Àkọsílẹ̀ Mátíù 13:1-58
-
ÀWỌN ÀPÈJÚWE NÍPA ÌJỌBA NÁÀ (1-52)
-
Afúnrúgbìn (1-9)
-
Ìdí tí Jésù fi lo àwọn àpèjúwe (10-17)
-
Ó sọ ìtumọ̀ àpèjúwe afúnrúgbìn (18-23)
-
Àlìkámà àti èpò (24-30)
-
Hóró músítádì àti ìwúkàrà (31-33)
-
Bó ṣe lo àwọn àpèjúwe mú àsọtẹ́lẹ̀ ṣẹ (34, 35)
-
Ó sọ ìtumọ̀ àpèjúwe àlìkámà àti èpò (36-43)
-
Ìṣúra tó pa mọ́ àti péálì tó dáa (44-46)
-
Àwọ̀n (47-50)
-
Ìṣúra tuntun àti ti àtijọ́ (51, 52)
-
-
Wọn ò gba Jésù ní agbègbè ìlú rẹ̀ (53-58)
13 Lọ́jọ́ yẹn, Jésù kúrò nínú ilé, ó sì jókòó sétí òkun.
2 Ọ̀pọ̀lọpọ̀ èèyàn kóra jọ sọ́dọ̀ rẹ̀ débi pé ó wọ ọkọ̀ ojú omi, ó jókòó, gbogbo àwọn èrò náà sì dúró sí etíkun.+
3 Ó wá fi àpèjúwe sọ ọ̀pọ̀lọpọ̀ nǹkan fún wọn,+ ó ní: “Ẹ wò ó! Afúnrúgbìn kan jáde lọ fún irúgbìn.+
4 Bó ṣe ń fún irúgbìn, díẹ̀ já bọ́ sí etí ọ̀nà, àwọn ẹyẹ wá, wọ́n sì ṣà á jẹ.+
5 Àwọn míì já bọ́ sórí ilẹ̀ àpáta tí kò fi bẹ́ẹ̀ sí iyẹ̀pẹ̀, wọ́n sì hù lójú ẹsẹ̀ torí pé iyẹ̀pẹ̀ náà ò jìn.+
6 Àmọ́ nígbà tí oòrùn ràn, ó jó wọn gbẹ, wọ́n sì rọ torí pé wọn ò ní gbòǹgbò.
7 Àwọn míì já bọ́ sáàárín ẹ̀gún, àwọn ẹ̀gún náà yọ, wọ́n sì fún wọn pa.+
8 Síbẹ̀ àwọn míì já bọ́ sórí iyẹ̀pẹ̀ tó dáa, wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí í so èso, eléyìí so ní ìlọ́po ọgọ́rùn-ún (100), ìyẹn ọgọ́ta (60), òmíràn ọgbọ̀n (30).+
9 Kí ẹni tó bá ní etí fetí sílẹ̀.”+
10 Àwọn ọmọ ẹ̀yìn wá bá a, wọ́n sì sọ fún un pé: “Kí ló dé tí ò ń fi àpèjúwe bá wọn sọ̀rọ̀?”+
11 Ó sọ fún wọn pé: “Ẹ̀yin la yọ̀ǹda fún pé kí ẹ lóye àwọn àṣírí mímọ́+ Ìjọba ọ̀run, àmọ́ a ò yọ̀ǹda fún wọn.
