Àkọsílẹ̀ Lúùkù 12:1-59
-
Ìwúkàrà àwọn Farisí (1-3)
-
Bẹ̀rù Ọlọ́run, má bẹ̀rù èèyàn (4-7)
-
Fi hàn pé o wà ní ìṣọ̀kan pẹ̀lú Kristi (8-12)
-
Àpèjúwe ọkùnrin ọlọ́rọ̀ kan tó jẹ́ òmùgọ̀ (13-21)
-
Ẹ yéé ṣàníyàn (22-34)
-
Agbo kékeré (32)
-
-
Ṣíṣọ́nà (35-40)
-
Ìríjú olóòótọ́ àti ìríjú aláìṣòótọ́ (41-48)
-
Kì í ṣe àlàáfíà, ìpínyà ni (49-53)
-
Ó yẹ kí wọ́n ṣàyẹ̀wò àkókò (54-56)
-
Yíyanjú ọ̀rọ̀ (57-59)
12 Láàárín àkókò yìí, nígbà tí ẹgbẹẹgbẹ̀rún èèyàn kóra jọ débi pé wọ́n ń tẹ ara wọn mọ́lẹ̀, ó bẹ̀rẹ̀ sí í sọ̀rọ̀, ó kọ́kọ́ sọ fún àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ pé: “Ẹ ṣọ́ra fún ìwúkàrà àwọn Farisí, ìyẹn àgàbàgebè.+
2 Àmọ́ kò sí ohun kan tí a rọra tọ́jú tí a ò ní ṣí payá, kò sì sí ohun tó jẹ́ àṣírí tí a ò ní mọ̀.+
3 Torí náà, ohunkóhun tí ẹ bá sọ nínú òkùnkùn, a máa gbọ́ ọ nínú ìmọ́lẹ̀, ohun tí ẹ bá sì sọ kẹ́lẹ́kẹ́lẹ́ nínú yàrá àdáni, a máa wàásù rẹ̀ látorí ilé.
4 Bákan náà, mò ń sọ fún yín, ẹ̀yin ọ̀rẹ́ mi,+ ẹ má bẹ̀rù àwọn tó ń pa ara, àmọ́ tí wọn ò lè ṣe ohunkóhun mọ́ lẹ́yìn èyí.+
5 Ṣùgbọ́n màá fi ẹni tí ẹ máa bẹ̀rù hàn yín: Ẹ bẹ̀rù Ẹni tó jẹ́ pé lẹ́yìn tó bá pani, ó ní àṣẹ láti sọni sínú Gẹ̀hẹ́nà.*+ Àní, mò ń sọ fún yín, Ẹni yìí ni kí ẹ bẹ̀rù.+
6 Ẹyọ owó méjì tí kò fi bẹ́ẹ̀ níye lórí* ni wọ́n ń ta ológoṣẹ́ márùn-ún, àbí bẹ́ẹ̀ kọ́? Síbẹ̀, Ọlọ́run ò gbàgbé* ìkankan nínú wọn.+
7 Kódà, gbogbo irun orí yín la ti kà.+ Ẹ má bẹ̀rù; ẹ níye lórí gan-an ju ọ̀pọ̀ ológoṣẹ́ lọ.+
8 “Mò ń sọ fún yín pé, gbogbo ẹni tó bá fi hàn pé òun mọ̀ mí níwájú àwọn èèyàn,+ Ọmọ èèyàn náà máa fi hàn pé òun mọ̀ ọ́n níwájú àwọn áńgẹ́lì Ọlọ́run.+
9 Àmọ́ ẹnikẹ́ni tó bá sẹ́ mi níwájú àwọn èèyàn, a máa sẹ́ ẹ níwájú àwọn áńgẹ́lì Ọlọ́run.+
10 Gbogbo ẹni tó bá sọ̀rọ̀ òdì sí Ọmọ èèyàn, a máa dárí rẹ̀ jì í, àmọ́ ẹnikẹ́ni tó bá sọ̀rọ̀ òdì sí ẹ̀mí mímọ́ kò ní rí ìdáríjì.+
11 Tí wọ́n bá mú yín wọlé síwájú ibi táwọn èèyàn pé jọ sí,* síwájú àwọn aṣojú ìjọba àti àwọn aláṣẹ, ẹ má ṣàníyàn nípa bí ẹ ṣe máa sọ̀rọ̀ tàbí ọ̀rọ̀ tí ẹ máa fi gbèjà ara yín tàbí ohun tí ẹ máa sọ,+
12 torí ní wákàtí yẹn gan-an, ẹ̀mí mímọ́ máa kọ́ yín ní àwọn ohun tó yẹ kí ẹ sọ.”+
13 Ẹnì kan láàárín èrò wá sọ fún un pé: “Olùkọ́, sọ fún arákùnrin mi kó pín ogún fún mi.”
