di ọjọ́ tí wọ́n gba Jerúsálẹ́mù; ibẹ̀ ló ṣì wà nígbà tí wọ́n gba Jerúsálẹ́mù.+
Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé
^ Tàbí “àìsàn.”
^ Ní Héb., “jáde sí.”
^ Tàbí “á sì sá àsálà fún ọkàn rẹ̀.”
^ Ní Héb., “ọwọ́.”
^ Tàbí “òṣìṣẹ́ láàfin.”
^ Tàbí “ààfin.”
^ Tàbí “ààfin.”
^ Tàbí “ààfin.”
^ Tàbí “tó ń lépa ọkàn rẹ.”
^ Tàbí “ẹni tó dá ọkàn yìí fún wa.”
^ Ní Héb., “jáde sí.”
^ Tàbí “ọkàn rẹ yóò máa wà láàyè.”
^ Ní Héb., “jáde sí.”
^ Tàbí “ọkàn rẹ.”
^ Ní Héb., “jáde sí.”
^ Ní Héb., “Àwọn ọkùnrin tó wà ní àlàáfíà pẹ̀lú rẹ.”
^ Tàbí “ààfin.”