Jeremáyà 44:1-30
44 Ọ̀rọ̀ tí Jeremáyà gbọ́ nípa gbogbo Júù tó ń gbé ní ilẹ̀ Íjíbítì,+ ìyẹn àwọn tó ń gbé ní Mígídólì,+ ní Tápánẹ́sì,+ ní Nófì*+ àti ní ilẹ̀ Pátírọ́sì,+ pé:
2 “Ohun tí Jèhófà Ọlọ́run àwọn ọmọ ogun, Ọlọ́run Ísírẹ́lì sọ nìyí, ‘Ẹ ti rí gbogbo àjálù tí mo mú bá Jerúsálẹ́mù+ àti gbogbo àwọn ìlú Júdà, wọ́n ti di àwókù lónìí yìí, kò sì sí ẹni tó ń gbé inú wọn.+
3 Ìdí ni pé wọ́n hùwà ibi láti mú mi bínú, torí wọ́n lọ ń rú ẹbọ,+ wọ́n sì ń sin àwọn ọlọ́run míì tí wọn kò mọ̀, tí ẹ̀yin tàbí àwọn baba ńlá yín náà kò sì mọ̀.+
4 Mò ń rán gbogbo àwọn ìránṣẹ́ mi wòlíì sí yín, mo sì ń rán wọn léraléra,* pé: “Ẹ jọ̀wọ́, ẹ má ṣe ohun ìríra tí mi ò fẹ́ yìí.”+
5 Ṣùgbọ́n wọn kò tẹ́tí sí mi, wọn kò sì fetí sílẹ̀ láti yí pa dà kúrò nínú ìwà ibi wọn, kí wọ́n má ṣe rú ẹbọ sí àwọn ọlọ́run míì.+
6 Nítorí náà, ìrunú mi àti ìbínú mi tú jáde, ó sì jó bí iná ní àwọn ìlú Júdà àti ní àwọn ojú ọ̀nà Jerúsálẹ́mù, wọ́n sì di àwókù àti ahoro bí wọ́n ṣe rí lónìí yìí.’+
7 “Ní báyìí, ohun tí Jèhófà, Ọlọ́run àwọn ọmọ ogun, Ọlọ́run Ísírẹ́lì sọ nìyí, ‘Kí nìdí tí ẹ fi ń fa àjálù ńlá bá ara* yín, tí ọkùnrin àti obìnrin, ọmọdé àti ọmọ jòjòló á fi ṣègbé ní Júdà, tí kò fi ní sí ẹni tó máa ṣẹ́ kù?
8 Kí nìdí tí ẹ fi ń fi iṣẹ́ ọwọ́ yín mú mi bínú, tí ẹ̀ ń rú ẹbọ sí àwọn ọlọ́run míì ní ilẹ̀ Íjíbítì tí ẹ lọ ń gbé? Ẹ ó ṣègbé, ẹ ó sì di ẹni ègún àti ẹni ẹ̀gàn láàárín gbogbo orílẹ̀-èdè ayé.+
9 Ṣé ẹ ti gbàgbé ìwà burúkú àwọn baba ńlá yín, ìwà burúkú àwọn ọba Júdà+ àti ìwà burúkú àwọn aya wọn,+ ìwà burúkú tiyín àti ìwà burúkú àwọn aya yín,+ tí gbogbo yín hù ní ilẹ̀ Júdà àti ní àwọn ojú ọ̀nà Jerúsálẹ́mù?
10 Títí di òní yìí, wọn kò rẹ ara wọn sílẹ̀,* ẹ̀rù kò bà wọ́n,+ bẹ́ẹ̀ ni wọn kò rìn nínú òfin mi àti nínú àwọn ìlànà mi tí mo fi lélẹ̀ fún ẹ̀yin àti àwọn baba ńlá yín.’+
11 “Nítorí náà, ohun tí Jèhófà Ọlọ́run àwọn ọmọ ogun, Ọlọ́run Ísírẹ́lì sọ nìyí, ‘Wò ó, mo ti pinnu láti mú àjálù bá yín kí n lè pa gbogbo Júdà run.
