Àkọsílẹ̀ Lúùkù 10:1-42
10 Lẹ́yìn àwọn nǹkan yìí, Olúwa yan àwọn àádọ́rin (70) míì, ó sì rán wọn jáde ṣáájú rẹ̀ ní méjì-méjì+ sínú gbogbo ìlú àti ibi tí òun fúnra rẹ̀ máa lọ.
2 Ó wá sọ fún wọn pé: “Òótọ́ ni, ìkórè pọ̀, àmọ́ àwọn òṣìṣẹ́ ò tó nǹkan. Torí náà, ẹ bẹ Ọ̀gá ìkórè pé kó rán àwọn òṣìṣẹ́ jáde láti bá a kórè.+
3 Ẹ lọ! Ẹ wò ó! Mò ń rán yín jáde bí ọ̀dọ́ àgùntàn sí àárín ìkookò.+
4 Ẹ má ṣe gbé àpò owó, àpò oúnjẹ tàbí bàtà,+ ẹ má sì kí ẹnikẹ́ni* lójú ọ̀nà.
5 Ibikíbi tí ẹ bá ti wọ ilé kan, ẹ kọ́kọ́ sọ pé: ‘Àlàáfíà fún ilé yìí o.’+
6 Tí ọ̀rẹ́ àlàáfíà bá sì wà níbẹ̀, àlàáfíà yín máa wá sórí rẹ̀. Àmọ́ tí kò bá sí, ó máa pa dà sọ́dọ̀ yín.
7 Torí náà, ẹ dúró sínú ilé yẹn,+ kí ẹ jẹ, kí ẹ sì mu ohun tí wọ́n bá pèsè,+ torí owó iṣẹ́ tọ́ sí òṣìṣẹ́.+ Ẹ má ṣe máa ti ilé kan bọ́ sí òmíràn.
8 “Bákan náà, ibikíbi tí ẹ bá ti wọ ìlú kan, tí wọ́n sì gbà yín, ẹ jẹ ohun tí wọ́n bá gbé síwájú yín,
9 kí ẹ wo àwọn aláìsàn tó wà níbẹ̀ sàn, kí ẹ sì sọ fún wọn pé: ‘Ìjọba Ọlọ́run ti sún mọ́ ọ̀dọ̀ yín.’+
10 Àmọ́ ibikíbi tí ẹ bá ti wọ ìlú kan, tí wọn ò sì gbà yín, ẹ lọ sí àwọn ọ̀nà rẹ̀ tó bọ́ sí gbangba, kí ẹ sì sọ pé:
11 ‘A nu eruku tó lẹ̀ mọ́ wa lẹ́sẹ̀ pàápàá látinú ìlú yín kúrò lòdì sí yín.+ Síbẹ̀, ẹ fi èyí sọ́kàn pé Ìjọba Ọlọ́run ti sún mọ́lé.’
12 Mò ń sọ fún yín pé Sódómù máa lè fara dà á ní ọjọ́ yẹn ju ìlú yẹn lọ.+
13 “O gbé, ìwọ Kórásínì! O gbé, ìwọ Bẹtisáídà! torí ká ní àwọn iṣẹ́ agbára tó ṣẹlẹ̀ nínú yín bá ṣẹlẹ̀ ní Tírè àti Sídónì ni, tipẹ́tipẹ́ ni wọ́n á ti ronú pìwà dà, tí wọ́n á jókòó pẹ̀lú aṣọ ọ̀fọ̀* àti eérú.+
14 Torí náà, Tírè àti Sídónì máa lè fara dà á lásìkò ìdájọ́ jù yín lọ.
15 Àti ìwọ, Kápánáúmù, ṣé a máa gbé ọ ga dé ọ̀run ni? Inú Isà Òkú* nísàlẹ̀ lo máa lọ!