12 Torí ẹnikẹ́ni tó bá ní, a máa fi kún ohun tó ní, a sì máa mú kó ní púpọ̀; àmọ́ ẹnikẹ́ni tí kò bá ní, a máa gba ohun tó ní pàápàá kúrò lọ́wọ́ rẹ̀.+
13 Ìdí nìyẹn tí mo fi ń fi àpèjúwe bá wọn sọ̀rọ̀; torí ní ti bí wọ́n ṣe ń wò, lásán ni wọ́n ń wò, ní ti bí wọ́n ṣe ń gbọ́, lásán ni wọ́n ń gbọ́, kò sì yé wọn.+
14 Àsọtẹ́lẹ̀ Àìsáyà sì ṣẹ sí wọn lára. Ó sọ pé: ‘Ó dájú pé ẹ máa gbọ́, àmọ́ kò ní yé yín rárá, ó sì dájú pé ẹ máa wò, àmọ́ ẹ ò ní ríran rárá.+
15 Torí ọkàn àwọn èèyàn yìí ti yigbì, wọ́n sì ti fi etí wọn gbọ́, àmọ́ wọn ò dáhùn, wọ́n ti di ojú wọn, kí wọ́n má bàa fi ojú wọn ríran láé, kí wọ́n má sì fi etí wọn gbọ́, kó má sì yé wọn nínú ọkàn wọn, kí wọ́n lè yí pa dà, kí n sì mú wọn lára dá.’+
16 “Àmọ́, aláyọ̀ ni ojú yín torí wọ́n rí àti etí yín torí wọ́n gbọ́.+
17 Lóòótọ́ ni mo sọ fún yín pé, ó wu ọ̀pọ̀ àwọn wòlíì àti àwọn olódodo pé kí wọ́n rí àwọn ohun tí ẹ̀ ń rí, àmọ́ wọn ò rí i,+ ó wù wọ́n kí wọ́n gbọ́ àwọn ohun tí ẹ̀ ń gbọ́, àmọ́ wọn ò gbọ́ ọ.
18 “Ní báyìí, ẹ fetí sí àpèjúwe ọkùnrin tó fún irúgbìn.+
19 Tí ẹnikẹ́ni bá gbọ́ ọ̀rọ̀ Ìjọba náà, àmọ́ tí kò yé e, ẹni burúkú náà+ á wá, á sì já ohun tí a gbìn sínú ọkàn rẹ̀ gbà lọ; èyí ni irúgbìn tó bọ́ sí etí ọ̀nà.+
20 Ní ti èyí tó bọ́ sórí ilẹ̀ àpáta, òun ló ń gbọ́ ọ̀rọ̀ náà, tó sì fi ayọ̀ tẹ́wọ́ gbà á lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀.+
21 Síbẹ̀, kò ta gbòǹgbò nínú rẹ̀, àmọ́ ó ń bá a lọ fúngbà díẹ̀, lẹ́yìn tí ìpọ́njú tàbí inúnibíni sì dé nítorí ọ̀rọ̀ náà, ẹsẹ̀kẹsẹ̀ ni a mú un kọsẹ̀.
22 Ní ti èyí tó bọ́ sáàárín àwọn ẹ̀gún, òun ló ń gbọ́ ọ̀rọ̀ náà, àmọ́ tí àníyàn ètò àwọn nǹkan yìí*+ àti agbára ìtannijẹ ọrọ̀ fún ọ̀rọ̀ náà pa, kò sì so èso.+
23 Ní ti èyí tó bọ́ sórí iyẹ̀pẹ̀ tó dáa, òun ló ń gbọ́ ọ̀rọ̀ náà, tó sì ń yé e, tó so èso lóòótọ́, tó sì ń mú èso jáde, eléyìí so ní ìlọ́po ọgọ́rùn-ún (100), ìyẹn ọgọ́ta (60), òmíràn ọgbọ̀n (30).”+
24 Ó sọ àpèjúwe míì fún wọn, ó ní: “A lè fi Ìjọba ọ̀run wé ọkùnrin kan tó fún irúgbìn tó dáa sínú pápá rẹ̀.
25 Nígbà tí àwọn èèyàn ń sùn, ọ̀tá rẹ̀ wá, ó gbin èpò sí àárín àlìkámà* náà, ó sì lọ.
26 Nígbà tí ohun ọ̀gbìn náà hù, tó sì so èso, àwọn èpò náà fara hàn.
27 Àwọn ẹrú baálé ilé náà wá, wọ́n sì sọ fún un pé, ‘Ọ̀gá, ṣebí irúgbìn tó dáa lo gbìn sínú pápá rẹ? Báwo ló ṣe wá ní èpò?’
28 Ó sọ fún wọn pé, ‘Ọkùnrin kan tó jẹ́ ọ̀tá ló ṣe èyí.’+ Àwọn ẹrú náà sọ fún un pé, ‘Ṣé o fẹ́ ká lọ kó wọn jọ ni?’
