Àkọsílẹ̀ Lúùkù 19:1-48

  • Jésù lọ sọ́dọ̀ Sákéù (1-10)

  • Àpèjúwe mínà mẹ́wàá (11-27)

  • Jésù gun kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ wọnú ìlú (28-40)

  • Jésù sunkún lórí Jerúsálẹ́mù (41-44)

  • Jésù fọ tẹ́ńpìlì mọ́ (45-48)

19  Lẹ́yìn náà, ó wọ Jẹ́ríkò, ó sì ń kọjá lọ.  Ọkùnrin kan tó ń jẹ́ Sákéù wà níbẹ̀; olórí àwọn agbowó orí ni, ó sì jẹ́ ọlọ́rọ̀.  Ó gbìyànjú láti rí ẹni tó ń jẹ́ Jésù yìí, àmọ́ èrò tó wà níbẹ̀ ò jẹ́ kó lè rí i, torí èèyàn kúkúrú ni.  Ló bá sáré lọ síwájú, ó sì gun igi síkámórè* kó lè rí i, torí ọ̀nà yẹn ló fẹ́ gbà kọjá.  Nígbà tí Jésù dé ibẹ̀, ó wòkè, ó sì sọ fún un pé: “Sákéù, tètè sọ̀ kalẹ̀, torí mo gbọ́dọ̀ dé sí ilé rẹ lónìí.”  Ló bá yára sọ̀ kalẹ̀, ó sì gbà á lálejò tayọ̀tayọ̀.  Nígbà tí wọ́n rí èyí, gbogbo wọn ń kùn pé: “Ọ̀dọ̀ ọkùnrin tó jẹ́ ẹlẹ́ṣẹ̀ ló lọ dé sí.”+  Àmọ́ Sákéù dìde dúró, ó sì sọ fún Olúwa pé: “Wò ó! Olúwa, ìdajì àwọn ohun ìní mi ni màá fún àwọn aláìní, ohunkóhun tí mo bá sì fipá gbà* lọ́wọ́ ẹnikẹ́ni ni màá dá pa dà ní ìlọ́po mẹ́rin.”+  Jésù wá sọ fún un pé: “Lónìí, ìgbàlà ti wọnú ilé yìí, torí pé ọmọ Ábúráhámù ni òun náà. 10  Torí Ọmọ èèyàn wá, kó lè wá ohun tó sọ nù, kó sì gbà á là.”+ 11  Bí wọ́n ṣe ń fetí sí àwọn nǹkan yìí, ó sọ àpèjúwe míì torí ó ti sún mọ́ Jerúsálẹ́mù, wọ́n sì rò pé Ìjọba Ọlọ́run máa fara hàn lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀.+ 12  Torí náà, ó sọ pé: “Ọkùnrin kan tí wọ́n bí ní ilé ọlá rìnrìn àjò lọ sí ilẹ̀ kan tó jìnnà+ kó lè lọ gba agbára láti jọba, kó sì pa dà. 13  Ó pe mẹ́wàá lára àwọn ẹrú rẹ̀, ó fún wọn ní mínà* mẹ́wàá, ó sì sọ fún wọn pé, ‘Ẹ máa fi ṣòwò títí màá fi dé.’+ 14  Àmọ́ àwọn aráàlú rẹ̀ kórìíra rẹ̀, wọ́n sì rán àwọn ikọ̀ tẹ̀ lé e, kí wọ́n sọ pé, ‘A ò fẹ́ kí ọkùnrin yìí jọba lé wa lórí.’ 15  “Nígbà tó pa dà dé lẹ́yìn tó gba agbára láti jọba,* ó pe àwọn ẹrú tó fún ní owó* náà, kó lè mọ èrè tí wọ́n jẹ nínú òwò tí wọ́n ṣe.+ 16  Èyí àkọ́kọ́ wá bá a, ó sọ pé, ‘Olúwa, mo fi mínà rẹ jèrè mínà mẹ́wàá.’