Léfítíkù 27:1-34

  • Ríra ohun téèyàn jẹ́jẹ̀ẹ́ rẹ̀ pa dà (1-27)

  • Àwọn ohun téèyàn yà sọ́tọ̀ pátápátá fún Jèhófà (28, 29)

  • Ríra ìdá mẹ́wàá pa dà (30-34)

27  Jèhófà ń bá ọ̀rọ̀ tó ń sọ fún Mósè lọ pé:  “Sọ fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì pé, ‘Tí ẹnì kan bá jẹ́ ẹ̀jẹ́ pàtàkì+ láti mú iye tí wọ́n dá lé ẹnì* kan wá fún Jèhófà,  kí iye tí wọ́n máa dá lé ọkùnrin tó jẹ́ ẹni ogún (20) ọdún sí ọgọ́ta (60) ọdún jẹ́ àádọ́ta (50) ṣékélì* fàdákà, kó jẹ́ ìwọ̀n ṣékélì ibi mímọ́.*  Àmọ́ tó bá jẹ́ obìnrin, kí iye tí wọ́n máa dá lé e jẹ́ ọgbọ̀n (30) ṣékélì.  Tí ẹni náà bá jẹ́ ẹni ọdún márùn-ún sí ogún (20) ọdún, kí iye tí wọ́n máa dá lé ọkùnrin jẹ́ ogún (20) ṣékélì, kí ti obìnrin sì jẹ́ ṣékélì mẹ́wàá.  Tó bá jẹ́ ọmọ oṣù kan sí ọdún márùn-ún, kí iye tí wọ́n máa dá lé ọkùnrin jẹ́ ṣékélì fàdákà márùn-ún, kí ti obìnrin sì jẹ́ ṣékélì fàdákà mẹ́ta.  “‘Tó bá jẹ́ ẹni ọgọ́ta (60) ọdún sókè, kí iye tí wọ́n máa dá lé ọkùnrin jẹ́ ṣékélì mẹ́ẹ̀ẹ́dógún (15), kí ti obìnrin sì jẹ́ ṣékélì mẹ́wàá.  Àmọ́ tí ẹni náà bá tòṣì débi pé kò lè san owó náà,+ kó dúró níwájú àlùfáà, kí àlùfáà sì díye lé e. Kí iye tí àlùfáà máa dá lé e jẹ́ iye tí agbára ẹni tó jẹ́jẹ̀ẹ́ náà máa ká.+  “‘Tó bá jẹ́ ẹran tó bójú mu láti fi ṣe ọrẹ fún Jèhófà ló jẹ́jẹ̀ẹ́ pé òun máa mú wá, ohunkóhun tó bá fún Jèhófà yóò di mímọ́. 10  Kó má pààrọ̀ rẹ̀, kó má sì fi èyí tó dáa rọ́pò èyí tí kò dáa tàbí kó fi èyí tí kò dáa rọ́pò èyí tó dáa. Àmọ́ tó bá fi ẹran pààrọ̀ ẹran, ẹran tó pààrọ̀ àti èyí tó fi pààrọ̀ yóò di ohun mímọ́. 11  Tó bá jẹ́ ẹran aláìmọ́,+ tí kò bójú mu ló mú wá láti fi ṣe ọrẹ fún Jèhófà, kó mú kí ẹran náà dúró níwájú àlùfáà. 12  Kí àlùfáà wá díye lé e, bó bá ṣe dáa tàbí bó ṣe burú sí. Iye tí àlùfáà bá dá lé e ni yóò jẹ́. 13  Àmọ́ tó bá tiẹ̀ fẹ́ rà á pa dà, ó gbọ́dọ̀ fi ìdá márùn-ún iye tí wọ́n dá lé e kún un.+ 14  “‘Tí ẹnì kan bá ya ilé rẹ̀ sí mímọ́, tó fi ṣe ohun mímọ́ fún Jèhófà, kí àlùfáà díye lé e, bó bá ṣe dáa tàbí bó ṣe burú sí. Iye tí àlùfáà bá dá lé e ni iye owó rẹ̀ yóò jẹ́.+ 15  Àmọ́ tí ẹni tó ya ilé náà sí mímọ́ bá fẹ́ rà á pa dà, ó gbọ́dọ̀ fi ìdá márùn-ún iye tí wọ́n dá lé e kún un, yóò sì di tirẹ̀. 16  “‘Tí ẹnì kan bá ya apá kan lára ilẹ̀ rẹ̀ sí mímọ́ fún Jèhófà, iye irúgbìn tí wọ́n máa fún sínú rẹ̀ ni wọ́n á fi díwọ̀n iye tí wọ́n máa dá lé e: ọkà bálì tó kún òṣùwọ̀n hómérì* kan máa jẹ́ àádọ́ta (50) ṣékélì fàdákà. 17  Tó bá ya ilẹ̀ rẹ̀ sí mímọ́ láti ọdún Júbílì,+ iye tí wọ́n dá lé e kò ní yí pa dà. 18  Tó bá jẹ́ ẹ̀yìn ọdún Júbílì ló ya ilẹ̀ rẹ̀ sí mímọ́, kí àlùfáà fi iye ọdún tó ṣẹ́ kù kí ọdún Júbílì tó ń bọ̀ tó dé ṣírò owó rẹ̀ fún un, kó sì yọ kúrò nínú iye tí wọ́n dá lé e.