29 Ó sọ pé, ‘Rárá, torí kí ẹ má bàa hú àlìkámà pẹ̀lú èpò nígbà tí ẹ bá ń kó èpò jọ.
30 Ẹ jẹ́ kí méjèèjì jọ dàgbà títí dìgbà ìkórè, tó bá wá dìgbà ìkórè, màá sọ fún àwọn tó ń kórè pé: Ẹ kọ́kọ́ kó àwọn èpò jọ, kí ẹ sì dì wọ́n ní ìdìpọ̀-ìdìpọ̀ láti sun wọ́n; kí ẹ wá kó àlìkámà jọ sínú ilé ìkẹ́rùsí mi.’”+
31 Ó sọ àpèjúwe míì fún wọn, ó ní: “Ìjọba ọ̀run dà bíi hóró músítádì kan, tí ọkùnrin kan mú, tó sì gbìn sínú pápá rẹ̀.+
32 Ní tòótọ́, òun ló rí tín-ń-tín jù lọ nínú gbogbo irúgbìn, àmọ́ tó bá ti dàgbà, òun ló máa ń tóbi jù lọ nínú àwọn ọ̀gbìn oko, á sì di igi, débi pé àwọn ẹyẹ ojú ọ̀run á wá máa gbé láàárín àwọn ẹ̀ka rẹ̀.”
33 Ó sọ àpèjúwe míì fún wọn, ó ní: “Ìjọba ọ̀run dà bí ìwúkàrà, èyí tí obìnrin kan mú, tó sì pò mọ́ ìyẹ̀fun tó kún òṣùwọ̀n ńlá mẹ́ta, títí gbogbo rẹ̀ fi wú.”+
34 Gbogbo nǹkan yìí ni Jésù fi àpèjúwe sọ fún àwọn èrò náà. Ní tòótọ́, kì í bá wọn sọ̀rọ̀ láìlo àpèjúwe,+
35 kí ohun tí a sọ nípasẹ̀ wòlíì lè ṣẹ, ẹni tó sọ pé: “Màá la ẹnu mi láti sọ àpèjúwe; màá kéde àwọn ohun tó pa mọ́ láti ìbẹ̀rẹ̀.”*+
36 Lẹ́yìn tó ní kí àwọn èrò náà máa lọ, ó wọnú ilé. Àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ wá bá a, wọ́n sì sọ pé: “Ṣàlàyé àpèjúwe àwọn èpò inú pápá fún wa.”
37 Ó dá wọn lóhùn pé: “Ọmọ èèyàn ni ẹni tó fún irúgbìn tó dáa;
38 ayé ni pápá náà.+ Ní ti irúgbìn tó dáa, àwọn yìí ni àwọn ọmọ Ìjọba náà, àmọ́ àwọn ọmọ ẹni burúkú náà ni èpò,+
39 Èṣù sì ni ọ̀tá tó gbìn wọ́n. Ìparí ètò àwọn nǹkan* ni ìgbà ìkórè, àwọn áńgẹ́lì sì ni olùkórè.
40 Torí náà, bí a ṣe kó àwọn èpò jọ, tí a sì dáná sun wọ́n, bẹ́ẹ̀ ló ṣe máa rí ní ìparí ètò àwọn nǹkan.*+
41 Ọmọ èèyàn máa rán àwọn áńgẹ́lì rẹ̀, wọ́n sì máa kó gbogbo ohun tó ń fa ìkọ̀sẹ̀ àti àwọn arúfin jáde kúrò nínú Ìjọba rẹ̀,
42 wọ́n sì máa jù wọ́n sínú iná ìléru.+ Ibẹ̀ ni wọ́n á ti máa sunkún, tí wọ́n á sì ti máa payín keke.
