Málákì 1:1-14

  • Jèhófà nífẹ̀ẹ́ àwọn èèyàn rẹ̀ (1-5)

  • Àwọn àlùfáà ń fi ẹran tó lábùkù rúbọ (6-14)

    • Wọ́n á gbé orúkọ Ọlọ́run ga láàárín àwọn orílẹ̀-èdè (11)

1  Ìkéde: Ọ̀rọ̀ tí Jèhófà gbẹnu Málákì* sọ fún Ísírẹ́lì nìyí:  Jèhófà sọ pé, “Mo ti fi hàn pé mo nífẹ̀ẹ́ yín.”+ Àmọ́, ẹ sọ pé: “Kí lo ṣe tó fi hàn pé o nífẹ̀ẹ́ wa?” Jèhófà sọ pé, “Ṣebí ọmọ ìyá ni Jékọ́bù àti Ísọ̀?+ Àmọ́ mo nífẹ̀ẹ́ Jékọ́bù,  mo sì kórìíra Ísọ̀;+ mo sọ àwọn òkè rẹ̀ di ahoro,+ màá jẹ́ kí àwọn ajáko* inú aginjù gba ogún rẹ̀.”+  “Bó tilẹ̀ jẹ́ pé Édómù sọ pé, ‘Wọ́n ti fọ́ wa túútúú, àmọ́ a máa pa dà, a ó sì tún àwọn àwókù náà kọ́,’ ohun tí Jèhófà Ọlọ́run àwọn ọmọ ogun sọ nìyí, ‘Wọ́n máa kọ́ ọ; àmọ́ màá ya á lulẹ̀, wọ́n sì máa pè wọ́n ní “ilẹ̀ ìwà burúkú” àti “àwọn èèyàn tí Jèhófà ti ta nù títí láé.”+  Ẹ ó fi ojú yín rí i, ẹ ó sì sọ pé: “Kí wọ́n gbé Jèhófà ga ní ilẹ̀ Ísírẹ́lì.”’”  Èmi Jèhófà Ọlọ́run àwọn ọmọ ogun sọ fún ẹ̀yin àlùfáà tó ń tàbùkù sí orúkọ mi+ pé: “‘Ọmọ máa ń bọlá fún bàbá,+ ìránṣẹ́ sì máa ń bọlá fún ọ̀gá rẹ̀. Torí náà, bí mo bá jẹ́ bàbá,+ ǹjẹ́ kò yẹ kí ẹ bọlá fún mi?+ Bí mo bá sì jẹ́ ọ̀gá,* ǹjẹ́ kò yẹ kí ẹ bẹ̀rù* mi?’ “‘Àmọ́, ẹ sọ pé: “Kí la ṣe tí a fi tàbùkù sí orúkọ rẹ?”’  “‘Ẹ̀ ń fi oúnjẹ* ẹlẹ́gbin rúbọ lórí pẹpẹ mi.’ “‘Ẹ sì sọ pé: “Kí la ṣe tí a fi sọ ẹ́ di ẹlẹ́gbin?”’ “‘Ẹ̀ ń sọ pé: “Tábìlì Jèhófà+ kò wúlò.”  Nígbà tí ẹ bá ń fi ẹran tó fọ́jú rúbọ, ẹ̀ ń sọ pé: “Kò sí ohun tó burú níbẹ̀.” Tí ẹ bá sì ń mú ẹran tó yarọ tàbí èyí tó ń ṣàìsàn wá, ẹ̀ ń sọ pé: “Kò sí ohun tó burú níbẹ̀.”’”+ “Ẹ jọ̀ọ́, ẹ mú un lọ síwájú gómìnà yín. Ṣé inú rẹ̀ á dùn sí yín, ṣé ẹ sì máa rí ojúure rẹ̀?” ni Jèhófà Ọlọ́run àwọn ọmọ ogun wí.  “Ní báyìí, ẹ jọ̀ọ́, ẹ bẹ Ọlọ́run,* kó lè ṣojúure sí wa. Ṣé irú ọrẹ tí ẹ mú wá yẹn lè mú kó ṣojúure sí ẹnikẹ́ni nínú yín?” ni Jèhófà Ọlọ́run àwọn ọmọ ogun wí. 10  “Ta ló fẹ́ ti àwọn ilẹ̀kùn* nínú yín?+ Ẹ kì í fẹ́ dá iná pẹpẹ mi láìjẹ́ pé ẹ gba nǹkan kan.+ Inú mi ò dùn sí yín,” ni Jèhófà Ọlọ́run àwọn ọmọ ogun wí, “inú mi ò sì dùn sí ìkankan nínú ọrẹ tí ẹ mú wá.”+ 11  “Torí láti yíyọ oòrùn dé wíwọ̀ rẹ̀,* wọn yóò gbé orúkọ mi ga láàárín àwọn orílẹ̀-èdè.+ Níbi gbogbo, wọ́n á mú kí ẹbọ rú èéfín, wọ́n á sì mú àwọn ọrẹ wá torí orúkọ mi, bí ẹ̀bùn tó mọ́; torí wọn yóò gbé orúkọ mi ga láàárín àwọn orílẹ̀-èdè,”+ ni Jèhófà Ọlọ́run àwọn ọmọ ogun wí. 12  “Àmọ́ ẹ̀ ń kẹ́gàn rẹ̀,*+ ẹ̀ ń sọ pé, ‘Tábìlì Jèhófà jẹ́ ẹlẹ́gbin, ó sì yẹ ká tẹ́ńbẹ́lú èso àti oúnjẹ rẹ̀.’+ 13  Ẹ tún sọ pé, ‘Ẹ wò ó! Ó ti sú wa o!’ ẹ sì fi í ṣe ẹlẹ́yà,” ni Jèhófà Ọlọ́run àwọn ọmọ ogun wí. “Ẹran tí ẹ jí, èyí tó yarọ àti èyí tó ń ṣàìsàn lẹ̀ ń mú wá. Àní, irú nǹkan bẹ́ẹ̀ lẹ̀ ń fún mi! Ṣé ó yẹ kí n gbà á lọ́wọ́ yín?”+ ni Jèhófà wí. 14  “Ègún ni fún ẹni tó ń ṣe àrékérekè, tó ní akọ ẹran tí ara rẹ̀ dá ṣáṣá nínú agbo ẹran rẹ̀, tó sì wá fi ẹran tó ní àbùkù* rúbọ sí Jèhófà lẹ́yìn tó jẹ́ ẹ̀jẹ́. Torí Ọba tó ju ọba lọ ni mí,”+ ni Jèhófà Ọlọ́run àwọn ọmọ ogun wí, “orúkọ mi yóò sì ba àwọn orílẹ̀-èdè lẹ́rù.”+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé

Ó túmọ̀ sí “Ìránṣẹ́ Mi.”
Tàbí “akátá.”
Tàbí “ọ̀gá àgbà.”
Tàbí “bọ̀wọ̀ fún.”
Ní Héb., “búrẹ́dì.”
Tàbí “tu Ọlọ́run lójú.”
Ó ṣe kedere pé, iṣẹ́ títi àwọn ilẹ̀kùn tẹ́ńpìlì ló ń sọ.
Tàbí “láti ìlà oòrùn dé ìwọ̀ oòrùn.”
Tàbí kó jẹ́, “pẹ̀gàn mi.”
Tàbí “àbààwọ́n.”