Jeremáyà 47:1-7
-
Àsọtẹ́lẹ̀ lórí àwọn Filísínì (1-7)
47 Ọ̀rọ̀ tí Jèhófà sọ nìyí fún wòlíì Jeremáyà nípa àwọn Filísínì,+ kí Fáráò tó pa Gásà run.
2 Ohun tí Jèhófà sọ nìyí:
“Wò ó! Omi ń bọ̀ láti àríwá.
Ó máa di ọ̀gbàrá tó kún àkúnya.
Á sì kún bo ilẹ̀ náà àti gbogbo ohun tó wà lórí rẹ̀,Pẹ̀lú ìlú náà àti àwọn tó ń gbé inú rẹ̀.
Àwọn ọkùnrin á figbe ta,Gbogbo ẹni tó ń gbé ilẹ̀ náà á sì pohùn réré ẹkún.
3 Nígbà tí pátákò àwọn akọ ẹṣin rẹ̀ bá ń kilẹ̀,Tí kẹ̀kẹ́ ogun rẹ̀ ń dúnTí àgbá kẹ̀kẹ́ rẹ̀ ń rọ́ gìrìgìrì,Àwọn bàbá kò tiẹ̀ ní bojú wẹ̀yìn wo àwọn ọmọ wọn,Nítorí ọwọ́ wọn ti rọ,
4 Nítorí ọjọ́ ń bọ̀ tí gbogbo Filísínì máa pa run;+Gbogbo olùrànlọ́wọ́ tó ṣẹ́ kù ní Tírè+ àti Sídónì+ la máa gé kúrò.
Nítorí Jèhófà máa pa àwọn Filísínì run,Àwọn tó ṣẹ́ kù láti erékùṣù Káfítórì.*+
5 Orí pípá* máa dé bá Gásà.
A ti pa Áṣíkẹ́lónì lẹ́nu mọ́.+
Ìwọ àṣẹ́kù àfonífojì* wọn,Ìgbà wo lo máa kọ ara rẹ lábẹ dà?+
6 Áà! Idà Jèhófà!+
Ìgbà wo lo máa tó gbé jẹ́ẹ́?
Pa dà sínú àkọ̀ rẹ.
Sinmi, kí o sì dákẹ́.
7 Báwo ló ṣe máa gbé jẹ́ẹ́
Nígbà tí Jèhófà ti pàṣẹ fún un?
Ó ti yàn án pé kí ó gbéjà ko
Áṣíkẹ́lónì àti etí òkun.”+
Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé
^ Ìyẹn, Kírétè.
^ Ìyẹn ni pé wọ́n á fá irun orí wọn torí pé wọ́n ń ṣọ̀fọ̀ àti pé ìtìjú bá wọn.
^ Tàbí “pẹ̀tẹ́lẹ̀.”