Àkọsílẹ̀ Lúùkù 21:1-38
21 Bó ṣe gbójú sókè, ó rí i tí àwọn ọlọ́rọ̀ ń fi ẹ̀bùn wọn sínú àwọn àpótí ìṣúra.+
2 Ó wá rí opó aláìní kan tó fi ẹyọ owó kéékèèké méjì tí ìníyelórí rẹ̀ kéré gan-an* síbẹ̀,+
3 ó sì sọ pé: “Lóòótọ́ ni mo sọ fún yín pé ohun tí opó aláìní yìí fi sílẹ̀ ju ti gbogbo wọn lọ.+
4 Torí gbogbo àwọn yìí fi ẹ̀bùn sílẹ̀ látinú àjẹṣẹ́kù wọn, àmọ́ òun, láìka pé kò ní lọ́wọ́,* ó fi gbogbo ohun tó ní láti gbé ẹ̀mí rẹ̀ ró síbẹ̀.”+
5 Lẹ́yìn náà, nígbà tí àwọn kan ń sọ̀rọ̀ nípa tẹ́ńpìlì, bí wọ́n ṣe fi òkúta tó rẹwà àti àwọn ohun tí a yà sí mímọ́ ṣe é lọ́ṣọ̀ọ́,+
6 ó sọ pé: “Ní ti àwọn nǹkan yìí tí ẹ̀ ń rí báyìí, ọjọ́ ń bọ̀ tí wọn ò ní fi òkúta kan sílẹ̀ lórí òkúta míì láìwó o palẹ̀.”+
7 Wọ́n wá bi í pé: “Olùkọ́, ìgbà wo gan-an ni àwọn nǹkan yìí máa ṣẹlẹ̀, kí ló sì máa jẹ́ àmì ìgbà tí àwọn nǹkan yìí máa ṣẹlẹ̀?”+
8 Ó sọ pé: “Ẹ ṣọ́ra kí wọ́n má bàa ṣì yín lọ́nà;+ torí ọ̀pọ̀ èèyàn máa wá ní orúkọ mi, wọ́n á sọ pé, ‘Èmi ni ẹni náà’ àti pé, ‘Àkókò náà ti sún mọ́lé.’ Ẹ má tẹ̀ lé wọn.+
9 Bákan náà, tí ẹ bá gbọ́ nípa ogun àti rògbòdìyàn,* ẹ má bẹ̀rù. Torí àwọn nǹkan yìí gbọ́dọ̀ kọ́kọ́ ṣẹlẹ̀, àmọ́ ẹsẹ̀kẹsẹ̀ kọ́ ni òpin máa dé.”+
10 Ó wá sọ fún wọn pé: “Orílẹ̀-èdè máa dìde sí orílẹ̀-èdè+ àti ìjọba sí ìjọba.+
11 Ìmìtìtì ilẹ̀ tó lágbára máa wáyé, àìtó oúnjẹ àti àjàkálẹ̀ àrùn sì máa wà láti ibì kan dé ibòmíì;+ ẹ máa rí àwọn ohun tó ń bani lẹ́rù, àwọn àmì tó lágbára sì máa wà láti ọ̀run.
12 “Àmọ́ kí gbogbo àwọn nǹkan yìí tó ṣẹlẹ̀, àwọn èèyàn máa gbé ọwọ́ wọn lé yín, wọ́n á sì ṣe inúnibíni sí yín,+ wọ́n á fà yín lé àwọn sínágọ́gù lọ́wọ́, wọ́n á sì fi yín sẹ́wọ̀n. Wọ́n máa mú yín lọ síwájú àwọn ọba àti àwọn gómìnà nítorí orúkọ mi.+
13 Èyí máa jẹ́ kí ẹ lè jẹ́rìí.
14 Torí náà, ẹ pinnu lọ́kàn yín pé ẹ ò ní fi bí ẹ ṣe máa gbèjà ara yín dánra wò ṣáájú,+
15 torí màá fún yín ní àwọn ọ̀rọ̀ àti ọgbọ́n tí gbogbo àwọn alátakò yín lápapọ̀ ò ní lè ta kò tàbí kí wọ́n jiyàn rẹ̀.+
16 Bákan náà, àwọn òbí, àwọn arákùnrin, àwọn mọ̀lẹ́bí àti àwọn ọ̀rẹ́ pàápàá máa fà yín léni lọ́wọ́,* wọ́n máa pa àwọn kan nínú yín,+
17 gbogbo èèyàn sì máa kórìíra yín nítorí orúkọ mi.+
18 Àmọ́ ìkankan nínú irun orí yín pàápàá kò ní ṣègbé.+
19 Tí ẹ bá ní ìfaradà, ẹ máa lè pa ẹ̀mí yín mọ́.*+
20 “Àmọ́, tí ẹ bá rí i tí àwọn ọmọ ogun pàgọ́ yí Jerúsálẹ́mù ká,+ nígbà náà, kí ẹ mọ̀ pé àkókò tó máa dahoro ti sún mọ́lé.+
21 Kí àwọn tó wà ní Jùdíà bẹ̀rẹ̀ sí í sá lọ sí àwọn òkè,+ kí àwọn tó wà nínú ìlú náà kúrò níbẹ̀, kí àwọn tó sì wà ní ìgbèríko má wọ ibẹ̀,
22 torí pé àwọn ọjọ́ yìí la máa ṣe ìdájọ́,* kí gbogbo ohun tí a kọ lè ṣẹ.
