Àkọsílẹ̀ Lúùkù 7:1-50
7 Nígbà tó parí gbogbo ọ̀rọ̀ tó fẹ́ bá àwọn èèyàn náà sọ, ó wọ Kápánáúmù.
2 Ẹrú ọ̀gágun kan, tí ọ̀gá rẹ̀ fẹ́ràn gan-an ń ṣàìsàn gidigidi, ó sì ti fẹ́rẹ̀ẹ́ kú.+
3 Nígbà tí ọ̀gágun náà gbọ́ nípa Jésù, ó rán àwọn kan lára àwọn àgbààgbà àwọn Júù sí i, kí wọ́n sọ fún un pé kó wá, kó lè mú ẹrú òun lára dá.
4 Wọ́n wá bá Jésù, wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí í bẹ̀ ẹ́ taratara, wọ́n ní: “Ó yẹ lẹ́ni tí o lè ṣe é fún,
5 torí ó nífẹ̀ẹ́ orílẹ̀-èdè wa, òun ló sì kọ́ sínágọ́gù wa.”
6 Torí náà, Jésù tẹ̀ lé wọn. Àmọ́ nígbà tó sún mọ́ ilé ọ̀gágun náà, ọ̀gágun náà ti rán àwọn ọ̀rẹ́ pé kí wọ́n sọ fún un pé: “Ọ̀gá, má ṣèyọnu, torí mi ò yẹ lẹ́ni tí o lè wá sábẹ́ òrùlé rẹ̀.+
7 Ìdí nìyẹn tí mi ò fi ka ara mi sí ẹni tó yẹ láti wá sọ́dọ̀ rẹ. Àmọ́, sọ̀rọ̀, kí o sì jẹ́ kí ara ìránṣẹ́ mi yá.
8 Torí èmi náà wà lábẹ́ àṣẹ, mo sì ní àwọn ọmọ ogun tó wà lábẹ́ àṣẹ mi, tí mo bá sọ fún eléyìí pé, ‘Lọ!’ á lọ, tí mo bá sọ fún ẹlòmíì pé, ‘Wá!’ á wá, tí mo bá sì sọ fún ẹrú mi pé, ‘Ṣe báyìí!’ á ṣe é.”
9 Nígbà tí Jésù gbọ́ àwọn nǹkan yìí, ọ̀rọ̀ ọkùnrin náà yà á lẹ́nu, ó wá yíjú sí àwọn èrò tó ń tẹ̀ lé e, ó sì sọ pé: “Mò ń sọ fún yín pé, mi ò tíì rí ẹnì kankan ní Ísírẹ́lì pàápàá tó ní ìgbàgbọ́ tó lágbára tó báyìí.”+
10 Nígbà tí àwọn tí ọkùnrin náà rán wá pa dà sílé, wọ́n rí i pé ara ẹrú náà ti yá.+
11 Kò pẹ́ lẹ́yìn ìyẹn, ó rìnrìn àjò lọ sí ìlú kan tó ń jẹ́ Náínì, àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ àti èrò rẹpẹtẹ sì ń bá a rìnrìn àjò.
12 Bó ṣe sún mọ́ ẹnubodè ìlú náà, wò ó! wọ́n ń gbé òkú ọkùnrin kan jáde, òun nìkan ṣoṣo ni ìyá rẹ̀ bí.*+ Yàtọ̀ síyẹn, opó ni obìnrin náà. Èrò rẹpẹtẹ tún tẹ̀ lé e látinú ìlú náà.
13 Nígbà tí Olúwa tajú kán rí i, àánú rẹ̀ ṣe é,+ ó sì sọ fún un pé: “Má sunkún mọ́.”+
14 Ló bá sún mọ́ wọn, ó fọwọ́ kan àga ìgbókùú* náà, àwọn tó gbé e sì dúró. Ó wá sọ pé: “Ọ̀dọ́kùnrin, mo sọ fún ọ, dìde!”+
15 Ọkùnrin tó ti kú náà wá dìde jókòó, ó bẹ̀rẹ̀ sí í sọ̀rọ̀, Jésù sì fà á lé ìyá rẹ̀ lọ́wọ́.+
16 Ẹ̀rù ba gbogbo wọn, wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí í yin Ọlọ́run lógo, wọ́n ní: “A ti gbé wòlíì ńlá kan dìde láàárín wa”+ àti pé, “Ọlọ́run ti yíjú sí àwọn èèyàn rẹ̀.”+
17 Ìròyìn yìí nípa rẹ̀ sì tàn káàkiri gbogbo Jùdíà àti gbogbo ìgbèríko tó wà ní àyíká.
