Jeremáyà 46:1-28
46 Ọ̀rọ̀ tí Jèhófà sọ fún wòlíì Jeremáyà nípa àwọn orílẹ̀-èdè nìyí:+
2 Sí Íjíbítì,+ nípa àwọn ọmọ ogun Fáráò Nékò + ọba Íjíbítì, tí ó wà lẹ́gbẹ̀ẹ́ odò Yúfírétì, ẹni tí Nebukadinésárì* ọba Bábílónì ṣẹ́gun ní Kákémíṣì, ní ọdún kẹrin Jèhóákímù+ ọmọ Jòsáyà, ọba Júdà:
3 “Ẹ to asà* àti apata ńlá,Ẹ sì jáde lọ sójú ogun.
4 Ẹ fi ìjánu sí ẹṣin, kí ẹ sì gùn ún, ẹ̀yin agẹṣin.
Ẹ lọ dúró sí àyè yín, kí ẹ sì dé akoto.*
Ẹ dán aṣóró, kí ẹ sì wọ ẹ̀wù irin.
5 ‘Kí nìdí tí mo fi rí wọn tí jìnnìjìnnì bò wọ́n?
Wọ́n ń sá pa dà, àwọn jagunjagun wọn ni a ti lù bolẹ̀.
Wọ́n ti sá lọ tẹ̀rùtẹ̀rù, àwọn jagunjagun wọn kò sì bojú wẹ̀yìn.
Ìbẹ̀rù wà níbi gbogbo,’ ni Jèhófà wí.
6 ‘Àwọn tí ẹsẹ̀ wọn yá nílẹ̀ kò lè sá lọ, àwọn jagunjagun kò sì lè sá àsálà.
Ní àríwá, lẹ́gbẹ̀ẹ́ odò Yúfírétì,Wọ́n ti kọsẹ̀, wọ́n sì ti ṣubú.’+
7 Ta ló ń bọ̀ yìí bí odò Náílì,Bí odò tí omi rẹ̀ ń ru gùdù?
8 Íjíbítì ń gòkè bọ̀ bí odò Náílì,+Bí odò tí omi rẹ̀ ń ru gùdù,Ó sì sọ pé, ‘Màá gòkè lọ, màá sì bo ilẹ̀ ayé.
Màá pa ìlú náà àti àwọn tó ń gbé inú rẹ̀ run.’
9 Ẹ gòkè lọ, ẹ̀yin ẹṣin!
Ẹ sá eré àsápajúdé, ẹ̀yin kẹ̀kẹ́ ẹṣin!
Kí àwọn jagunjagun jáde lọ,Kúṣì àti Pútì, tí wọ́n mọ apata lò,+Pẹ̀lú àwọn Lúdímù,+ tí wọ́n mọ ọrun tẹ̀,* tí wọ́n sì mọ̀ ọ́n lò,+
10 “Ọjọ́ yẹn jẹ́ ti Olúwa Ọba Aláṣẹ, Jèhófà Ọlọ́run àwọn ọmọ ogun, ọjọ́ ẹ̀san tó máa gbẹ̀san lára àwọn ọ̀tá rẹ̀. Idà máa pa wọ́n ní àpatẹ́rùn, á sì mu ẹ̀jẹ̀ wọn ní àmuyó, nítorí Olúwa Ọba Aláṣẹ, Jèhófà Ọlọ́run àwọn ọmọ ogun, ní ẹbọ* kan ní ilẹ̀ àríwá lẹ́gbẹ̀ẹ́ odò Yúfírétì.+
11 Gòkè lọ sí Gílíádì láti mú básámù wá,+Ìwọ wúńdíá ọmọbìnrin Íjíbítì.
Asán ni o sọ oògùn rẹ di púpọ̀,Torí kò sí ìwòsàn fún ọ.+
12 Àwọn orílẹ̀-èdè ti gbọ́ nípa àbùkù rẹ,+Igbe ẹkún rẹ sì ti kún ilẹ̀ náà.
Nítorí jagunjagun ń kọsẹ̀ lára jagunjagun,Àwọn méjèèjì sì jọ ṣubú lulẹ̀.”
13 Ọ̀rọ̀ tí Jèhófà sọ fún wòlíì Jeremáyà nípa bí Nebukadinésárì* ọba Bábílónì ṣe máa wá pa ilẹ̀ Íjíbítì rẹ́ nìyí:+
14 “Sọ ọ́ ní Íjíbítì, sì kéde rẹ̀ ní Mígídólì.+
Kéde rẹ̀ ní Nófì* àti ní Tápánẹ́sì.+
Sọ pé, ‘Ẹ dúró sí àyè yín, kí ẹ sì múra sílẹ̀,Nítorí idà kan máa pani run ní gbogbo àyíká yín.
15 Kí nìdí tí a fi gbá àwọn alágbára ọkùnrin yín lọ?
Wọn kò lè dúró,Nítorí Jèhófà ti tì wọ́n ṣubú.
16 Iye àwọn tó ń kọsẹ̀, tí wọ́n sì ń ṣubú pọ̀ gan-an.
Ẹnì kìíní ń sọ fún ẹnì kejì rẹ̀ pé:
“Dìde! Jẹ́ kí a pa dà sọ́dọ̀ àwọn èèyàn wa àti sí ìlú ìbílẹ̀ waNítorí idà tó ń hanni léèmọ̀.”’