23 Ó mà ṣe o, fún àwọn aláboyún àti àwọn tó ń tọ́ ọmọ jòjòló ní àwọn ọjọ́ yẹn o!+ Torí wàhálà ńlá máa bá ilẹ̀ náà, ìbínú sì máa wá sórí àwọn èèyàn yìí.
24 Wọ́n máa fi ojú idà ṣá wọn balẹ̀, wọ́n á sì kó wọn lẹ́rú lọ sí gbogbo orílẹ̀-èdè;+ àwọn orílẹ̀-èdè* sì máa tẹ Jerúsálẹ́mù mọ́lẹ̀, títí àkókò tí a yàn fún àwọn orílẹ̀-èdè* fi máa pé.+
25 “Bákan náà, àwọn àmì máa wà nínú oòrùn, òṣùpá àti àwọn ìràwọ̀,+ ìdààmú sì máa bá àwọn orílẹ̀-èdè ní ayé, wọn ò ní mọ ọ̀nà àbáyọ torí ariwo omi òkun àti bó ṣe ń ru gùdù.
26 Àwọn èèyàn máa kú sára nítorí ìbẹ̀rù àti àwọn ohun tí wọ́n ń retí pé ó máa ṣẹlẹ̀ ní ilẹ̀ ayé tí à ń gbé, torí a máa mi àwọn agbára ọ̀run.
27 Nígbà náà, wọ́n á rí Ọmọ èèyàn+ tó ń bọ̀ nínú àwọsánmà* pẹ̀lú agbára àti ògo ńlá.+
28 Àmọ́ tí àwọn nǹkan yìí bá ti bẹ̀rẹ̀ sí í ṣẹlẹ̀, ẹ nàró ṣánṣán, kí ẹ sì gbé orí yín sókè, torí ìdáǹdè yín ń sún mọ́lé.”
29 Ó wá sọ àpèjúwe kan fún wọn pé: “Ẹ kíyè sí igi ọ̀pọ̀tọ́ àti gbogbo igi yòókù.+
30 Tí wọ́n bá ti ń rúwé, ẹ máa rí i fúnra yín, ẹ sì máa mọ̀ pé ìgbà ẹ̀ẹ̀rùn ti sún mọ́lé nìyẹn.
31 Bákan náà, tí ẹ bá rí i tí àwọn nǹkan yìí ń ṣẹlẹ̀, kí ẹ mọ̀ pé Ìjọba Ọlọ́run ti sún mọ́lé.
32 Lóòótọ́ ni mo sọ fún yín pé, ó dájú pé ìran yìí ò ní kọjá lọ títí gbogbo nǹkan fi máa ṣẹlẹ̀.+
33 Ọ̀run àti ayé máa kọjá lọ, àmọ́ ó dájú pé àwọn ọ̀rọ̀ mi ò ní kọjá lọ.+
34 “Àmọ́ ẹ kíyè sí ara yín, kí àjẹjù, ọtí àmujù + àti àníyàn ìgbésí ayé má bàa di ẹrù pa ọkàn yín,+ láìròtẹ́lẹ̀ kí ọjọ́ yẹn sì dé bá yín lójijì
35 bí ìdẹkùn.+ Torí ó máa dé bá gbogbo àwọn tó ń gbé ní gbogbo ayé.
36 Torí náà, ẹ máa wà lójúfò,+ kí ẹ máa rawọ́ ẹ̀bẹ̀ nígbà gbogbo,+ kí ẹ lè bọ́ nínú gbogbo nǹkan tó gbọ́dọ̀ ṣẹlẹ̀ yìí, kí ẹ sì lè dúró níwájú Ọmọ èèyàn.”+
37 Torí náà, ní ọ̀sán, ó máa ń kọ́ni nínú tẹ́ńpìlì, àmọ́ ní òru, ó máa ń lọ dé sí òkè tí wọ́n ń pè ní Òkè Ólífì.
38 Gbogbo èèyàn sì máa ń wá sọ́dọ̀ rẹ̀ ní àárọ̀ kùtù kí wọ́n lè gbọ́ ọ̀rọ̀ rẹ̀ nínú tẹ́ńpìlì.
Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé
^ Ní Grk., “lẹ́pítónì méjì.” Wo Àfikún B14.
^ Tàbí “pé ó jẹ́ òtòṣì.”
^ Tàbí “rúkèrúdò; ìdàrúdàpọ̀.”
^ Tàbí “máa dà yín.”
^ Tàbí “jèrè ọkàn yín.”
^ Tàbí “máa jẹ́ ọjọ́ ẹ̀san.”
^ Tàbí “àwọn Kèfèrí.”
^ Tàbí “àwọn Kèfèrí.”
^ Tàbí “ìkùukùu.”