+ 19  Àmọ́ tí ẹni tó ya ilẹ̀ náà sí mímọ́ bá tiẹ̀ fẹ́ rà á pa dà, ó gbọ́dọ̀ fi ìdá márùn-ún iye tí wọ́n dá lé e kún un, yóò sì di tirẹ̀. 20  Tí kò bá wá ra ilẹ̀ náà pa dà, tí wọ́n sì tà á fún ẹlòmíì, kò ní lè rà á pa dà mọ́. 21  Tí wọ́n bá yọ̀ǹda ilẹ̀ náà lọ́dún Júbílì, yóò di ohun mímọ́ fún Jèhófà, ilẹ̀ tí wọ́n yà sọ́tọ̀ fún un. Ó máa di ohun ìní àwọn àlùfáà.+ 22  “‘Tí ẹnì kan bá ra ilẹ̀ kan, tí kì í ṣe ara ohun tó jogún,+ tó sì yà á sí mímọ́ fún Jèhófà, 23  kí àlùfáà bá a ṣírò owó rẹ̀ títí di ọdún Júbílì, kó sì san iye tí wọ́n dá lé e ní ọjọ́ yẹn.+ Ohun mímọ́ ló jẹ́ fún Jèhófà. 24  Ní ọdún Júbílì, ilẹ̀ náà yóò pa dà di ti ẹni tó tà á fún un, yóò di ti ẹni tó ni ilẹ̀ náà.+ 25  “‘Ṣékélì ibi mímọ́ ni kí ẹ fi díwọ̀n gbogbo owó náà. Kí ṣékélì náà jẹ́ ogún (20) òṣùwọ̀n gérà.* 26  “‘Àmọ́, kí ẹnì kankan má ya àkọ́bí ẹran sí mímọ́, torí ti Jèhófà ni àkọ́bí tí ẹran bá bí.+ Ì báà jẹ́ akọ màlúù tàbí àgùntàn, Jèhófà ló ni ín.+ 27  Tó bá wà lára àwọn ẹran aláìmọ́, tó sì tún un rà pa dà gẹ́gẹ́ bí iye tí wọ́n dá lé e, kó fi ìdá márùn-ún rẹ̀ kún un.+ Àmọ́ tí kò bá rà á pa dà, iye tí wọ́n dá lé e ni kí wọ́n tà á. 28  “‘Àmọ́ tí ẹnì kan bá ti ya ohunkóhun sọ́tọ̀ pátápátá* fún Jèhófà látinú àwọn ohun tó ní, ì báà jẹ́ èèyàn tàbí ẹran tàbí ilẹ̀ tó jẹ́ tirẹ̀, kò gbọ́dọ̀ tà á tàbí kó rà á pa dà. Gbogbo ohun tí èèyàn bá ti yà sọ́tọ̀ jẹ́ ohun mímọ́ jù lọ fún Jèhófà.+ 29  Bákan náà, ẹ ò gbọ́dọ̀ ra ẹnikẹ́ni tí a máa pa run pa dà.+ Ṣe ni kí ẹ pa á.+ 30  “‘Gbogbo ìdá mẹ́wàá+ ilẹ̀ náà jẹ́ ti Jèhófà, ì báà jẹ́ látinú irè oko ilẹ̀ náà tàbí èso igi. Ohun mímọ́ fún Jèhófà ni. 31  Tí ẹnì kan bá fẹ́ ra èyíkéyìí nínú ìdá mẹ́wàá rẹ̀ pa dà, kó fi ìdá márùn-ún rẹ̀ kún un. 32  Ní ti gbogbo ìdá mẹ́wàá ọ̀wọ́ ẹran àti agbo ẹran, gbogbo ohun tó bá kọjá lábẹ́ ọ̀pá olùṣọ́ àgùntàn, kí ẹran* kẹwàá di ohun mímọ́ fún Jèhófà. 33  Kó má yẹ̀ ẹ́ wò bóyá ó dáa tàbí kò dáa, kó má sì pààrọ̀ rẹ̀. Àmọ́ tó bá gbìyànjú láti pààrọ̀ rẹ̀ pẹ́nrẹ́n, èyí tó fẹ́ pààrọ̀ àti èyí tó fi pààrọ̀ yóò di ohun mímọ́.+ Kò gbọ́dọ̀ rà á pa dà.’” 34  Èyí ni àwọn àṣẹ tí Jèhófà pa fún Mósè ní Òkè Sínáì+ pé kó sọ fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì.

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé

Tàbí “ọkàn.”
Ṣékélì kan jẹ́ gíráàmù 11.4. Wo Àfikún B14.
Tàbí “ṣékélì mímọ́.”
Hómérì kan jẹ́ òṣùwọ̀n tó gba Lítà 220. Wo Àfikún B14.
Gérà kan jẹ́ gíráàmù 0.57. Wo Àfikún B14.
Tàbí “fún ìparun.”
Tàbí “orí.”