16 “Ẹnikẹ́ni tó bá fetí sí yín, fetí sí mi.+ Ẹnikẹ́ni tí kò bá sì kà yín sí, kò ka èmi náà sí. Bákan náà, ẹnikẹ́ni tí kò bá kà mí sí, kò ka Ẹni tó rán mi náà sí.”+
17 Lẹ́yìn náà, àwọn àádọ́rin (70) náà pa dà dé tayọ̀tayọ̀, wọ́n ń sọ pé: “Olúwa, àwọn ẹ̀mí èṣù pàápàá tẹrí ba fún wa torí pé a lo orúkọ rẹ.”+
18 Ó wá sọ fún wọn pé: “Mo rí i tí Sátánì já bọ́+ bíi mànàmáná láti ọ̀run.
19 Ẹ wò ó! Mo ti fún yín ní àṣẹ láti fi ẹsẹ̀ tẹ àwọn ejò àti àkekèé mọ́lẹ̀ àti àṣẹ lórí gbogbo agbára ọ̀tá,+ kò sì ní sí ohunkóhun tó máa pa yín lára.
20 Ṣùgbọ́n, ẹ má yọ̀ torí pé a mú kí àwọn ẹ̀mí tẹrí ba fún yín, àmọ́ ẹ yọ̀ torí pé a ti kọ orúkọ yín sílẹ̀ ní ọ̀run.”+
21 Ní wákàtí yẹn gan-an, ó yọ̀ gidigidi nínú ẹ̀mí mímọ́, ó sì sọ pé: “Baba, Olúwa ọ̀run àti ayé, mo yìn ọ́ ní gbangba, torí pé o rọra fi àwọn nǹkan yìí pa mọ́ fún àwọn ọlọ́gbọ́n àti àwọn amòye,+ o sì ti ṣí wọn payá fún àwọn ọmọdé. Bẹ́ẹ̀ ni, Baba, torí pé ohun tí o fọwọ́ sí nìyí.+
22 Baba mi ti fa ohun gbogbo lé mi lọ́wọ́, kò sẹ́ni tó mọ ẹni tí Ọmọ jẹ́, àfi Baba, kò sì sẹ́ni tó mọ ẹni tí Baba jẹ́, àfi Ọmọ+ àti ẹnikẹ́ni tí Ọmọ bá fẹ́ ṣí i payá fún.”+
23 Ó wá yíjú sí àwọn ọmọ ẹ̀yìn, ó sì sọ fún wọn láwọn nìkan pé: “Aláyọ̀ ni àwọn ojú tó rí àwọn ohun tí ẹ̀ ń rí.+
24 Torí mò ń sọ fún yín pé, ó wu ọ̀pọ̀ àwọn wòlíì àti àwọn ọba pé kí wọ́n rí àwọn ohun tí ẹ̀ ń rí, àmọ́ wọn ò rí i,+ ó wù wọ́n kí wọ́n gbọ́ àwọn ohun tí ẹ̀ ń gbọ́, àmọ́ wọn ò gbọ́ ọ.”
25 Wò ó! ọkùnrin kan tó mọ Òfin dunjú dìde láti dán an wò, ó sì sọ pé: “Olùkọ́, kí ló yẹ kí n ṣe kí n lè jogún ìyè àìnípẹ̀kun?”+
26 Ó sọ fún un pé: “Kí la kọ sínú Òfin? Kí lo kà níbẹ̀?”
27 Ọkùnrin náà dáhùn pé: “‘Kí o fi gbogbo ọkàn rẹ àti gbogbo ara* rẹ àti gbogbo okun rẹ àti gbogbo èrò rẹ nífẹ̀ẹ́ Jèhófà* Ọlọ́run rẹ,’+ kí o sì ‘nífẹ̀ẹ́ ọmọnìkejì rẹ bí ara rẹ.’”+
28 Ó sọ fún un pé: “Ìdáhùn rẹ tọ́; máa ṣe bẹ́ẹ̀, o sì máa rí ìyè.”+
29 Àmọ́ ọkùnrin náà fẹ́ fi hàn pé olódodo ni òun,+ ó wá sọ fún Jésù pé: “Ta ni ọmọnìkejì mi gan-an?”
