Lẹ́tà sí Àwọn Ará Kólósè 3:1-25
3 Tó bá jẹ́ pé a ti gbé yín dìde pẹ̀lú Kristi,+ ẹ máa wá àwọn nǹkan ti òkè, níbi tí Kristi jókòó sí ní ọwọ́ ọ̀tún Ọlọ́run.+
2 Ẹ máa ronú nípa àwọn nǹkan ti òkè,+ kì í ṣe nípa àwọn nǹkan ti ayé.+
3 Nítorí ẹ ti kú, a sì ti fi ìyè yín pa mọ́ sọ́dọ̀ Kristi ní ìṣọ̀kan pẹ̀lú Ọlọ́run.
4 Nígbà tí a bá fi Kristi, ìyè wa,+ hàn kedere, nígbà náà, a ó fi ẹ̀yin náà hàn kedere pẹ̀lú rẹ̀ nínú ògo.+
5 Nítorí náà, ẹ sọ àwọn ẹ̀yà ara yín+ tó wà láyé di òkú ní ti ìṣekúṣe,* ìwà àìmọ́, ìfẹ́ ìbálòpọ̀ tí kò níjàánu,+ ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ àti ojúkòkòrò, tó jẹ́ ìbọ̀rìṣà.
6 Tìtorí àwọn nǹkan yìí ni ìrunú Ọlọ́run ṣe ń bọ̀.
7 Bí ẹ̀yin náà ṣe ń ṣe* nìyẹn nínú ọ̀nà ìgbésí ayé yín ti tẹ́lẹ̀.*+
8 Àmọ́ ní báyìí, ẹ gbọ́dọ̀ mú gbogbo wọn kúrò lọ́dọ̀ yín: ìrunú, ìbínú, ìwà burúkú+ àti ọ̀rọ̀ èébú,+ kí ẹ sì mú ọ̀rọ̀ rírùn+ kúrò lẹ́nu yín.
9 Ẹ má ṣe máa parọ́ fún ara yín.+ Ẹ bọ́ ìwà* àtijọ́ sílẹ̀+ pẹ̀lú àwọn àṣà rẹ̀,
10 ẹ sì fi ìwà tuntun wọ ara yín láṣọ,+ èyí tí à ń fi ìmọ̀ tó péye sọ di tuntun, kí ó lè jọ àwòrán Ẹni tó dá a,+
11 níbi tí kò ti sí Gíríìkì tàbí Júù, ìdádọ̀dọ́* tàbí àìdádọ̀dọ́,* àjèjì, Sítíánì,* ẹrú tàbí òmìnira; àmọ́ Kristi ni ohun gbogbo, ó sì wà nínú ohun gbogbo.+
12 Nítorí náà, gẹ́gẹ́ bí àyànfẹ́ Ọlọ́run,+ ẹ̀yin tí ẹ jẹ́ mímọ́ àti olùfẹ́, ẹ fi ìfẹ́ oníjẹ̀lẹ́ńkẹ́ ti àánú,+ inú rere, ìrẹ̀lẹ̀,*+ ìwà tútù+ àti sùúrù+ wọ ara yín láṣọ.
13 Ẹ máa fara dà á fún ara yín, kí ẹ sì máa dárí ji ara yín fàlàlà,+ kódà tí ẹnikẹ́ni bá ní ìdí láti fẹ̀sùn kan ẹlòmíì.+ Bí Jèhófà* ṣe dárí jì yín ní fàlàlà, ẹ̀yin náà gbọ́dọ̀ máa ṣe bẹ́ẹ̀.+
14 Àmọ́, yàtọ̀ sí gbogbo àwọn nǹkan yìí, ẹ fi ìfẹ́ wọ ara yín láṣọ,+ nítorí ó jẹ́ ìdè ìrẹ́pọ̀ pípé.+
15 Bákan náà, ẹ jẹ́ kí àlàáfíà Kristi jọba lọ́kàn yín,*+ nítorí a ti pè yín sínú àlàáfíà yẹn nínú ara kan. Torí náà, ẹ máa dúpẹ́.