43 Ní àkókò yẹn, àwọn olódodo máa tàn yòò bí oòrùn+ nínú Ìjọba Baba wọn. Kí ẹni tó bá ní etí fetí sílẹ̀.
44 “Ìjọba ọ̀run dà bí ìṣúra tí a fi pa mọ́ sínú pápá, èyí tí ọkùnrin kan rí, tó sì fi pa mọ́; torí pé inú rẹ̀ ń dùn, ó lọ ta gbogbo ohun tó ní, ó sì ra pápá yẹn.+
45 “Ìjọba ọ̀run tún dà bí oníṣòwò kan tó ń rìnrìn àjò, tó ń wá àwọn péálì tó dáa.
46 Nígbà tó rí péálì kan tó níye lórí gan-an, ó lọ, ó sì yára ta gbogbo ohun tó ní, ó sì rà á.+
47 “Ìjọba ọ̀run tún dà bí àwọ̀n ńlá kan, tí wọ́n jù sínú òkun, tó sì kó oríṣiríṣi ẹja.
48 Nígbà tó kún, wọ́n fà á gòkè sí etíkun, wọ́n wá jókòó, wọ́n kó àwọn tó dáa+ sínú àwọn ohun èlò, àmọ́ wọ́n da èyí tí kò dáa+ nù.
49 Bó ṣe máa rí ní ìparí ètò àwọn nǹkan* nìyẹn. Àwọn áńgẹ́lì máa jáde lọ, wọ́n á ya àwọn ẹni burúkú sọ́tọ̀ kúrò lára àwọn olódodo,
50 wọ́n sì máa jù wọ́n sínú iná ìléru. Ibẹ̀ ni wọ́n á ti máa sunkún, tí wọ́n á sì ti máa payín keke.
51 “Ṣé gbogbo nǹkan yìí yé yín?” Wọ́n sọ fún un pé: “Bẹ́ẹ̀ ni.”
52 Ó wá sọ fún wọn pé: “Tó bá rí bẹ́ẹ̀, gbogbo ẹni tó ń kọ́ni ní gbangba, tí a kọ́ nípa Ìjọba ọ̀run, dà bí ọkùnrin kan tó jẹ́ baálé ilé, tó kó àwọn ohun tuntun àti ohun àtijọ́ jáde látinú ibi tó ń kó ìṣúra sí.”
53 Nígbà tí Jésù sọ àwọn àpèjúwe yìí tán, ó kúrò níbẹ̀.
54 Lẹ́yìn tó dé agbègbè ìlú rẹ̀,+ ó bẹ̀rẹ̀ sí í kọ́ wọn nínú sínágọ́gù wọn, débi pé ó yà wọ́n lẹ́nu, wọ́n sì sọ pé: “Ibo ni ọkùnrin yìí ti rí ọgbọ́n yìí àti àwọn iṣẹ́ agbára yìí?+
55 Àbí ọmọ káfíńtà kọ́ nìyí?+ Ṣebí Màríà lorúkọ ìyá rẹ̀, Jémíìsì, Jósẹ́fù, Símónì àti Júdásì sì ni àwọn arákùnrin rẹ̀?+
56 Ṣebí gbogbo àwọn arábìnrin rẹ̀ ló wà pẹ̀lú wa? Ibo ló ti wá rí gbogbo èyí?”+
57 Torí náà, wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí í kọsẹ̀ nítorí rẹ̀.+ Ṣùgbọ́n Jésù sọ fún wọn pé: “Wòlíì máa ń níyì, àmọ́ kì í gbayì ní ìlú rẹ̀ àti ní ilé òun fúnra rẹ̀.”+
58 Kò sì ṣe ọ̀pọ̀ iṣẹ́ agbára níbẹ̀ torí pé wọn ò nígbàgbọ́.
Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé
^ Tàbí “àsìkò yìí.” Wo Àlàyé Ọ̀rọ̀.
^ Tàbí “wíìtì.”
^ Tàbí kó jẹ́, “láti ìgbà tí a ti fi ìpìlẹ̀ ayé sọlẹ̀.”
^ Tàbí “àsìkò kan.” Wo Àlàyé Ọ̀rọ̀.
^ Tàbí “àsìkò náà.” Wo Àlàyé Ọ̀rọ̀.
^ Tàbí “àsìkò náà.” Wo Àlàyé Ọ̀rọ̀.