Léfítíkù 5:1-19
5 “‘Tí ẹnì* kan bá gbọ́ tí wọ́n ń kéde ní gbangba pé kí ẹni tó bá mọ̀ nípa ọ̀rọ̀ kan wá jẹ́rìí sí i,*+ tí ẹni náà sì jẹ́ ẹlẹ́rìí ọ̀rọ̀ náà tàbí tó ṣojú rẹ̀ tàbí tó mọ̀ nípa rẹ̀, àmọ́ tí kò sọ, ó ti ṣẹ̀, yóò sì jìyà ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀.
2 “‘Tàbí tí ẹnì* kan bá fara kan ohun àìmọ́ èyíkéyìí, yálà òkú ẹran inú igbó tó jẹ́ aláìmọ́, ẹran ọ̀sìn tó jẹ́ aláìmọ́ tàbí ọ̀kan lára àwọn ohun alààyè tó ń gbá yìn-ìn tó jẹ́ aláìmọ́,+ ẹni náà máa di aláìmọ́, á sì jẹ̀bi, kódà tí kò bá tiẹ̀ mọ̀.
3 Tó bá sì ṣẹlẹ̀ pé ẹnì kan fara kan ohun àìmọ́ ti èèyàn+ láìmọ̀, ohun àìmọ́ èyíkéyìí tó lè sọ ọ́ di aláìmọ́, tó sì wá mọ̀, ó ti jẹ̀bi.
4 “‘Tàbí tí ẹnì* kan bá búra láìronú jinlẹ̀ pé òun máa ṣe ohun kan, yálà ohun tó dáa tàbí ohun tí kò dáa, ohun yòówù kó jẹ́, tí kò sì mọ̀, àmọ́ tó wá mọ̀ pé òun ti búra láìronú jinlẹ̀, ó ti jẹ̀bi.*+
5 “‘Tó bá jẹ̀bi torí pé ó ṣe ọ̀kan nínú àwọn nǹkan yìí, kó jẹ́wọ́+ èyí tó ṣe gan-an.
6 Kó tún mú ẹbọ ẹ̀bi rẹ̀ wá fún Jèhófà torí ẹ̀ṣẹ̀ tó dá,+ ìyẹn abo ẹran látinú agbo ẹran láti fi rú ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀, ó lè jẹ́ abo ọ̀dọ́ àgùntàn tàbí abo ọmọ ewúrẹ́. Àlùfáà yóò wá ṣe ètùtù fún un torí ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀.
7 “‘Àmọ́ tí agbára rẹ̀ ò bá gbé àgùntàn, kó mú ẹyẹ oriri méjì tàbí ọmọ ẹyẹlé méjì+ wá fún Jèhófà láti fi rú ẹbọ ẹ̀bi fún ẹ̀ṣẹ̀ tó dá, ọ̀kan fún ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀, ìkejì fún ẹbọ sísun.+
8 Kó mú wọn wá fún àlùfáà, kí àlùfáà kọ́kọ́ mú èyí tó jẹ́ ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀ wá, kó sì já orí rẹ̀ níwájú ọrùn rẹ̀ láìjá a sọ́tọ̀ọ̀tọ̀.
9 Kó wọ́n lára ẹ̀jẹ̀ ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀ náà sí ẹ̀gbẹ́ pẹpẹ, àmọ́ kó ro ẹ̀jẹ̀ tó kù sí ìsàlẹ̀ pẹpẹ.+ Ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀ ni.
10 Kó fi ìkejì rú ẹbọ sísun bí wọ́n ṣe máa ń ṣe é;+ kí àlùfáà sì ṣe ètùtù fún un torí ẹ̀ṣẹ̀ tó dá, yóò sì rí ìdáríjì.+
11 “‘Tí agbára rẹ̀ ò bá wá ká ẹyẹ oriri méjì tàbí ọmọ ẹyẹlé méjì, kó mú ìyẹ̀fun tó kúnná tó jẹ́ ìdá mẹ́wàá òṣùwọ̀n eéfà*+ wá láti fi rú ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀ torí ẹ̀ṣẹ̀ tó dá. Kó má da òróró sí i, kó má sì fi oje igi tùràrí sí i, torí ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀ ni.
