Málákì 4:1-6

  • Èlíjà yóò wá kí ọjọ́ Jèhófà tó dé (1-6)

    • “Oòrùn òdodo yóò ràn” (2)

4  “Wò ó! ọjọ́ náà ń bọ̀, ó ń jó bí iná ìléru,+ nígbà tí gbogbo àwọn agbéraga àti gbogbo àwọn tó ń hùwà burúkú yóò dà bí àgékù pòròpórò. Ọjọ́ tó ń bọ̀ náà yóò jẹ wọ́n run,” ni Jèhófà Ọlọ́run àwọn ọmọ ogun wí, “kò sì ní fi gbòǹgbò tàbí ẹ̀ka sílẹ̀ fún wọn.  Àmọ́ oòrùn òdodo yóò ràn sórí ẹ̀yin tó bọlá fún* orúkọ mi, ìtànṣán* rẹ̀ yóò mú yín lára dá; ẹ ó sì máa tọ pọ́n-ún pọ́n-ún kiri bí àwọn ọmọ màlúù tí wọ́n bọ́ sanra.”  Jèhófà Ọlọ́run àwọn ọmọ ogun sọ pé: “Ẹ ó tẹ àwọn ẹni burúkú mọ́lẹ̀, torí wọ́n á dà bí eruku lábẹ́ ẹsẹ̀ yín, ní ọjọ́ tí mo bá ṣe ohun tí mo sọ.”  “Ẹ rántí Òfin Mósè ìránṣẹ́ mi, àwọn ìlànà àti àṣẹ tí mo pa fún gbogbo Ísírẹ́lì ní Hórébù pé kí wọ́n tẹ̀ lé.+  “Wò ó! Èmi yóò rán wòlíì Èlíjà sí yín+ kí ọjọ́ ńlá Jèhófà tó ń bani lẹ́rù tó dé.+  Ó sì máa yí ọkàn àwọn bàbá pa dà sọ́dọ̀ àwọn ọmọ+ àti ọkàn àwọn ọmọ pa dà sọ́dọ̀ àwọn bàbá, kí n má bàa fìyà jẹ ayé, kí n sì pa á run.”

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé

Ní Héb., “bẹ̀rù.”
Ní Héb., “àwọn ìyẹ́.”