+ 17  Ó sọ fún un pé, ‘O káre láé, ẹrú rere! Torí o ti fi hàn pé o jẹ́ olóòótọ́ nínú ohun tó kéré gan-an, jẹ́ aláṣẹ lórí ìlú mẹ́wàá.’+ 18  Ìkejì wá dé, ó sọ pé, ‘Olúwa, mo fi mínà rẹ jèrè mínà márùn-ún.’+ 19  Ó sọ fún ẹni yìí náà pé, ‘Ìwọ náà, máa bójú tó ìlú márùn-ún.’ 20  Àmọ́ ẹrú míì dé, ó sì sọ pé, ‘Olúwa, mínà rẹ rèé tí mo fi pa mọ́ sínú aṣọ. 21  Ṣó o rí i, ẹ̀rù rẹ ló bà mí, torí pé èèyàn tó le ni ọ́; ohun tó ò fi sílẹ̀ lo máa ń gbà, ohun tó ò sì gbìn lo máa ń ká.’+ 22  Ó sọ fún un pé, ‘Ẹrú burúkú, ọ̀rọ̀ ẹnu rẹ ni mo fi dá ọ lẹ́jọ́. O mọ̀, àbí, pé èèyàn tó le ni mí, ohun tí mi ò fi sílẹ̀ ni mò ń gbà, ohun tí mi ò sì gbìn ni mò ń ká?+ 23  Kí ló dé tó ò fi owó* mi sí báǹkì? Tí n bá sì dé, ǹ bá gbà á pẹ̀lú èlé.’ 24  “Ló bá sọ fún àwọn tó dúró nítòsí pé, ‘Ẹ gba mínà náà lọ́wọ́ rẹ̀, kí ẹ sì fún ẹni tó ní mínà mẹ́wàá.’+ 25  Àmọ́ wọ́n sọ fún un pé, ‘Olúwa, mínà mẹ́wàá ló ní!’— 26  ‘Mò ń sọ fún yín, gbogbo ẹni tó bá ní, a máa fi kún èyí tó ní, àmọ́ ẹni tí kò bá ní, a máa gba èyí tó ní pàápàá lọ́wọ́ rẹ̀.+ 27  Bákan náà, ẹ mú àwọn ọ̀tá mi yìí wá síbí, àwọn tí ò fẹ́ kí n jọba lórí wọn, kí ẹ sì pa wọ́n níwájú mi.’” 28  Lẹ́yìn tó sọ àwọn nǹkan yìí, ó ń bá ìrìn àjò rẹ̀ lọ, ó ń gòkè lọ sí Jerúsálẹ́mù. 29  Nígbà tó sún mọ́ Bẹtifágè àti Bẹ́tánì, ní òkè tí wọ́n ń pè ní Òkè Ólífì,+ ó rán méjì lára àwọn ọmọ ẹ̀yìn jáde,+ 30  ó sọ pé: “Ẹ lọ sínú abúlé ọ̀ọ́kán yìí, tí ẹ bá sì ti wọ ibẹ̀, ẹ máa rí ọmọ kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́* kan tí wọ́n so, èyí tí èèyàn kankan ò jókòó lé rí. Ẹ tú u, kí ẹ sì mú un wá síbí. 31  Àmọ́ tí ẹnikẹ́ni bá bi yín pé, ‘Kí ló dé tí ẹ fi ń tú u?’ kí ẹ sọ pé, ‘Olúwa fẹ́ lò ó.’” 32  Torí náà, àwọn tó rán níṣẹ́ lọ, wọ́n sì rí i bó ṣe sọ fún wọn gẹ́lẹ́.+ 33  Àmọ́ bí wọ́n ṣe ń tú ọmọ kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ náà, àwọn tó ni ín sọ fún wọn pé: “Kí ló dé tí ẹ fi ń tú ọmọ kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ yẹn?” 34  Wọ́n sọ pé: “Olúwa fẹ́ lò ó.” 35  Wọ́n wá mú un lọ sọ́dọ̀ Jésù, wọ́n ju aṣọ àwọ̀lékè wọn sórí ọmọ kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ náà, wọ́n sì mú kí Jésù jókòó sórí rẹ̀.