14 Ó sọ fún un pé: “Ọkùnrin yìí, ta ló yàn mí ṣe adájọ́ tàbí alárinà láàárín ẹ̀yin méjèèjì?”
15 Ó wá sọ fún wọn pé: “Ẹ la ojú yín sílẹ̀, kí ẹ sì máa ṣọ́ra fún onírúurú ojúkòkòrò,*+ torí pé tí ẹnì kan bá tiẹ̀ ní nǹkan rẹpẹtẹ, àwọn ohun tó ní kò lè fún un ní ìwàláàyè.”+
16 Torí náà, ó sọ àpèjúwe kan fún wọn, ó ní: “Ilẹ̀ ọkùnrin ọlọ́rọ̀ kan méso jáde dáadáa.
17 Ó wá bẹ̀rẹ̀ sí í rò ó lọ́kàn ara rẹ̀ pé, ‘Kí ni kí n ṣe báyìí tí mi ò ní ibì kankan tí màá kó irè oko mi jọ sí?’
18 Torí náà, ó sọ pé, ‘Ohun tí màá ṣe nìyí:+ Màá ya àwọn ilé ìkẹ́rùsí mi lulẹ̀, màá sì kọ́ àwọn tó tóbi, ibẹ̀ ni màá kó gbogbo ọkà mi àti gbogbo ẹrù mi jọ sí,
19 màá sì sọ fún ara* mi pé: “O ní* ọ̀pọ̀ nǹkan rere tí mo ti tò jọ fún ọ̀pọ̀ ọdún; fọkàn balẹ̀, máa jẹ, máa mu, máa gbádùn ara ẹ.”’
20 Àmọ́ Ọlọ́run sọ fún un pé, ‘Aláìlóye, òru òní ni wọ́n máa béèrè ẹ̀mí* rẹ lọ́wọ́ rẹ. Ta ló máa wá ni àwọn ohun tí o ti tò jọ?’+
21 Bẹ́ẹ̀ ló máa rí fún ẹni tó bá ń to ìṣúra jọ fún ara rẹ̀ àmọ́ tí kò ní ọrọ̀ lọ́dọ̀ Ọlọ́run.”+
22 Ó wá sọ fún àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ pé: “Ìdí nìyẹn tí mo fi ń sọ fún yín pé, ẹ yéé ṣàníyàn nípa ẹ̀mí* yín, ní ti ohun tí ẹ máa jẹ tàbí nípa ara yín, ní ti ohun tí ẹ máa wọ̀.+
23 Torí ẹ̀mí* níye lórí ju oúnjẹ lọ, ara sì níye lórí ju aṣọ lọ.
24 Ẹ wo àwọn ẹyẹ ìwò: Wọn kì í fúnrúgbìn, wọn kì í sì í kárúgbìn; wọn ò ní abà tàbí ilé ìkẹ́rùsí; síbẹ̀ Ọlọ́run ń bọ́ wọn.+ Ṣé ẹ ò wá níye lórí gan-an ju àwọn ẹyẹ lọ ni?+
25 Èwo nínú yín ló lè fi ìgbọ̀nwọ́* kan kún ìwàláàyè rẹ̀, tó bá ń ṣàníyàn?
26 Torí náà, tí ẹ ò bá lè ṣe ohun tó kéré bí èyí, kí ló wá dé tí ẹ̀ ń ṣàníyàn nípa àwọn ohun tó ṣẹ́ kù?+
27 Ẹ ronú nípa bí àwọn òdòdó lílì ṣe ń dàgbà: Wọn kì í ṣe làálàá, wọn kì í sì í rànwú;* àmọ́ mò ń sọ fún yín pé, a ò ṣe Sólómọ́nì pàápàá lọ́ṣọ̀ọ́ nínú gbogbo ògo rẹ̀ bí ọ̀kan lára àwọn yìí.+
28 Tó bá jẹ́ pé báyìí ni Ọlọ́run ṣe ń wọ ewéko inú pápá láṣọ, tó wà lónìí, tí a sì jù sínú ààrò lọ́la, ṣé kò wá ní wọ̀ yín láṣọ jù bẹ́ẹ̀ lọ, ẹ̀yin tí ìgbàgbọ́ yín kéré?