12 Màá sì kó àṣẹ́kù Júdà tí wọ́n ti pinnu láti lọ sí ilẹ̀ Íjíbítì kí wọ́n lè máa gbé ibẹ̀, gbogbo wọn sì máa ṣègbé ní ilẹ̀ Íjíbítì.+ Idà yóò pa wọ́n, ìyàn yóò sì mú kí wọ́n ṣègbé; látorí ẹni tó kéré jù dórí ẹni tó dàgbà jù, idà àti ìyàn ni yóò pa wọ́n. Wọ́n á sì di ẹni ègún, ohun àríbẹ̀rù, ẹni ìfiré àti ẹni ẹ̀gàn.+
13 Ṣe ni màá fìyà jẹ àwọn tó ń gbé ní ilẹ̀ Íjíbítì, bí mo ṣe fìyà jẹ Jerúsálẹ́mù nípasẹ̀ idà, ìyàn àti àjàkálẹ̀ àrùn.*+
14 Àṣẹ́kù Júdà tí wọ́n lọ ń gbé ní ilẹ̀ Íjíbítì kò ní lè sá àsálà tàbí kí wọ́n yè bọ́ láti pa dà sí ilẹ̀ Júdà. Á wù wọ́n* pé kí wọ́n pa dà, kí wọ́n sì máa gbé ibẹ̀, àmọ́ wọn ò ní lè pa dà, àyàfi àwọn díẹ̀ tó máa sá àsálà.’”
15 Gbogbo ọkùnrin tí wọ́n mọ̀ pé àwọn ìyàwó wọn ti ń rú ẹbọ sí àwọn ọlọ́run míì àti gbogbo àwọn ìyàwó tí wọ́n wà níbẹ̀, tí wọ́n jẹ́ àwùjọ ńlá àti gbogbo èèyàn tó ń gbé nílẹ̀ Íjíbítì,+ ní Pátírọ́sì,+ dá Jeremáyà lóhùn pé:
16 “A ò ní fetí sí ọ̀rọ̀ tí o sọ fún wa ní orúkọ Jèhófà.
17 Kàkà bẹ́ẹ̀, a ó rí i dájú pé a ṣe gbogbo ohun tó ti ẹnu wa jáde, láti rú ẹbọ sí Ọbabìnrin Ọ̀run* àti láti da ọrẹ ohun mímu jáde sí i,+ bí àwa àti àwọn baba ńlá wa, àwọn ọba wa àti àwọn ìjòyè wa ti ṣe ní àwọn ìlú Júdà àti ní àwọn ojú ọ̀nà Jerúsálẹ́mù, nígbà tí a máa ń jẹ oúnjẹ ní àjẹtẹ́rùn, tí nǹkan sì ń dáa fún wa, tí a kò sì rí àjálù kankan.
18 Láti ìgbà tí a ò ti rúbọ sí Ọbabìnrin Ọ̀run* mọ́, tí a ò sì da ọrẹ ohun mímu jáde sí i ni a ti ṣaláìní ohun gbogbo, tí idà àti ìyàn sì ti mú kí á ṣègbé.”
19 Àwọn obìnrin náà sọ pé: “Nígbà tí à ń rú ẹbọ sí Ọbabìnrin Ọ̀run,* tí a sì ń da ọrẹ ohun mímu jáde sí i, ṣebí àwọn ọkọ wa lọ́wọ́ sí i pé kí a máa ṣe àkàrà ìrúbọ ní ìrísí rẹ̀, kí a sì máa da ọrẹ ohun mímu jáde sí i?”
20 Nígbà náà, Jeremáyà sọ fún gbogbo àwọn èèyàn náà, ìyẹn àwọn ọkùnrin àti àwọn ìyàwó wọn àti gbogbo àwọn tó ń bá a sọ̀rọ̀, ó ní:
21 “Ẹbọ tí ẹ rú, tí àwọn baba ńlá yín, àwọn ọba yín, àwọn ìjòyè yín àti àwọn èèyàn ilẹ̀ náà rú ní àwọn ìlú Júdà àti ní àwọn ojú ọ̀nà Jerúsálẹ́mù,+ ni Jèhófà ti rántí, wọ́n sì wá sí i lọ́kàn!
22 Níkẹyìn, Jèhófà kò lè fara da ìwà ibi yín mọ́ àti àwọn ohun ìríra tí ẹ ti ṣe, torí náà ilẹ̀ yín pa run, ó di ohun àríbẹ̀rù àti ègún, kò sì sí ẹnikẹ́ni tó ń gbé ibẹ̀, bó ṣe rí lónìí yìí.+
23 Nítorí ẹ ti rú àwọn ẹbọ yìí àti pé ẹ ti ṣẹ̀ sí Jèhófà, tí ẹ kò ṣègbọràn sí ohùn Jèhófà, tí ẹ kò sì pa òfin àti ìlànà rẹ̀ mọ́ pẹ̀lú àwọn ìránnilétí rẹ̀, ìdí nìyẹn tí àjálù yìí fi bá yín bó ṣe rí lónìí yìí.”+
24 Jeremáyà sì ń bá ọ̀rọ̀ rẹ̀ lọ, ó sọ fún gbogbo àwọn èèyàn náà àti gbogbo àwọn obìnrin náà pé: “Ẹ gbọ́ ọ̀rọ̀ Jèhófà, gbogbo ẹ̀yin ará Júdà tó wà ní ilẹ̀ Íjíbítì.