16 Ẹ jẹ́ kí ọ̀rọ̀ Kristi máa gbé inú yín lọ́pọ̀lọpọ̀ nínú gbogbo ọgbọ́n. Ẹ máa kọ́ ara yín, kí ẹ sì máa gba ara yín níyànjú* pẹ̀lú àwọn sáàmù,+ ìyìn sí Ọlọ́run, àwọn orin ẹ̀mí tí à ń fi ìmoore* kọ, kí ẹ máa kọrin sí Jèhófà* nínú ọkàn yín.+
17 Ohunkóhun tí ẹ bá ń ṣe ní ọ̀rọ̀ tàbí ní ìṣe, ẹ máa ṣe ohun gbogbo ní orúkọ Jésù Olúwa, kí ẹ máa tipasẹ̀ rẹ̀ dúpẹ́ lọ́wọ́ Ọlọ́run tó jẹ́ Baba.+
18 Ẹ̀yin aya, ẹ máa tẹrí ba fún àwọn ọkọ yín,+ bó ṣe yẹ nínú Olúwa.
19 Ẹ̀yin ọkọ, ẹ máa nífẹ̀ẹ́ àwọn aya yín,+ ẹ má sì bínú sí wọn lọ́nà òdì.*+
20 Ẹ̀yin ọmọ, ẹ máa gbọ́ràn sí àwọn òbí yín lẹ́nu nínú ohun gbogbo,+ nítorí èyí dára gidigidi lójú Olúwa.
21 Ẹ̀yin bàbá, ẹ má ṣe máa mú àwọn ọmọ yín bínú,*+ kí wọ́n má bàa soríkodò.*
22 Ẹ̀yin ẹrú, ẹ máa gbọ́ràn sí àwọn ọ̀gá yín* lẹ́nu nínú ohun gbogbo,+ kì í ṣe nígbà tí wọ́n bá ń wò yín nìkan, torí kí ẹ lè tẹ́ èèyàn lọ́rùn,* àmọ́ ẹ máa fòótọ́ ọkàn ṣe é pẹ̀lú ìbẹ̀rù Jèhófà.*
23 Ohunkóhun tí ẹ bá ń ṣe, ẹ ṣe é tọkàntọkàn* bíi pé Jèhófà* lẹ̀ ń ṣe é fún,+ kì í ṣe èèyàn,
24 torí ẹ mọ̀ pé ọ̀dọ̀ Jèhófà* lẹ ti máa gba ogún náà bí èrè.+ Ẹ máa ṣẹrú fún Ọ̀gá náà, Kristi.
25 Ó dájú pé ẹni tó ń ṣe àìtọ́ á gba ẹ̀san ohun tó ṣe,+ kò sì sí ojúsàájú kankan.+
Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé
^ Lédè Gíríìkì, por·neiʹa. Wo Àlàyé Ọ̀rọ̀.
^ Tàbí “ṣe rìn.”
^ Tàbí “nígbà tí ẹ̀ ń gbé irú ìgbé ayé yẹn.”
^ Ní Grk., “ọkùnrin.”
^ Tàbí “ìkọlà.”
^ Tàbí “àìkọlà.”
^ “Sítíánì” ń tọ́ka sí àwọn tí kò lajú.
^ Tàbí “ìrẹ̀lẹ̀ ọkàn.”
^ Tàbí “máa darí ọkàn yín.”
^ Tàbí “bá ara yín wí.”
^ Tàbí “oore ọ̀fẹ́.”
^ Tàbí “ẹ má sì kanra mọ́ wọn.”
^ Tàbí “ni àwọn ọmọ yín lára.”
^ Tàbí “rẹ̀wẹ̀sì.”
^ Ní Grk., “kì í ṣe àrójúṣe bíi ti àwọn tó máa ń fẹ́ wu èèyàn.”
^ Ní Grk., “ọ̀gá yín nípa tara.”
^ Wo Àlàyé Ọ̀rọ̀, “Ọkàn.”