29 Torí náà, ẹ yéé wá ohun tí ẹ máa jẹ àti ohun tí ẹ máa mu, ẹ má sì jẹ́ kí àníyàn kó yín lọ́kàn sókè mọ́;+
30 torí gbogbo nǹkan yìí ni àwọn orílẹ̀-èdè ayé ń wá lójú méjèèjì, àmọ́ Baba yín mọ̀ pé ẹ nílò àwọn nǹkan yìí.+
31 Kàkà bẹ́ẹ̀, ẹ máa wá Ìjọba rẹ̀, a sì máa fi àwọn nǹkan yìí kún un fún yín.+
32 “Má bẹ̀rù, agbo kékeré,+ torí Baba yín ti fọwọ́ sí i láti fún yín ní Ìjọba náà.+
33 Ẹ ta àwọn ohun ìní yín, kí ẹ sì ṣe ìtọrẹ àánú.*+ Ẹ ṣe àwọn àpò owó tí kì í gbó, ìṣúra tí kò lè kùnà láé sí ọ̀run,+ níbi tí olè kankan kò lè sún mọ́, tí òólá* kankan ò sì lè jẹ ẹ́ run.
34 Torí ibi tí ìṣúra yín bá wà, ibẹ̀ ni ọkàn yín náà máa wà.
35 “Ẹ múra, kí ẹ sì wà ní sẹpẹ́,*+ kí ẹ jẹ́ kí àwọn fìtílà yín máa jó,+
36 kí ẹ sì dà bí àwọn ọkùnrin tó ń dúró de ọ̀gá wọn pé kó pa dà dé+ láti ibi ìgbéyàwó,+ kó lè jẹ́ pé tó bá dé, tó sì kan ilẹ̀kùn, ẹsẹ̀kẹsẹ̀ ni wọ́n á ṣílẹ̀kùn fún un.
37 Aláyọ̀ ni àwọn ẹrú tí ọ̀gá náà rí i pé wọ́n ń ṣọ́nà nígbà tó dé! Lóòótọ́ ni mo sọ fún yín, ó máa múra* láti ṣiṣẹ́, á sì ní kí wọ́n jókòó* sídìí tábìlì, ó máa wá sí tòsí, á sì ṣe ìránṣẹ́ fún wọn.
38 Tó bá sì dé ní ìṣọ́ kejì,* kódà kó jẹ́ ìkẹta,* tó sì rí i pé wọ́n wà ní sẹpẹ́, aláyọ̀ ni wọ́n!
39 Ṣùgbọ́n ẹ mọ èyí, ká ní baálé ilé mọ wákàtí tí olè máa wá ni, kò ní jẹ́ kí wọ́n ráyè wọ ilé òun.+
40 Ẹ̀yin náà, ẹ múra sílẹ̀, torí pé wákàtí tí ẹ ò rò pé ó lè jẹ́ ni Ọmọ èèyàn ń bọ̀.”+
41 Pétérù wá sọ pé: “Olúwa, ṣé àwa nìkan lò ń sọ àpèjúwe yìí fún àbí gbogbo èèyàn?”
42 Olúwa sọ pé: “Ní tòótọ́, ta ni ìríjú olóòótọ́* náà, tó jẹ́ olóye,* tí ọ̀gá rẹ̀ máa yàn pé kó bójú tó àwọn ìránṣẹ́* rẹ̀, kó máa fún wọn ní ìwọ̀n oúnjẹ wọn ní àkókò tó yẹ?+
43 Aláyọ̀ ni ẹrú yẹn tí ọ̀gá rẹ̀ bá dé, tó sì rí i tó ń ṣe bẹ́ẹ̀!
44 Mò ń sọ fún yín ní tòótọ́, ó máa yàn án pé kó máa bójú tó gbogbo ohun ìní rẹ̀.
45 Àmọ́ tí ẹrú yẹn bá lọ sọ nínú ọkàn rẹ̀ pé, ‘Ọ̀gá mi ò tètè dé,’ tó wá bẹ̀rẹ̀ sí í lu àwọn ìránṣẹ́kùnrin àti ìránṣẹ́bìnrin, tó ń jẹ, tó ń mu, tó sì mutí yó,+
46 ọ̀gá ẹrú yẹn máa dé ní ọjọ́ tí kò retí rẹ̀ àti wákàtí tí kò mọ̀, ó máa fi ìyà tó le jù lọ jẹ ẹ́, ó sì máa kà á mọ́ àwọn aláìṣòótọ́.
47 Nígbà náà, ẹrú yẹn tó lóye ohun tí ọ̀gá rẹ̀ fẹ́ àmọ́ tí kò múra sílẹ̀, tí kò sì ṣe ohun tó ní kó ṣe* la máa nà ní ẹgba tó pọ̀.+
48 Àmọ́ èyí tí kò lóye, síbẹ̀ tó ṣe àwọn ohun tó fi yẹ kó jẹgba la máa nà ní ẹgba díẹ̀. Ní tòótọ́, gbogbo ẹni tí a bá fún ní púpọ̀, a máa béèrè púpọ̀ lọ́wọ́ rẹ̀, ẹni tí a bá sì yàn pé kó máa bójú tó ohun púpọ̀, ohun tó pọ̀ ju ti tẹ́lẹ̀ la máa béèrè lọ́wọ́ rẹ̀.+
49 “Mo wá láti dá iná kan ní ayé, kí ni mo tún fẹ́ tó bá jẹ́ pé a ti dá iná náà báyìí?
