Léfítíkù 9:1-24

  • Áárónì rú àwọn ẹbọ àfiyanni (1-24)

9  Ní ọjọ́ kẹjọ,+ Mósè pe Áárónì àti àwọn ọmọ rẹ̀ àti àwọn àgbààgbà Ísírẹ́lì.  Ó sọ fún Áárónì pé: “Mú ọmọ màlúù kan fún ara rẹ láti fi rú ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀+ àti àgbò kan láti fi rú ẹbọ sísun, kí ara wọn dá ṣáṣá, kí o sì mú wọn wá síwájú Jèhófà.  Àmọ́ kí o sọ fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì pé, ‘Ẹ mú akọ ewúrẹ́ kan láti fi rú ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀ àti ọmọ màlúù kan àti ọmọ àgbò kan, kí ọ̀kọ̀ọ̀kan jẹ́ ọlọ́dún kan tí ara rẹ̀ dá ṣáṣá, kí ẹ fi rú ẹbọ sísun,  kí ẹ sì mú akọ màlúù kan àti àgbò kan láti fi rú ẹbọ ìrẹ́pọ̀,+ kí ẹ fi wọ́n rúbọ níwájú Jèhófà, pẹ̀lú ọrẹ ọkà+ tí ẹ pò mọ́ òróró, torí Jèhófà yóò fara hàn+ yín lónìí.’”  Wọ́n mú ohun tí Mósè pa láṣẹ wá síwájú àgọ́ ìpàdé. Ni gbogbo àpéjọ náà bá sún mọ́ iwájú, wọ́n sì dúró níwájú Jèhófà.  Mósè sì sọ pé: “Ohun tí Jèhófà pàṣẹ pé kí ẹ ṣe nìyí, kí Jèhófà lè fi ògo rẹ̀ hàn yín.”+  Mósè wá sọ fún Áárónì pé: “Sún mọ́ pẹpẹ, kí o rú ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀+ rẹ àti ẹbọ sísun, kí o sì ṣe ètùtù fún ara rẹ+ àti ilé rẹ; mú ọrẹ àwọn èèyàn náà wá,+ kí o sì ṣe ètùtù fún wọn,+ bí Jèhófà ṣe pa á láṣẹ.”  Lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀, Áárónì sún mọ́ pẹpẹ, ó sì pa ọmọ màlúù ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀ tó jẹ́ tirẹ̀.+  Lẹ́yìn náà, àwọn ọmọ Áárónì gbé ẹ̀jẹ̀+ ẹran náà wá fún un, ó ki ìka rẹ̀ bọ ẹ̀jẹ̀ náà, ó sì fi sára àwọn ìwo pẹpẹ, ó wá da ẹ̀jẹ̀ tó kù sí ìsàlẹ̀ pẹpẹ.+ 10  Ó mú kí ọ̀rá àti àwọn kíndìnrín àti àmọ́ tó wà lára ẹ̀dọ̀ látinú ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀ náà rú èéfín lórí pẹpẹ, bí Jèhófà ṣe pa á láṣẹ fún Mósè.+ 11  Ó sì fi iná sun ẹran náà àti awọ rẹ̀ lẹ́yìn ibùdó.+ 12  Lẹ́yìn náà, ó pa ẹran ẹbọ sísun náà, àwọn ọmọ Áárónì gbé ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ fún un, ó sì wọ́n ọn sí gbogbo ẹ̀gbẹ́ pẹpẹ náà.+ 13  Wọ́n kó àwọn ègé ẹran ẹbọ sísun náà àti orí rẹ̀ fún un, ó sì mú kó rú èéfín lórí pẹpẹ. 14  Ó tún fọ ìfun àti ẹsẹ̀ rẹ̀, ó sì mú kó rú èéfín lórí ẹbọ sísun tó wà lórí pẹpẹ. 15  Lẹ́yìn náà, ó mú ọrẹ àwọn èèyàn náà wá, ó mú ewúrẹ́ tó fẹ́ fi rú ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀ fún àwọn èèyàn náà, ó sì pa á, ó sì fi rú ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀ bíi ti àkọ́kọ́. 16  Ó mú ẹbọ sísun náà wá, ó sì ṣe é bí wọ́n ṣe ń ṣe é.+ 17  Lẹ́yìn náà, ó mú ọrẹ ọkà+ wá, ó bu ẹ̀kúnwọ́ rẹ̀, ó sì mú kó rú èéfín lórí pẹpẹ, yàtọ̀ sí ẹbọ sísun tó sun ní àárọ̀.+ 18  Lẹ́yìn ìyẹn, ó pa akọ màlúù àti àgbò ẹbọ ìrẹ́pọ̀ tó jẹ́ ti àwọn èèyàn náà. Àwọn ọmọ Áárónì wá gbé ẹ̀jẹ̀ náà fún un, ó sì wọ́n ọn yí ká gbogbo ẹ̀gbẹ́ pẹpẹ.+ 19  Ní ti àwọn ọ̀rá akọ màlúù náà,+ ìrù àgbò náà tó lọ́ràá, ọ̀rá tó bo àwọn ohun tó wà nínú ẹran náà, àwọn kíndìnrín àti àmọ́ tó wà lára ẹ̀dọ̀,+ 20  wọ́n kó gbogbo àwọn ọ̀rá náà sórí àwọn igẹ̀, lẹ́yìn náà, ó mú kí àwọn ọ̀rá náà rú èéfín lórí pẹpẹ.+ 21  Àmọ́ Áárónì fi àwọn igẹ̀ àti ẹsẹ̀ ọ̀tún síwá-sẹ́yìn bí ọrẹ fífì níwájú Jèhófà, bí Mósè ṣe pa á láṣẹ.+ 22  Áárónì wá kọjú sí àwọn èèyàn náà, ó sì gbé ọwọ́ rẹ̀ sókè, ó súre fún wọn,+ ó sì sọ̀ kalẹ̀ kúrò níbi tó ti ń fi ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀, ẹbọ sísun àti ẹbọ ìrẹ́pọ̀ rúbọ. 23  Níkẹyìn, Mósè àti Áárónì lọ sínú àgọ́ ìpàdé, wọ́n jáde wá, wọ́n sì súre fún àwọn èèyàn náà.+ Jèhófà wá fi ògo rẹ̀ han gbogbo àwọn èèyàn náà,+ 24  iná sì bọ́ láti ọ̀dọ̀ Jèhófà,+ ó sì bẹ̀rẹ̀ sí í jó ẹbọ sísun àti àwọn ọ̀rá tó wà lórí pẹpẹ. Nígbà tí gbogbo àwọn èèyàn náà rí i, wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí í kígbe, wọ́n sì dojú bolẹ̀.+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé