Léfítíkù 7:1-38

  • Ìtọ́ni nípa àwọn ọrẹ (1-21)

    • Ẹbọ ẹ̀bi (1-10)

    • Ẹbọ ìrẹ́pọ̀ (11-21)

  • Ẹ ò gbọ́dọ̀ jẹ ọ̀rá tàbí ẹ̀jẹ̀ (22-27)

  • Ìpín àlùfáà (28-36)

  • Ọ̀rọ̀ ìparí nípa àwọn ọrẹ (37, 38)

7  “‘Òfin ẹbọ ẹ̀bi+ nìyí: Ohun mímọ́ jù lọ ni.  Ibi tí wọ́n ti ń pa ẹran ẹbọ sísun ni kí wọ́n ti pa ẹran ẹbọ ẹ̀bi, kí wọ́n sì wọ́n ẹ̀jẹ̀ rẹ̀+ sí gbogbo ẹ̀gbẹ́ pẹpẹ.+  Kó mú gbogbo ọ̀rá rẹ̀+ wá, pẹ̀lú ìrù ọlọ́ràá, ọ̀rá tó bo ìfun  àti kíndìnrín méjèèjì pẹ̀lú ọ̀rá wọn tó wà nítòsí abẹ́nú. Kó tún yọ àmọ́ tó wà lára ẹ̀dọ̀ pẹ̀lú àwọn kíndìnrín náà.+  Kí àlùfáà mú kí wọ́n rú èéfín lórí pẹpẹ, kó fi ṣe ọrẹ àfinásun sí Jèhófà.+ Ẹbọ ẹ̀bi ni.  Kí gbogbo ọkùnrin tó jẹ́ àlùfáà jẹ ẹ́,+ ibi mímọ́ ni kí wọ́n sì ti jẹ ẹ́. Ohun mímọ́ jù lọ ni.+  Òfin ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀ náà kan ẹbọ ẹ̀bi; àlùfáà tó fi ṣe ètùtù ló ni ín.+  “‘Tí àlùfáà bá mú ẹbọ sísun tó jẹ́ ti ẹnì kan wá, awọ+ ẹran ẹbọ sísun tó mú wá fún àlùfáà yóò di tirẹ̀.  “‘Gbogbo ọrẹ ọkà tí wọ́n bá yan nínú ààrò tàbí tí wọ́n sè nínú páànù tàbí nínú agbada+ jẹ́ ti àlùfáà tó mú un wá. Yóò di tirẹ̀.+ 10  Àmọ́ gbogbo ọrẹ ọkà tí wọ́n pò mọ́ òróró+ tàbí tó gbẹ+ yóò jẹ́ ti gbogbo àwọn ọmọ Áárónì; ìpín kálukú máa dọ́gba. 11  “‘Òfin ẹbọ ìrẹ́pọ̀+ tí ẹnì kan bá mú wá fún Jèhófà nìyí: 12  Tó bá mú un wá láti fi ṣe ìdúpẹ́,+ kó mú ẹbọ ìdúpẹ́ náà wá pẹ̀lú búrẹ́dì aláìwú tí wọ́n pò mọ́ òróró, tó sì rí bí òrùka, búrẹ́dì aláìwú pẹlẹbẹ tí wọ́n pò mọ́ òróró àti búrẹ́dì tó rí bí òrùka tí wọ́n fi ìyẹ̀fun tó kúnná ṣe, tí wọ́n pò dáadáa tí wọ́n sì pò mọ́ òróró. 13  Kó mú ọrẹ rẹ̀ wá pẹ̀lú búrẹ́dì tí wọ́n fi ìwúkàrà sí tó rí bí òrùka, kó sì mú ẹbọ ìdúpẹ́ ti ẹbọ ìrẹ́pọ̀ rẹ̀ wá. 14  Kó mú ọ̀kan lára ọrẹ kọ̀ọ̀kan wá nínú rẹ̀ láti fi ṣe ìpín mímọ́ fún Jèhófà; yóò di ti àlùfáà tó wọ́n ẹ̀jẹ̀ ẹbọ ìrẹ́pọ̀.+ 15  Ọjọ́ tó bá mú ẹbọ ìdúpẹ́ ti ẹbọ ìrẹ́pọ̀ rẹ̀ wá ni kó jẹ ẹran rẹ̀. Kò gbọ́dọ̀ ṣẹ́ ìkankan nínú rẹ̀ kù di àárọ̀.+ 16  “‘Tí ohun tó bá fi rúbọ bá jẹ́ ti ẹ̀jẹ́+ tàbí ọrẹ àtinúwá,+ ọjọ́ tó bá mú ọrẹ rẹ̀ wá ni kó jẹ ẹ́, kó sì jẹ ohun tó bá ṣẹ́ kù lára rẹ̀ ní ọjọ́ kejì. 17  Àmọ́ kó fi iná sun+ ohunkóhun tó bá ṣẹ́ kù di ọjọ́ kẹta lára ẹran tó fi rúbọ. 18  Tí wọ́n bá jẹ èyíkéyìí lára ẹran ẹbọ ìrẹ́pọ̀ rẹ̀ ní ọjọ́ kẹta, ẹni tó mú un wá kò ní rí ìtẹ́wọ́gbà. Kò ní rí ojú rere; ohun tí kò tọ́ ni, ẹni* tó bá sì jẹ lára rẹ̀ yóò jìyà ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀.+ 19  Ẹ ò gbọ́dọ̀ jẹ ẹran tó bá fara kan ohun àìmọ́ èyíkéyìí. Ṣe ni kí ẹ fi iná sun ún. Gbogbo ẹni tó bá mọ́ lè jẹ ẹran tó mọ́. 20  “‘Àmọ́ tí ẹnikẹ́ni* tó jẹ́ aláìmọ́ bá jẹ ẹran ẹbọ ìrẹ́pọ̀, tó jẹ́ ti Jèhófà, kí ẹ pa ẹni* náà, kí ẹ lè mú un kúrò láàárín àwọn èèyàn rẹ̀.