50 Ní tòótọ́, mo ní ìbatisí kan tí a fi máa batisí mi, ẹ sì wo bí ìdààmú tó bá mi ṣe pọ̀ tó títí ó fi máa parí!+
51 Ṣé ẹ rò pé mo wá láti mú kí àlàáfíà wà ní ayé ni? Rárá o, mò ń sọ fún yín pé, dípò ìyẹn, ìpínyà ni.+
52 Torí láti ìsinsìnyí lọ, ẹni márùn-ún máa pínyà nínú ilé kan, ẹni mẹ́ta sí méjì àti ẹni méjì sí mẹ́ta.
53 Wọ́n máa pínyà, bàbá sí ọmọkùnrin àti ọmọkùnrin sí bàbá, ìyá sí ọmọbìnrin àti ọmọbìnrin sí ìyá, ìyá ọkọ sí ìyàwó ọmọ rẹ̀ àti ìyàwó sí ìyá ọkọ rẹ̀.”+
54 Lẹ́yìn náà, ó tún sọ fún àwọn èrò náà pé: “Tí ẹ bá rí i tí ojú ọ̀run ṣú ní ìwọ̀ oòrùn, kíá lẹ máa sọ pé, ‘Ìjì ń bọ̀,’ ó sì máa ń rí bẹ́ẹ̀.
55 Tí ẹ bá sì rí i pé atẹ́gùn ń fẹ́ láti gúúsù, ẹ máa sọ pé, ‘Ooru máa mú,’ ó sì máa ń ṣẹlẹ̀ bẹ́ẹ̀.
56 Ẹ̀yin alágàbàgebè, ẹ mọ bí wọ́n ṣe ń ṣàyẹ̀wò bí ayé àti òfúrufú ṣe rí, àmọ́ kí nìdí tí ẹ ò fi mọ bí ẹ ṣe máa ṣàyẹ̀wò àkókò yìí gan-an?+
57 Kí ló dé tí ẹ̀yin fúnra yín náà ò pinnu ohun tó jẹ́ òdodo?
58 Bí àpẹẹrẹ, tí ìwọ àti ẹni tó fẹ̀sùn kàn ọ́ lábẹ́ òfin bá ń lọ sọ́dọ̀ alákòóso kan, sapá láti yanjú ọ̀rọ̀ náà pẹ̀lú rẹ̀ lójú ọ̀nà, kó má bàa mú ọ wá síwájú adájọ́, kí adájọ́ wá fi ọ́ lé òṣìṣẹ́ ilé ẹjọ́ lọ́wọ́, kí òṣìṣẹ́ ilé ẹjọ́ sì jù ọ́ sẹ́wọ̀n.+
59 Mò ń sọ fún ọ pé, ó dájú pé o ò ní kúrò níbẹ̀ títí wàá fi san ẹyọ owó kékeré tó kù* tí o jẹ́.”
Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé
^ Wo Àlàyé Ọ̀rọ̀.
^ Ní Grk., “Ásáríò méjì.” Wo Àfikún B14.
^ Tàbí “gbójú fo.”
^ Tàbí “síwájú àwọn sínágọ́gù.”
^ Tàbí “wọ̀bìà.”
^ Tàbí “ọkàn.”
^ Tàbí “Ọkàn, o ní.”
^ Tàbí “ọkàn.”
^ Tàbí “ọkàn.”
^ Tàbí “ọkàn.”
^ Wo Àfikún B14.
^ Tàbí “ṣe òwú.”
^ Tàbí “ìtọrẹ fún àwọn aláìní.” Wo Àlàyé Ọ̀rọ̀.
^ Tàbí “kòkòrò.”
^ Ní Grk., “Ẹ di abẹ́nú yín lámùrè.”
^ Tàbí “dira rẹ̀ lámùrè.”
^ Tàbí “rọ̀gbọ̀kú.”
^ Láti nǹkan bí aago mẹ́sàn-án alẹ́ sí ọ̀gànjọ́ òru.
^ Láti ọ̀gànjọ́ òru sí nǹkan bí aago mẹ́ta àárọ̀.
^ Tàbí “alábòójútó ilé.”
^ Tàbí “ọlọ́gbọ́n.”
^ Tàbí “àwọn ìránṣẹ́ ilé.”
^ Tàbí “ṣe ìfẹ́ rẹ̀.”
^ Ní Grk., “lẹ́pítónì tó kù.” Wo Àfikún B14.