25 Ohun tí Jèhófà Ọlọ́run àwọn ọmọ ogun, Ọlọ́run Ísírẹ́lì sọ nìyí, ‘Ohun tí ẹ̀yin àti àwọn ìyàwó yín ti fi ẹnu yín sọ, ni ẹ fi ọwọ́ yín mú ṣẹ, torí ẹ sọ pé: “Àá rí i dájú pé a mú ẹ̀jẹ́ wa ṣẹ pé a ó rú ẹbọ sí Ọbabìnrin Ọ̀run,* a ó sì da ọrẹ ohun mímu jáde sí i.”+ Ó dájú pé ẹ̀yin obìnrin yìí máa mú ẹ̀jẹ́ yín ṣẹ, ẹ ó sì pa ẹ̀jẹ́ yín mọ́.’
26 “Nítorí náà, ẹ gbọ́ ọ̀rọ̀ Jèhófà, gbogbo ẹ̀yin ará Júdà tó ń gbé ní ilẹ̀ Íjíbítì: ‘“Wò ó, mo fi orúkọ ńlá mi búra,” ni Jèhófà wí, “pé èyíkéyìí lára èèyàn Júdà+ tó wà ní gbogbo ilẹ̀ Íjíbítì kò ní pe orúkọ mi mọ́ nígbà ìbúra pé, ‘Bí Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ ti wà láàyè!’+
27 Wò ó, ojú mi wà lára wọn fún àjálù, kì í ṣe fún ohun rere;+ gbogbo àwọn ọkùnrin Júdà tó wà ní ilẹ̀ Íjíbítì ni idà àti ìyàn yóò pa, títí wọn kò fi ní sí mọ́.+
28 Àwọn díẹ̀ ló máa bọ́ lọ́wọ́ idà, tí wọ́n á sì pa dà láti ilẹ̀ Íjíbítì sí ilẹ̀ Júdà.+ Lẹ́yìn náà, gbogbo àwọn tó ṣẹ́ kù nílẹ̀ Júdà, tí wọ́n wá sí ilẹ̀ Íjíbítì láti máa gbé ibẹ̀, máa mọ ẹni tí ọ̀rọ̀ rẹ̀ ṣẹ, bóyá tèmi ni tàbí tiwọn!”’”
29 “‘Àmì tó wà fún yín nìyí,’ ni Jèhófà wí, ‘pé màá fìyà jẹ yín ní ibí yìí, kí ẹ lè mọ̀ pé àjálù tí mo ṣèlérí fún yín yóò ṣẹ dájúdájú.
30 Ohun tí Jèhófà sọ nìyí: “Wò ó, màá fi Fáráò Hófírà, ọba Íjíbítì, lé ọwọ́ àwọn ọ̀tá rẹ̀ àti lé ọwọ́ àwọn tó fẹ́ gba ẹ̀mí rẹ̀,* bí mo ṣe fi Sedekáyà ọba Júdà lé ọwọ́ Nebukadinésárì* ọba Bábílónì, ẹni tó jẹ́ ọ̀tá rẹ̀, tó sì fẹ́ gba ẹ̀mí rẹ̀.”’”*+
Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé
^ Tàbí “Mémúfísì.”
^ Ní Héb., “mò ń jí ní kùtùkùtù, mo sì ń rán wọn.”
^ Tàbí “ọkàn.”
^ Tàbí “banú jẹ́.”
^ Tàbí “àìsàn.”
^ Tàbí “Ọkàn wọn á fà sí i.”
^ Orúkọ oyè abo ọlọ́run tí àwọn èèyàn Ísírẹ́lì apẹ̀yìndà ń jọ́sìn; ó ṣeé ṣe kó jẹ́ abo ọlọ́run ìbímọlémọ.
^ Orúkọ oyè abo ọlọ́run tí àwọn èèyàn Ísírẹ́lì apẹ̀yìndà ń jọ́sìn; ó ṣeé ṣe kó jẹ́ abo ọlọ́run ìbímọlémọ.
^ Orúkọ oyè abo ọlọ́run tí àwọn èèyàn Ísírẹ́lì apẹ̀yìndà ń jọ́sìn; ó ṣeé ṣe kó jẹ́ abo ọlọ́run ìbímọlémọ.
^ Orúkọ oyè abo ọlọ́run tí àwọn èèyàn Ísírẹ́lì apẹ̀yìndà ń jọ́sìn; ó ṣeé ṣe kó jẹ́ abo ọlọ́run ìbímọlémọ.
^ Tàbí “àwọn tó ń lépa ọkàn rẹ̀.”
^ Ní Héb., “Nebukadirésárì,” ọ̀nà míì tí wọ́n ń gbà kọ orúkọ yìí.
^ Tàbí “tó sì ń lépa ọkàn rẹ̀.”