30 Jésù dáhùn pé: “Ọkùnrin kan ń sọ̀ kalẹ̀ lọ láti Jerúsálẹ́mù sí Jẹ́ríkò, ó sì bọ́ sọ́wọ́ àwọn ọlọ́ṣà, wọ́n bọ́ ọ láṣọ, wọ́n lù ú, wọ́n sì fi sílẹ̀ lọ nígbà tó ti fẹ́rẹ̀ẹ́ kú.
31 Ó ṣẹlẹ̀ pé àsìkò yẹn ni àlùfáà kan ń sọ̀ kalẹ̀ lọ lójú ọ̀nà yẹn, àmọ́ nígbà tó rí ọkùnrin náà, ó gba ọ̀nà tó wà ní òdìkejì kọjá lọ.
32 Bákan náà, nígbà tí ọmọ Léfì kan dé ibẹ̀, tó sì rí i, ó gba ọ̀nà tó wà ní òdìkejì kọjá lọ.
33 Àmọ́ ará Samáríà+ kan tó ń rìnrìn àjò gba ọ̀nà yẹn ṣàdédé bá a pàdé, nígbà tó rí i, àánú rẹ̀ ṣe é.
34 Torí náà, ó sún mọ́ ọn, ó di àwọn ọgbẹ́ rẹ̀, ó sì da òróró àti wáìnì sí i. Ó wá gbé e sórí ẹran rẹ̀, ó gbé e lọ sí ilé ìgbàlejò kan, ó sì tọ́jú rẹ̀.
35 Lọ́jọ́ kejì, ó mú owó dínárì* méjì jáde, ó fún olùtọ́jú ilé náà, ó sì sọ pé: ‘Tọ́jú rẹ̀, ohunkóhun tí o bá sì ná lẹ́yìn èyí, màá san án pa dà fún ọ tí mo bá dé.’
36 Lójú tìẹ, èwo nínú àwọn mẹ́ta yìí ló fi hàn pé òun jẹ́ ọmọnìkejì+ ọkùnrin tó bọ́ sọ́wọ́ àwọn ọlọ́ṣà náà?”
37 Ó sọ pé: “Ẹni tó ṣàánú rẹ̀ ni.”+ Jésù wá sọ fún un pé: “Ìwọ náà, lọ ṣe ohun kan náà.”+
38 Bí wọ́n ṣe ń lọ, ó wọ abúlé kan. Ibí ni obìnrin kan tó ń jẹ́ Màtá+ ti gbà á lálejò sínú ilé rẹ̀.
39 Ó tún ní arábìnrin kan tó ń jẹ́ Màríà, ẹni tó jókòó síbi ẹsẹ̀ Olúwa, tó sì ń fetí sí ohun tó ń sọ.*
40 Àmọ́ ní ti Màtá, ọ̀pọ̀lọpọ̀ ohun tó ń ṣe gbà á lọ́kàn. Torí náà, ó wá bá Jésù, ó sì sọ pé: “Olúwa, ṣé o ò rí i bí arábìnrin mi ṣe fi èmi nìkan sílẹ̀ láti bójú tó àwọn nǹkan ni? Sọ fún un pé kó wá ràn mí lọ́wọ́.”
41 Olúwa dá a lóhùn pé: “Màtá, Màtá, ò ń ṣàníyàn, o sì ń ṣèyọnu nípa nǹkan tó pọ̀.
42 Nǹkan díẹ̀ tàbí ẹyọ kan ṣoṣo la nílò. Màríà ní tiẹ̀, yan ìpín rere,*+ a ò sì ní gbà á lọ́wọ́ rẹ̀.”
Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé
^ Tàbí “gbá ẹnikẹ́ni mọ́ra láti kí i.”
^ Ní Grk., “aṣọ àpò ìdọ̀họ.”
^ Tàbí “Hédíìsì,” ìyẹn ibojì aráyé. Wo Àlàyé Ọ̀rọ̀.
^ Wo Àlàyé Ọ̀rọ̀, “Ọkàn.”
^ Wo Àfikún B14.
^ Ní Grk., “ọ̀rọ̀ rẹ̀.”
^ Tàbí “ìpín tó dáa jù.”