18 Àwọn ọmọ ẹ̀yìn Jòhánù wá ròyìn gbogbo nǹkan yìí fún un.+
19 Torí náà, Jòhánù pe méjì nínú àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀, ó sì rán wọn sí Olúwa pé kí wọ́n bi í pé: “Ṣé ìwọ ni Ẹni Tó Ń Bọ̀,+ àbí ká máa retí ẹlòmíì?”
20 Nígbà tí wọ́n dé ọ̀dọ̀ rẹ̀, àwọn ọkùnrin náà sọ pé: “Jòhánù Arinibọmi rán wa sí ọ láti béèrè pé, ‘Ṣé ìwọ ni Ẹni Tó Ń Bọ̀, àbí ká máa retí ẹlòmíì?’”
21 Ní wákàtí yẹn, ó ṣe ìwòsàn fún ọ̀pọ̀ àwọn aláìsàn,+ àwọn tó ní àrùn tó le àti àwọn tó ní ẹ̀mí burúkú, ó sì mú kí ọ̀pọ̀ afọ́jú pa dà ríran.
22 Ó dá wọn lóhùn pé: “Ẹ lọ ròyìn ohun tí ẹ ti rí, tí ẹ sì ti gbọ́ fún Jòhánù: Àwọn afọ́jú ti ń ríran báyìí,+ àwọn arọ ń rìn, à ń wẹ àwọn adẹ́tẹ̀ mọ́, àwọn adití ń gbọ́ràn,+ à ń jí àwọn òkú dìde, a sì ń sọ ìhìn rere fún àwọn aláìní.+
23 Aláyọ̀ ni ẹni tí kò rí ohunkóhun tó máa mú kó kọsẹ̀ nínú mi.”+
24 Nígbà tí àwọn tí Jòhánù rán wá lọ tán, Jésù bẹ̀rẹ̀ sí í sọ fún àwọn èrò náà nípa Jòhánù pé: “Kí lẹ jáde lọ wò ní aginjù? Ṣé esùsú* tí atẹ́gùn ń gbé kiri ni?+
25 Kí wá lẹ jáde lọ wò? Ṣé ọkùnrin tó wọ aṣọ àtàtà* ni?+ Ṣebí inú ilé àwọn ọba ni àwọn tó wọ aṣọ tó rẹwà, tí wọ́n sì ń gbé ìgbé ayé gbẹdẹmukẹ máa ń wà?
26 Ká sòótọ́, kí wá lẹ jáde lọ wò? Ṣé wòlíì ni? Àní mo sọ fún yín, ó ju wòlíì lọ dáadáa.+
27 Ẹni yìí la kọ̀wé nípa rẹ̀ pé: ‘Wò ó! Màá rán ìránṣẹ́ mi ṣáájú rẹ,* ẹni tó máa ṣètò ọ̀nà rẹ dè ọ́.’+
28 Mò ń sọ fún yín, nínú àwọn tí obìnrin bí, kò sí ẹni tó tóbi ju Jòhánù lọ, àmọ́ ẹni kékeré nínú Ìjọba Ọlọ́run tóbi jù ú lọ.”+
29 (Nígbà tí gbogbo èèyàn àti àwọn agbowó orí gbọ́ èyí, wọ́n kéde pé olódodo ni Ọlọ́run, torí Jòhánù ti ṣe ìrìbọmi fún wọn.+
30 Àmọ́ àwọn Farisí àti àwọn tó mọ Òfin dunjú kò ka ìmọ̀ràn* tí Ọlọ́run fún wọn sí,+ torí pé kò tíì ṣe ìrìbọmi fún wọn.)
31 “Ta ni màá wá fi àwọn èèyàn ìran yìí wé, ta ni wọ́n sì jọ?+
32 Wọ́n dà bí àwọn ọmọ kéékèèké tí wọ́n jókòó nínú ọjà, tí wọ́n sì ń ké pe ara wọn, tí wọ́n ń sọ pé: ‘A fun fèrè fún yín, àmọ́ ẹ ò jó; a pohùn réré ẹkún, àmọ́ ẹ ò sunkún.’
33 Bákan náà, Jòhánù Arinibọmi wá, kò jẹ búrẹ́dì, kò sì mu wáìnì,+ àmọ́ ẹ sọ pé, ‘Ẹlẹ́mìí èṣù ni.’
34 Ọmọ èèyàn wá, ó ń jẹ, ó sì ń mu, àmọ́ ẹ sọ pé: ‘Wò ó! Ọkùnrin alájẹkì, ti kò mọ̀ ju kó mu wáìnì lọ, ọ̀rẹ́ àwọn agbowó orí àti àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀!’+
35 Síbẹ̀ náà, a fi ọgbọ́n hàn ní olódodo* nípasẹ̀ gbogbo àwọn ọmọ rẹ̀.”*+
36 Ọkàn lára àwọn Farisí ń rọ̀ ọ́ ṣáá pé kó wá bá òun jẹun. Torí náà, ó wọ ilé Farisí náà, ó sì jókòó* sídìí tábìlì.
