Àkọsílẹ̀ Mátíù 17:1-27
17 Ọjọ́ mẹ́fà lẹ́yìn náà, Jésù mú Pétérù, Jémíìsì àti Jòhánù arákùnrin rẹ̀ dání lọ sí orí òkè kan tó ga fíofío láwọn nìkan.+
2 A sì yí i pa dà di ológo níwájú wọn; ojú rẹ̀ tàn bí oòrùn, aṣọ àwọ̀lékè rẹ̀ sì tàn yòò* bí ìmọ́lẹ̀.+
3 Wò ó! Mósè àti Èlíjà fara hàn wọ́n níbẹ̀, wọ́n ń bá a sọ̀rọ̀.
4 Pétérù wá sọ fún Jésù pé: “Olúwa, ó dáa bí a ṣe wà níbí. Tí o bá fẹ́, màá pa àgọ́ mẹ́ta síbí, ọ̀kan fún ọ, ọ̀kan fún Mósè àti ọ̀kan fún Èlíjà.”
5 Bí wọ́n ṣe ń sọ̀rọ̀ lọ́wọ́, wò ó! ìkùukùu* tó mọ́lẹ̀ yòò ṣíji bò wọ́n, sì wò ó! ohùn kan dún látinú ìkùukùu náà pé: “Èyí ni Ọmọ mi, àyànfẹ́, ẹni tí mo ti tẹ́wọ́ gbà.+ Ẹ fetí sí i.”+
6 Nígbà tí wọ́n gbọ́ èyí, àwọn ọmọ ẹ̀yìn náà dojú bolẹ̀, ẹ̀rù sì bà wọ́n gidigidi.
7 Jésù wá sún mọ́ wọn, ó fọwọ́ kàn wọ́n, ó sì sọ pé: “Ẹ dìde. Ẹ má bẹ̀rù.”
8 Nígbà tí wọ́n gbójú sókè, wọn ò rí ẹnì kankan àfi Jésù nìkan.
9 Bí wọ́n ṣe ń sọ̀ kalẹ̀ látorí òkè náà, Jésù pàṣẹ fún wọn pé: “Ẹ má sọ ìran náà fún ẹnikẹ́ni títí a fi máa jí Ọmọ èèyàn dìde.”+
10 Àmọ́ àwọn ọmọ ẹ̀yìn bi í pé: “Kí ló wá dé tí àwọn akọ̀wé òfin fi ń sọ pé Èlíjà gbọ́dọ̀ kọ́kọ́ wá?”+
11 Ó fèsì pé: “Èlíjà ń bọ̀ lóòótọ́, ó sì máa mú kí gbogbo nǹkan pa dà sí bó ṣe yẹ.+
12 Àmọ́ mò ń sọ fún yín pé Èlíjà ti wá, wọn ò sì dá a mọ̀, àmọ́ wọ́n ṣe ohun tó wù wọ́n sí i.+ Lọ́nà kan náà, Ọmọ èèyàn máa jìyà lọ́wọ́ wọn.”+
13 Ìgbà yẹn ni àwọn ọmọ ẹ̀yìn fòye mọ̀ pé ọ̀rọ̀ Jòhánù Arinibọmi ló ń bá àwọn sọ.
14 Nígbà tí wọ́n dé ọ̀dọ̀ àwọn èrò,+ ọkùnrin kan wá bá a, ó kúnlẹ̀ fún un, ó sì sọ pé:
15 “Olúwa, ṣàánú ọmọkùnrin mi, torí ó ní wárápá, ara rẹ̀ ò sì yá. Ó máa ń ṣubú sínú iná àti sínú omi lọ́pọ̀ ìgbà.+
16 Mo mú un wá sọ́dọ̀ àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ, àmọ́ wọn ò lè wò ó sàn.”
17 Jésù fèsì pé: “Ìran aláìnígbàgbọ́ àti oníbékebèke,+ títí dìgbà wo ni màá fi wà pẹ̀lú yín? Títí dìgbà wo ni màá fi máa fara dà á fún yín? Ẹ mú un wá sọ́dọ̀ mi níbí.”
18 Jésù wá bá ẹ̀mí èṣù náà wí, ó sì jáde kúrò nínú ọmọkùnrin náà, ara ọmọ náà sì yá láti wákàtí yẹn.+
19 Àwọn ọmọ ẹ̀yìn wá bá Jésù lóun nìkan, wọ́n sì sọ pé: “Kí ló dé tí a ò fi lè lé e jáde?”
20 Ó sọ fún wọn pé: “Torí ìgbàgbọ́ yín kéré ni. Lóòótọ́ ni mo sọ fún yín, tí ẹ bá ní ìgbàgbọ́ tó rí bíi hóró músítádì, ẹ máa sọ fún òkè yìí pé, ‘Kúrò níbí lọ sí ọ̀hún,’ ó sì máa lọ, kò sì sí ohun tí ẹ ò ní lè ṣe.”+
21 * ——
22 Ìgbà tí wọ́n kóra jọ sí Gálílì ni Jésù sọ fún wọn pé: “A máa fi Ọmọ èèyàn lé àwọn èèyàn lọ́wọ́,+
23 wọ́n máa pa á, a sì máa jí i dìde ní ọjọ́ kẹta.”+ Inú wọn sì bà jẹ́ gidigidi.
24 Lẹ́yìn tí wọ́n dé Kápánáúmù, àwọn ọkùnrin tó ń gba dírákímà méjì* fún owó orí wá bá Pétérù, wọ́n sì sọ pé: “Ṣé olùkọ́ yín kì í san dírákímà méjì fún owó orí ni?”+
25 Ó sọ pé: “Bẹ́ẹ̀ ni.” Àmọ́ nígbà tó wọnú ilé, Jésù ṣáájú rẹ̀ sọ̀rọ̀, ó bi í pé: “Kí lèrò rẹ, Símónì? Ọwọ́ ta ni àwọn ọba ayé ti ń gba owó ibodè tàbí owó orí? Ṣé ọwọ́ àwọn ọmọ wọn ni àbí ọwọ́ àwọn àjèjì?”
26 Nígbà tó sọ pé: “Ọwọ́ àwọn àjèjì ni,” Jésù sọ fún un pé: “Tó bá rí bẹ́ẹ̀, á jẹ́ pé àwọn ọmọ kì í san owó orí.
27 Àmọ́ ká má bàa mú wọn kọsẹ̀,+ lọ sí òkun, ju ìwọ̀ ẹja kan, kí o sì mú ẹja tó bá kọ́kọ́ jáde, tí o bá la ẹnu rẹ̀, wàá rí ẹyọ owó fàdákà kan.* Mú un, kí o sì fún wọn, kó jẹ́ tèmi àti tìrẹ.”
Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé
^ Tàbí “funfun.”
^ Tàbí “àwọsánmà.”
^ Ní Grk., “dírákímà méjì alápapọ̀.” Wo Àfikún B14.
^ Ní Grk., “ẹyọ owó sítátà kan,” òun ni wọ́n kà sí dírákímà mẹ́rin alápapọ̀. Wo Àfikún B14.