17 Ibẹ̀ ni wọ́n ti kéde pé,‘Fáráò ọba Íjíbítì jẹ́ ariwo lásánÒun ló jẹ́ kí àǹfààní* bọ́.’+
18 ‘Bí mo ti wà láàyè,’ ni Ọba wí, ẹni tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Jèhófà Ọlọ́run àwọn ọmọ ogun,‘Ó* máa wọlé wá bíi Tábórì+ láàárín àwọn òkèÀti bíi Kámẹ́lì+ lẹ́gbẹ̀ẹ́ òkun.
19 Di ẹrù tí o máa gbé lọ sí ìgbèkùn,Ìwọ ọmọbìnrin tó ń gbé ní Íjíbítì.
Nítorí Nófì* á di ohun àríbẹ̀rù;Wọ́n á sọ iná sí i,* ẹnikẹ́ni ò sì ní lè gbé ibẹ̀.+
20 Íjíbítì dà bí abo ọmọ màlúù tó lẹ́wà,Àmọ́ kòkòrò tó ń tani máa wá bá a láti àríwá.
21 Kódà àwọn ọmọ ogun tí ó háyà tó wà láàárín rẹ̀ dà bí ọmọ màlúù àbọ́sanra,Ṣùgbọ́n àwọn náà ti pẹ̀yìn dà, wọ́n sì jọ sá lọ.
Wọn kò lè dúró,+Nítorí ọjọ́ àjálù wọn ti dé bá wọn,Àkókò ìbẹ̀wò wọn.’
22 ‘Ìró rẹ̀ dà bíi ti ejò tó ń sá lọ,Nítorí wọ́n ń fi àáké lé e tagbáratagbára,Bí àwọn ọkùnrin tó ń gé igi.*
23 Wọ́n á gé igbó rẹ̀ lulẹ̀,’ ni Jèhófà wí, ‘bó tiẹ̀ dà bíi pé inú rẹ̀ kò ṣeé wọ̀.
Nítorí wọ́n pọ̀ ju eéṣú lọ, wọn ò sì níye.
24 Ojú máa ti ọmọbìnrin Íjíbítì.
A ó fà á lé ọwọ́ àwọn èèyàn àríwá.’+
25 “Jèhófà Ọlọ́run àwọn ọmọ ogun, Ọlọ́run Ísírẹ́lì, sọ pé: ‘Wò ó, màá yíjú sí Ámọ́nì+ láti Nóò*+ àti sí Fáráò àti Íjíbítì àti àwọn ọlọ́run rẹ̀+ àti àwọn ọba rẹ̀, àní màá yíjú sí Fáráò àti gbogbo àwọn tí wọ́n gbẹ́kẹ̀ lé e.’+
26 “‘Màá fà wọ́n lé ọwọ́ àwọn tó fẹ́ gba ẹ̀mí* wọn, lé ọwọ́ Nebukadinésárì* ọba Bábílónì+ àti àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀. Lẹ́yìn náà, wọ́n á máa gbé inú rẹ̀ bíi ti àtijọ́,’ ni Jèhófà wí.+
27 ‘Ní tìrẹ, má fòyà, ìwọ Jékọ́bù ìránṣẹ́ mi,Má sì jẹ́ kí ẹ̀rù bà ọ́, ìwọ Ísírẹ́lì.+
Nítorí màá gbà ọ́ láti ibi tó jìnnà réréÀti àwọn ọmọ* rẹ láti oko ẹrú tí wọ́n wà.+
Jékọ́bù á pa dà, ara rẹ̀ á balẹ̀, kò ní rí ìyọlẹ́nu,Ẹnì kankan ò sì ní dẹ́rù bà wọ́n.+
28 Torí náà, má fòyà, ìwọ Jékọ́bù ìránṣẹ́ mi,’ ni Jèhófà wí, ‘torí pé mo wà pẹ̀lú rẹ.
Màá pa gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè tí mo tú ọ ká sí àárín wọn run,+Àmọ́ ní tìrẹ, mi ò ní pa ọ́ run.+
Mi ò ní bá ọ wí* kọjá ààlà,+Mi ò sì ní ṣàìfi ìyà jẹ ọ́.’”
Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé
^ Ní Héb., “Nebukadirésárì,” ọ̀nà míì tí wọ́n ń gbà kọ orúkọ yìí.
^ Apata kékeré tí àwọn tafàtafà sábà máa ń gbé dání.
^ Irú èyí tí àwọn ọmọ ogun máa ń dé.
^ Ní Héb., “fi okùn sí.”
^ Tàbí “ìpakúpa.”
^ Ní Héb., “Nebukadirésárì,” ọ̀nà míì tí wọ́n ń gbà kọ orúkọ yìí.
^ Tàbí “Mémúfísì.”
^ Ní Héb., “àkókò tí a yàn.”
^ Ìyẹn, ẹni tó ṣẹ́gun Íjíbítì.
^ Tàbí “Mémúfísì.”
^ Tàbí kó jẹ́, “yóò di ahoro.”
^ Tàbí “tó ń kó igi jọ.”
^ Ìyẹn, Tíbésì.
^ Ní Héb., “Nebukadirésárì,” ọ̀nà míì tí wọ́n ń gbà kọ orúkọ yìí.
^ Tàbí “ọkàn.”
^ Ní Héb., “èso.”
^ Tàbí “tọ́ ọ sọ́nà.”