37 Wò ó! obìnrin kan tí wọ́n mọ̀ sí ẹlẹ́ṣẹ̀ ní ìlú náà gbọ́ pé ó ń jẹun* nínú ilé Farisí náà, ó sì mú orùba* alabásítà tí wọ́n rọ òróró onílọ́fínńdà sí wá.+
38 Ó dúró sẹ́yìn níbi ẹsẹ̀ rẹ̀, ó sunkún, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí í fi omijé rẹ̀ rin ẹsẹ̀ rẹ̀, ó wá ń fi irun orí rẹ̀ nù ún kúrò. Bákan náà, obìnrin náà rọra fi ẹnu ko ẹsẹ̀ rẹ̀, ó sì da òróró onílọ́fínńdà náà sí i.
39 Nígbà tí Farisí tó pè é wá rí èyí, ó sọ lọ́kàn ara rẹ̀ pé: “Tó bá jẹ́ pé wòlíì ni ọkùnrin yìí lóòótọ́, ó máa mọ obìnrin tó ń fọwọ́ kàn án yìí àti irú ẹni tó jẹ́, pé ẹlẹ́ṣẹ̀ ni.”+
40 Àmọ́ Jésù sọ fún un pé: “Símónì, mo fẹ́ sọ nǹkan kan fún ọ.” Ó fèsì pé: “Olùkọ́, sọ ọ́!”
41 “Ọkùnrin méjì jẹ ayánilówó kan ní gbèsè; ọ̀kan jẹ ẹ́ ní ọgọ́rùn-ún márùn-ún (500) owó dínárì,* àmọ́ èkejì jẹ ẹ́ ní àádọ́ta (50).
42 Nígbà tí wọn ò ní ohunkóhun tí wọ́n máa fi san án pa dà fún un, ó dárí ji àwọn méjèèjì pátápátá. Torí náà, èwo nínú wọn ló máa nífẹ̀ẹ́ rẹ̀ jù?”
43 Símónì dá a lóhùn pé: “Mo rò pé ẹni tó dárí púpọ̀ jì ni.” Ó sọ fún un pé: “Bí o ṣe dájọ́ yẹn tọ́.”
44 Ó wá yíjú sí obìnrin náà, ó sì sọ fún Símónì pé: “Ṣé o rí obìnrin yìí? Mo wọ ilé rẹ; o ò fún mi ní omi láti fọ ẹsẹ̀ mi. Àmọ́ obìnrin yìí fi omijé rẹ̀ rin ẹsẹ̀ mi, ó sì fi irun rẹ̀ nù ún kúrò.
45 O ò fẹnu kò mí lẹ́nu, àmọ́ obìnrin yìí, láti wákàtí tí mo ti wọlé, kò yéé rọra fi ẹnu ko ẹsẹ̀ mi.
46 O ò da òróró sí orí mi, àmọ́ obìnrin yìí da òróró onílọ́fínńdà sí ẹsẹ̀ mi.
47 Torí èyí, mò ń sọ fún ọ, bí àwọn ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀ tiẹ̀ pọ̀,* a dárí wọn jì í,+ torí ó ní ìfẹ́ púpọ̀. Àmọ́ ẹni tí a dárí díẹ̀ jì ní ìfẹ́ díẹ̀.”
48 Ó wá sọ fún un pé: “A dárí àwọn ẹ̀ṣẹ̀ rẹ jì ọ́.”+
49 Àwọn tó jókòó sídìí tábìlì pẹ̀lú rẹ̀ bẹ̀rẹ̀ sí í sọ láàárín ara wọn pé: “Ta ni ọkùnrin yìí tó tún lè dárí àwọn ẹ̀ṣẹ̀ jini?”+
50 Àmọ́ ó sọ fún obìnrin náà pé: “Ìgbàgbọ́ rẹ ti gbà ọ́ là;+ máa lọ ní àlàáfíà.”
Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé
^ Ní Grk., “òun ni ọmọ bíbí kan ṣoṣo ìyá rẹ̀.”
^ Tàbí “ibùsùn ìgbókùú.”
^ Ìyẹn, koríko etí omi.
^ Ní Grk., “aṣọ múlọ́múlọ́.”
^ Ní Grk., “síwájú ojú rẹ.”
^ Tàbí “ìtọ́sọ́nà.”
^ Tàbí “a dá ọgbọ́n láre.”
^ Tàbí “àwọn èso rẹ̀.”
^ Tàbí “rọ̀gbọ̀kú.”
^ Tàbí “jókòó nídìí tábìlì.”
^ Tàbí “ìgò.”
^ Wo Àfikún B14.
^ Tàbí “burú jáì.”