+ 21  Tí ẹnì* kan bá fara kan ohunkóhun tó jẹ́ aláìmọ́, yálà ohun àìmọ́ ti èèyàn+ tàbí ẹranko aláìmọ́+ tàbí ohunkóhun tó jẹ́ aláìmọ́ tó sì ń ríni lára,+ tí ẹni náà sì jẹ lára ẹran ẹbọ ìrẹ́pọ̀ náà, tó jẹ́ ti Jèhófà, kí ẹ pa ẹni* náà, kí ẹ lè mú un kúrò láàárín àwọn èèyàn rẹ̀.’” 22  Jèhófà ń bá ọ̀rọ̀ tó ń sọ fún Mósè lọ pé: 23  “Sọ fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì pé, ‘Ẹ ò gbọ́dọ̀ jẹ ọ̀rá+ èyíkéyìí láti ara akọ màlúù tàbí ọmọ àgbò tàbí ewúrẹ́. 24  Ẹ lè fi ọ̀rá òkú ẹran àti ọ̀rá ẹran tí ẹranko míì pa ṣe nǹkan míì, àmọ́ ẹ ò gbọ́dọ̀ jẹ ẹ́.+ 25  Tí ẹnikẹ́ni bá jẹ ọ̀rá ẹran tó mú wá láti fi ṣe ọrẹ àfinásun sí Jèhófà, kí ẹ pa onítọ̀hún kí ẹ lè mú un kúrò láàárín àwọn èèyàn rẹ̀. 26  “‘Ẹ ò gbọ́dọ̀ jẹ ẹ̀jẹ̀ èyíkéyìí+ ní gbogbo ibi tí ẹ̀ ń gbé, ì báà jẹ́ ti ẹyẹ tàbí ti ẹranko. 27  Kí ẹ pa ẹnikẹ́ni* tó bá jẹ ẹ̀jẹ̀ èyíkéyìí kí ẹ lè mú un kúrò+ láàárín àwọn èèyàn rẹ̀.’” 28  Jèhófà wá sọ fún Mósè pé: 29  “Sọ fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì pé, ‘Kí ẹnikẹ́ni tó bá fẹ́ mú ẹbọ ìrẹ́pọ̀ wá fún Jèhófà mú ọrẹ wá fún Jèhófà látinú ẹbọ ìrẹ́pọ̀ rẹ̀.+ 30  Ọwọ́ ara rẹ̀ ni kó fi mú ọ̀rá+ pẹ̀lú igẹ̀ wá láti fi ṣe ọrẹ àfinásun sí Jèhófà, kó sì fì í síwá-sẹ́yìn bí ọrẹ fífì+ níwájú Jèhófà. 31  Kí àlùfáà mú kí ọ̀rá náà rú èéfín lórí pẹpẹ,+ àmọ́ igẹ̀ náà jẹ́ ti Áárónì àti àwọn ọmọ rẹ̀.+ 32  “‘Kí ẹ fún àlùfáà ní ẹsẹ̀ ọ̀tún, kó jẹ́ ìpín mímọ́ tirẹ̀ látinú àwọn ẹbọ ìrẹ́pọ̀+ yín. 33  Kí ẹsẹ̀ ọ̀tún jẹ́ ìpín+ ọmọ Áárónì tó bá mú ẹ̀jẹ̀ ẹbọ ìrẹ́pọ̀ àti ọ̀rá wá. 34  Torí mo mú igẹ̀ ọrẹ fífì àti ẹsẹ̀ ìpín mímọ́ náà látinú àwọn ẹbọ ìrẹ́pọ̀ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì, mo sì fún àlùfáà Áárónì àti àwọn ọmọ rẹ̀, kó jẹ́ ìlànà tó máa wà fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì+ títí lọ. 35  “‘Ìpín tí wọ́n yà sọ́tọ̀ fún àwọn àlùfáà nìyí, fún Áárónì àti àwọn ọmọ rẹ̀, látinú àwọn ọrẹ àfinásun sí Jèhófà, ní ọjọ́ tó mú wọn wá síwájú Jèhófà láti ṣe àlùfáà rẹ̀.+ 36  Jèhófà pàṣẹ pé kí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì fún wọn ní ìpín yìí lọ́jọ́ tó fòróró yàn wọ́n.+ Àṣẹ tí wọ́n á máa pa mọ́ títí láé jálẹ̀ àwọn ìran wọn ni.’” 37  Èyí ni òfin nípa ẹbọ sísun,+ ọrẹ ọkà,+ ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀,+ ẹbọ ẹ̀bi,+ ẹbọ ìyannisípò+ àti ẹbọ ìrẹ́pọ̀,+ 38  bí Jèhófà ṣe pa á láṣẹ fún Mósè lórí Òkè Sínáì+ lọ́jọ́ tó pàṣẹ fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì pé kí wọ́n mú ọrẹ wọn wá fún Jèhófà ní aginjù Sínáì.+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé

Tàbí “ọkàn.”
Tàbí “ọkàn.”
Tàbí “ọkàn.”
Tàbí “ọkàn.”
Tàbí “ọkàn.”
Tàbí “ọkàn èyíkéyìí.”