Léfítíkù 26:1-46

  • Ẹ má ṣe bọ̀rìṣà (1, 2)

  • Ìbùkún tí wọ́n máa rí tí wọ́n bá ṣègbọràn (3-13)

  • Ìyà tí wọ́n máa jẹ tí wọ́n bá ṣàìgbọràn (14-46)

26  “‘Ẹ ò gbọ́dọ̀ ṣe àwọn ọlọ́run tí kò ní láárí fún ara yín,+ ẹ ò gbọ́dọ̀ ṣe ère gbígbẹ́+ tàbí ọwọ̀n òrìṣà fún ara yín, ẹ ò sì gbọ́dọ̀ gbé ère òkúta+ tí ẹ gbẹ́ sí ilẹ̀ yín láti forí balẹ̀ fún un;+ torí èmi ni Jèhófà Ọlọ́run yín.  Kí ẹ máa pa àwọn sábáàtì mi mọ́, kí ẹ sì máa bọ̀wọ̀ fún* ibi mímọ́ mi. Èmi ni Jèhófà.  “‘Tí ẹ bá ń tẹ̀ lé àwọn òfin mi, tí ẹ̀ ń pa àwọn àṣẹ mi mọ́, tí ẹ sì ń ṣe wọ́n,+  èmi yóò rọ ọ̀wààrà òjò fún yín ní àkókò tó yẹ,+ ilẹ̀ yóò mú èso jáde,+ àwọn igi oko yóò sì so èso.  Ẹ ó máa pakà títí di ìgbà tí ẹ máa kórè èso àjàrà, ẹ ó sì máa kórè èso àjàrà títí di ìgbà tí ẹ máa fúnrúgbìn; ẹ ó jẹun ní àjẹyó, ẹ ó sì máa gbé láìséwu ní ilẹ̀ yín.+  Màá mú kí àlàáfíà wà ní ilẹ̀ náà,+ ẹ ó sì dùbúlẹ̀ láìsí ẹni tó máa dẹ́rù bà yín;+ màá mú àwọn ẹranko burúkú kúrò ní ilẹ̀ náà, idà ogun ò sì ní kọjá ní ilẹ̀ yín.  Ó dájú pé ẹ máa lé àwọn ọ̀tá yín, ẹ ó sì fi idà ṣẹ́gun wọn.  Ẹ̀yin márùn-ún yóò lé ọgọ́rùn-ún (100), ẹ̀yin ọgọ́rùn-ún (100) yóò lé ẹgbẹ̀rún mẹ́wàá (10,000), ẹ ó sì fi idà ṣẹ́gun àwọn ọ̀tá yín.+  “‘Màá ṣojúure* sí yín, màá mú kí ẹ bímọ lémọ, kí ẹ sì di púpọ̀,+ màá sì mú májẹ̀mú tí mo bá yín dá ṣẹ.+ 10  Bí ẹ ṣe ń jẹ irè oko tó ṣẹ́ kù láti ọdún tó kọjá, ẹ máa ní láti palẹ̀ èyí tó ṣẹ́ kù mọ́ kí tuntun lè wọlé. 11  Màá gbé àgọ́ ìjọsìn mi sáàárín yín,+ mi* ò sì ní kọ̀ yín. 12  Èmi yóò máa rìn láàárín yín, èmi yóò sì jẹ́ Ọlọ́run yín,+ ẹ̀yin ní tiyín, yóò sì jẹ́ èèyàn mi.+ 13  Èmi ni Jèhófà Ọlọ́run yín, tó mú yín kúrò ní ilẹ̀ Íjíbítì, kí ẹ má bàa ṣe ẹrú wọn mọ́. Mo ṣẹ́ àwọn ọ̀pá àjàgà yín, mo sì mú kí ẹ lè nàró ṣánṣán bí ẹ ṣe ń rìn.* 14  “‘Àmọ́, tí ẹ ò bá fetí sí mi, tí ẹ ò sì pa gbogbo àṣẹ yìí mọ́,+ 15  tí ẹ bá kọ àwọn òfin mi,+ tí ẹ* sì kórìíra àwọn ìdájọ́ mi débi pé ẹ ò pa gbogbo àṣẹ mi mọ́, tí ẹ sì da májẹ̀mú mi,+ 16  èmi, ní tèmi, yóò ṣe nǹkan wọ̀nyí sí yín: màá kó ìdààmú bá yín láti fìyà jẹ yín, màá fi ikọ́ ẹ̀gbẹ àti akọ ibà ṣe yín, yóò mú kí ojú yín di bàìbàì, kí ẹ* sì ṣègbé. Lásán ni ẹ máa fún irúgbìn yín, torí àwọn ọ̀tá yín ni yóò jẹ ẹ́.+ 17  Mi ò ní fojúure wò yín, àwọn ọ̀tá yín á sì ṣẹ́gun yín;+ àwọn tó kórìíra yín yóò tẹ̀ yín mọ́lẹ̀,+ ẹ ó sì sá nígbà tí ẹnì kankan ò lé yín.