12 Kó gbé e wá fún àlùfáà, kí àlùfáà sì bu ẹ̀kúnwọ́ ìyẹ̀fun náà, kó fi ṣe ọrẹ ìṣàpẹẹrẹ,* kó sì mú kó rú èéfín lórí pẹpẹ lórí àwọn ọrẹ àfinásun sí Jèhófà. Ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀ ni.
13 Kí àlùfáà ṣe ètùtù fún un torí ẹ̀ṣẹ̀ tó dá, èyí tó wù kó jẹ́ nínú àwọn ẹ̀ṣẹ̀ yìí, yóò sì rí ìdáríjì.+ Èyí tó ṣẹ́ kù nínú ọrẹ náà yóò di ti àlùfáà,+ bíi ti ọrẹ ọkà.’”+
14 Jèhófà ń bá ọ̀rọ̀ tó ń sọ fún Mósè lọ pé:
15 “Tí ẹnì* kan bá hùwà àìṣòótọ́, ní ti pé ó ṣèèṣì ṣẹ̀ sí àwọn ohun mímọ́ Jèhófà,+ kó mú àgbò tí ara rẹ̀ dá ṣáṣá wá fún Jèhófà látinú agbo ẹran, kó fi rú ẹbọ ẹ̀bi;+ ṣékélì ibi mímọ́*+ ni kí wọ́n fi díwọ̀n iye ṣékélì* fàdákà rẹ̀.
16 Kó san nǹkan kan dípò ẹ̀ṣẹ̀ tó ṣẹ̀ sí ibi mímọ́, kó sì fi ìdá márùn-ún rẹ̀ kún un.+ Kó fún àlùfáà, kí àlùfáà lè fi àgbò ẹbọ ẹ̀bi ṣe ètùtù+ fún un, yóò sì rí ìdáríjì.+
17 “Tí ẹnì* kan bá ṣe èyíkéyìí nínú àwọn ohun tí Jèhófà pa láṣẹ pé kí ẹ má ṣe, tó sì tipa bẹ́ẹ̀ ṣẹ̀, bí kò bá tiẹ̀ mọ̀, yóò jìyà ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀ torí ó ṣì jẹ̀bi.+
18 Kó mú àgbò tí ara rẹ̀ dá ṣáṣá wá fún àlùfáà látinú agbo ẹran, láti fi rú ẹbọ ẹ̀bi,+ kí àgbò náà tó iye tí wọ́n dá lé e. Àlùfáà yóò wá ṣe ètùtù fún un torí àṣìṣe tó ṣe láìmọ̀ọ́mọ̀, yóò sì rí ìdáríjì.
19 Ẹbọ ẹ̀bi ni. Ó dájú pé ó ti jẹ̀bi torí ó ṣẹ Jèhófà.”
Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé
^ Ní Héb., “ó gbọ́ ohùn ègún (ìbúra).” Ó lè jẹ́ ìkéde nípa ẹ̀ṣẹ̀ tí ẹnì kan dá tó ní nínú ègún tí wọ́n gé fún ẹni tó dẹ́ṣẹ̀ tàbí fún ẹni tí ọ̀rọ̀ náà ṣojú rẹ̀ tó bá kọ̀ láti jẹ́rìí sí i.
^ Tàbí “ọkàn.”
^ Tàbí “ọkàn.”
^ Tàbí “ọkàn.”
^ Ohun tó ṣeé ṣe kó túmọ̀ sí ni pé kò mú ẹ̀jẹ́ rẹ̀ ṣẹ.
^ Ìdá mẹ́wàá òṣùwọ̀n eéfà kan jẹ́ Lítà 2.2. Wo Àfikún B14.
^ Tàbí “ohun ìrántí (ìṣàpẹẹrẹ) látinú rẹ̀.”
^ Tàbí “ọkàn.”
^ Ṣékélì kan jẹ́ gíráàmù 11.4. Wo Àfikún B14.
^ Tàbí “ṣékélì mímọ́.”
^ Tàbí “ọkàn.”