+ 36  Bó ṣe ń lọ, wọ́n ń tẹ́ aṣọ àwọ̀lékè wọn sí ojú ọ̀nà.+ 37  Gbàrà tó dé tòsí ojú ọ̀nà tó lọ sísàlẹ̀ láti Òkè Ólífì, inú gbogbo àwọn ọmọ ẹ̀yìn tí wọ́n pọ̀ rẹpẹtẹ bẹ̀rẹ̀ sí í dùn, wọ́n sì gbóhùn sókè, wọ́n ń yin Ọlọ́run torí gbogbo iṣẹ́ agbára tí wọ́n ti rí, 38  wọ́n ń sọ pé: “Ìbùkún ni fún ẹni tó ń bọ̀ bí Ọba ní orúkọ Jèhófà!* Àlàáfíà ní ọ̀run àti ògo ní ibi gíga lókè!”+ 39  Àmọ́ àwọn kan nínú àwọn Farisí tó wà láàárín èrò sọ fún un pé: “Olùkọ́, bá àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ wí.”+ 40  Àmọ́ ó fún wọn lésì pé: “Mò ń sọ fún yín, tí àwọn yìí bá dákẹ́, àwọn òkúta máa ké jáde.” 41  Nígbà tó dé tòsí, ó wo ìlú náà, ó sì sunkún lé e lórí,+ 42  ó ní: “Ká sọ pé ìwọ, àní ìwọ, ti fòye mọ àwọn ohun tó jẹ mọ́ àlàáfíà ní ọjọ́ yìí ni, àmọ́ a ti fi wọ́n pa mọ́ kúrò ní ojú rẹ báyìí.+ 43  Torí pé àwọn ọjọ́ máa dé bá ọ, tí àwọn ọ̀tá rẹ máa fi àwọn igi olórí ṣóńṣó ṣe odi yí ọ po, wọ́n máa yí ọ ká, wọ́n á sì dó tì ọ́* yí ká.+ 44  Wọ́n máa fọ́ ìwọ àti àwọn ọmọ rẹ tó wà nínú rẹ mọ́lẹ̀,+ wọn ò sì ní fi òkúta kan sílẹ̀ lórí òkúta kan nínú rẹ,+ torí pé o ò fi òye mọ àkókò tí a máa bẹ̀ ọ́ wò.” 45  Ó wá wọnú tẹ́ńpìlì, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí í lé àwọn tó ń tajà síta,+ 46  ó ń sọ fún wọn pé: “A ti kọ ọ́ pé, ‘A ó máa pe ilé mi ní ilé àdúrà,’+ àmọ́ ẹ ti sọ ọ́ di ihò àwọn olè.”+ 47  Ó ń kọ́ni lójoojúmọ́ nínú tẹ́ńpìlì. Síbẹ̀, àwọn olórí àlùfáà àti àwọn akọ̀wé òfin àti àwọn ẹni pàtàkì láàárín àwọn èèyàn ń wá bí wọ́n ṣe máa pa á;+ 48  àmọ́ wọn ò rí ọ̀nà kankan tí wọ́n lè gbà ṣe é, torí ṣe ni gbogbo èèyàn ń rọ̀ mọ́ ọn ṣáá kí wọ́n lè gbọ́ ọ̀rọ̀ rẹ̀.+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé

Tàbí “igi ọ̀pọ̀tọ́ mọ́líbẹ́rì.”
Tàbí “fipá gbà lórí ẹ̀sùn èké.”
Mínà kan nílẹ̀ Gíríìsì jẹ́ 340 gíráàmù, wọ́n sì gbà pé ó tó 100 dírákímà. Wo Àfikún B14.
Tàbí “agbára ìjọba.”
Ní Grk., “owó fàdákà.”
Ní Grk., “fàdákà.”
Tàbí “agódóńgbó.”
Tàbí “kó wàhálà bá ọ.”