+ 18  “‘Tí ẹ ò bá wá fetí sí mi lẹ́yìn èyí, ṣe ni màá fi ìyà ẹ̀ṣẹ̀ yín jẹ yín ní ìlọ́po méje. 19  Màá fòpin sí ìgbéraga yín, màá mú kí ojú ọ̀run yín dà bí irin+ àti ilẹ̀ yín bíi bàbà. 20  Lásán ni ẹ máa lo gbogbo agbára yín, torí ilẹ̀ yín kò ní mú èso rẹ̀ jáde,+ àwọn igi ilẹ̀ yín kò sì ní so èso. 21  “‘Tí ẹ bá ṣì ń kẹ̀yìn sí mi, tí ẹ ò sì fetí sí mi, ṣe ni màá fi ìyà ẹ̀ṣẹ̀ yín jẹ yín ní ìlọ́po méje. 22  Èmi yóò rán àwọn ẹran inú igbó sáàárín yín,+ wọ́n á pa yín lọ́mọ jẹ,+ wọ́n á pa àwọn ẹran ọ̀sìn yín run, wọ́n á dín iye yín kù, àwọn ọ̀nà yín yóò sì dá páropáro.+ 23  “‘Lẹ́yìn nǹkan wọ̀nyí, tí ẹ kò bá gba ìbáwí tí mo fún yín,+ tí ẹ ṣì ń kẹ̀yìn sí mi, 24  èmi náà yóò kẹ̀yìn sí yín, èmi fúnra mi yóò sì fìyà jẹ yín ní ìlọ́po méje torí ẹ̀ṣẹ̀ yín. 25  Èmi yóò mú idà ẹ̀san wá sórí yín torí ẹ da májẹ̀mú+ náà. Tí ẹ bá kóra jọ sínú àwọn ìlú yín, èmi yóò rán àrùn sí àárín yín,+ màá sì mú kí ọwọ́ àwọn ọ̀tá yín tẹ̀ yín.+ 26  Tí mo bá run ibi* tí ẹ kó búrẹ́dì*+ yín jọ sí, obìnrin mẹ́wàá ni yóò yan búrẹ́dì yín nínú ààrò kan ṣoṣo, wọ́n á máa wọn búrẹ́dì fún yín;+ ẹ ó jẹ, àmọ́ ẹ ò ní yó.+ 27  “‘Lẹ́yìn nǹkan wọ̀nyí, tí ẹ ò bá fetí sí mi, tí ẹ ṣì ń kẹ̀yìn sí mi, 28  èmi yóò túbọ̀ kẹ̀yìn sí yín,+ èmi fúnra mi yóò sì fi ìyà ẹ̀ṣẹ̀ yín jẹ yín ní ìlọ́po méje. 29  Torí náà, ṣe ni ẹ máa jẹ ẹran ara àwọn ọmọkùnrin yín, ẹ ó sì jẹ ẹran ara àwọn ọmọbìnrin yín.+ 30  Èmi yóò run àwọn ibi gíga+ tí ẹ ti ń sin àwọn òrìṣà yín, màá wó àwọn pẹpẹ tùràrí yín lulẹ̀, màá sì to òkú yín jọ pelemọ sórí òkú àwọn òrìṣà ẹ̀gbin*+ yín, èmi* yóò pa yín tì, màá sì kórìíra yín.+ 31  Èmi yóò mú kí idà pa àwọn ìlú yín,+ màá sì sọ àwọn ibi mímọ́ yín di ahoro, mi ò ní gbọ́ òórùn dídùn* àwọn ẹbọ yín. 32  Èmi fúnra mi yóò mú kí ilẹ̀ náà di ahoro,+ àwọn ọ̀tá yín tó ń gbé ibẹ̀ yóò sì máa wò ó tìyanutìyanu.+ 33  Èmi yóò tú yín ká sáàárín àwọn orílẹ̀-èdè,+ màá sì fa idà yọ látinú àkọ̀ láti lé yín bá;+ ilẹ̀ yín yóò di ahoro,+ àwọn ìlú yín yóò sì pa run. 34  “‘Nígbà yẹn, ilẹ̀ náà yóò san àwọn sábáàtì rẹ̀ ní gbogbo ọjọ́ tó bá fi wà ní ahoro, nígbà tí ẹ bá wà ní ilẹ̀ àwọn ọ̀tá yín. Nígbà yẹn, ilẹ̀ náà máa sinmi,* torí ó gbọ́dọ̀ san àwọn sábáàtì rẹ̀ pa dà.+ 35  Yóò sinmi ní gbogbo ọjọ́ tó bá fi wà ní ahoro, torí kò sinmi nígbà àwọn sábáàtì yín, nígbà tí ẹ̀ ń gbé ibẹ̀. 36  “‘Ní ti àwọn tó bá yè é,+ màá fi ìbẹ̀rù kún ọkàn wọn ní ilẹ̀ àwọn ọ̀tá wọn; ìró ewé tí atẹ́gùn ń fẹ́ máa lé wọn sá, wọ́n á fẹsẹ̀ fẹ bí ẹni ń sá fún idà, wọ́n á sì ṣubú láìsí ẹni tó ń lé wọn.+ 37  Wọ́n á kọ lu ara wọn bí ẹni ń sá fún idà, bó tiẹ̀ jẹ́ pé kò sẹ́ni tó ń lé wọn. Ẹ ò ní lè kojú àwọn ọ̀tá yín.+ 38  Ẹ ó ṣègbé láàárín àwọn orílẹ̀-èdè,+ ilẹ̀ àwọn ọ̀tá yín yóò sì jẹ yín run. 39  Àwọn tó bá ṣẹ́ kù nínú yín máa jẹrà sí ilẹ̀ àwọn ọ̀tá yín+ torí ẹ̀ṣẹ̀ yín. Àní, wọn yóò jẹrà dà nù torí ẹ̀ṣẹ̀ àwọn bàbá wọn.+ 40  Wọ́n á wá jẹ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ ara wọn+ àti ẹ̀ṣẹ̀ àwọn bàbá wọn pẹ̀lú ìwà àìṣòótọ́ àwọn bàbá wọn, wọ́n á sì gbà pé àwọn ti hùwà àìṣòótọ́ torí wọ́n kẹ̀yìn sí mi.+ 41  Èmi náà sì kẹ̀yìn sí wọn,+ torí mo mú wọn wá sí ilẹ̀ àwọn ọ̀tá wọn.+ “‘Bóyá nígbà yẹn, wọ́n á rẹ ọkàn wọn tí wọn ò kọ nílà* wálẹ̀,+ wọ́n á sì wá jìyà ẹ̀ṣẹ̀ wọn. 42  Màá sì rántí májẹ̀mú tí mo bá Jékọ́bù dá+ àti májẹ̀mú tí mo bá Ísákì dá,+ màá rántí májẹ̀mú tí mo bá Ábúráhámù dá,+ màá sì rántí ilẹ̀ náà. 43  Nígbà tí wọ́n pa ilẹ̀ náà tì, ó ń san àwọn sábáàtì rẹ̀,+ ó wà ní ahoro nígbà tí wọn ò sí níbẹ̀, wọ́n sì ń jìyà ẹ̀ṣẹ̀ wọn, torí wọ́n kọ àwọn ìdájọ́ mi, wọ́n* sì kórìíra àwọn àṣẹ mi.+ 44  Àmọ́ láìka gbogbo èyí sí, nígbà tí wọ́n ṣì wà ní ilẹ̀ àwọn ọ̀tá wọn, mi ò ní kọ̀ wọ́n pátápátá+ tàbí kí n ta wọ́n nù débi pé màá pa wọ́n run pátápátá, torí ìyẹn á da májẹ̀mú tí mo bá wọn dá,+ torí èmi ni Jèhófà Ọlọ́run wọn. 45  Nítorí wọn, màá rántí májẹ̀mú tí mo bá àwọn baba ńlá wọn dá,+ àwọn tí mo mú kúrò ní ilẹ̀ Íjíbítì níṣojú àwọn orílẹ̀-èdè,+ láti fi hàn pé èmi ni Ọlọ́run wọn. Èmi ni Jèhófà.’” 46  Èyí ni àwọn ìlànà, àwọn ìdájọ́ àti àwọn òfin tí Jèhófà gbé kalẹ̀ láàárín òun àti àwọn ọmọ Ísírẹ́lì lórí Òkè Sínáì nípasẹ̀ Mósè.+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé

Ní Héb., “bẹ̀rù.”
Ní Héb., “yíjú.”
Ní Héb., “ọkàn mi.”
Tàbí “rìn pẹ̀lú orí yín lókè.”
Tàbí “ọkàn yín.”
Tàbí “ọkàn yín.”
Tàbí “oúnjẹ.”
Ní Héb., “ọ̀pá.” Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ àwọn ọ̀pá tí wọ́n fi ń tọ́jú búrẹ́dì.
Ó ṣeé ṣe kí ọ̀rọ̀ Hébérù yìí ní í ṣe pẹ̀lú ọ̀rọ̀ tí wọ́n ń lò fún “ìgbẹ́,” wọ́n sì máa ń lò ó fún ohun tí wọ́n bá kórìíra.
Tàbí “ọkàn mi.”
Tàbí “tó tuni lójú.” Ní Héb., “atura.”
Tàbí “pa sábáàtì mọ́.”
Tàbí “ọkàn wọn tó le;” “tí wọn ò dá bí ẹni dá adọ̀dọ́.”
Tàbí “ọkàn wọn.”