Àkọsílẹ̀ Mátíù 23:1-39
23 Jésù wá bá àwọn èrò náà àti àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ sọ̀rọ̀, ó ní:
2 “Àwọn akọ̀wé òfin àti àwọn Farisí ti fi ara wọn sí orí ìjókòó Mósè.
3 Torí náà, gbogbo ohun tí wọ́n bá sọ fún yín ni kí ẹ ṣe, kí ẹ sì máa pa mọ́, àmọ́ ẹ má ṣe ohun tí wọ́n ń ṣe, torí tí wọ́n bá sọ̀rọ̀, wọn kì í ṣe ohun tí wọ́n sọ.+
4 Wọ́n ń di àwọn ẹrù tó wúwo, wọ́n sì ń gbé e sí èjìká àwọn èèyàn,+ àmọ́ àwọn fúnra wọn ò ṣe tán láti fi ìka wọn sún un.+
5 Torí kí àwọn èèyàn lè rí wọn ni wọ́n ṣe ń ṣe gbogbo ohun tí wọ́n ń ṣe,+ wọ́n fẹ àwọn akóló tí wọ́n ń kó ìwé mímọ́ sí, èyí tí wọ́n ń dè mọ́ra láti dáàbò bo ara wọn,*+ wọ́n sì mú kí wajawaja etí aṣọ wọn gùn.+
6 Wọ́n fẹ́ràn ibi tó lọ́lá jù níbi oúnjẹ alẹ́ àti ìjókòó iwájú* nínú àwọn sínágọ́gù,+
7 wọ́n fẹ́ràn kí wọ́n máa kí wọn níbi ọjà, kí àwọn èèyàn sì máa pè wọ́n ní Rábì.*
8 Àmọ́ ní tiyín, kí wọ́n má pè yín ní Rábì, torí Olùkọ́+ kan lẹ ní, arákùnrin sì ni gbogbo yín.
9 Bákan náà, ẹ má pe ẹnikẹ́ni ní baba yín ní ayé, torí Baba+ kan lẹ ní, Ẹni tó wà ní ọ̀run.
10 Kí wọ́n má sì pè yín ní aṣáájú, torí Aṣáájú kan lẹ ní, Kristi.
11 Àmọ́ kí ẹni tó tóbi jù lọ láàárín yín jẹ́ ìránṣẹ́ yín.+
12 Ẹnikẹ́ni tó bá gbé ara rẹ̀ ga, a máa rẹ̀ ẹ́ sílẹ̀,+ ẹnikẹ́ni tó bá sì rẹ ara rẹ̀ sílẹ̀, a máa gbé e ga.+
13 “Ẹ gbé, ẹ̀yin akọ̀wé òfin àti Farisí, ẹ̀yin alágàbàgebè! torí pé ẹ ti Ìjọba ọ̀run pa mọ́ àwọn èèyàn; ẹ̀yin fúnra yín ò wọlé, ẹ ò sì jẹ́ kí àwọn tó fẹ́ wọlé ráyè wọlé.+
14 * ——
15 “Ẹ gbé, ẹ̀yin akọ̀wé òfin àti Farisí, ẹ̀yin alágàbàgebè!+ torí pé ẹ̀ ń rìnrìn àjò gba orí òkun àti ilẹ̀ láti sọ ẹnì kan di aláwọ̀ṣe,* tó bá sì ti dà bẹ́ẹ̀, ẹ máa sọ ọ́ di ẹni tí Gẹ̀hẹ́nà* tọ́ sí ní ìlọ́po méjì jù yín lọ.
16 “Ẹ gbé, ẹ̀yin afọ́jú tó ń fini mọ̀nà,+ tó ń sọ pé, ‘Tí ẹnikẹ́ni bá fi tẹ́ńpìlì búra, kò ṣe nǹkan kan; àmọ́ tí ẹnikẹ́ni bá fi wúrà tẹ́ńpìlì búra, dandan ni kó ṣe ohun tó búra.’+
17 Ẹ̀yin òmùgọ̀ àti afọ́jú! Ní tòótọ́, èwo ló tóbi jù, ṣé wúrà ni àbí tẹ́ńpìlì tó sọ wúrà di mímọ́?
18 Bákan náà, ‘Tí ẹnikẹ́ni bá fi pẹpẹ búra, kò ṣe nǹkan kan; àmọ́ tí ẹnikẹ́ni bá fi ẹ̀bùn tó wà lórí rẹ̀ búra, dandan ni kó ṣe ohun tó búra.’
19 Ẹ̀yin afọ́jú! Èwo ló tóbi jù ní tòótọ́, ṣé ẹ̀bùn ni àbí pẹpẹ tó sọ ẹ̀bùn di mímọ́?
20 Torí náà, ẹnikẹ́ni tó bá fi pẹpẹ búra ń fi pẹpẹ náà àti gbogbo ohun tó wà lórí rẹ̀ búra;
21 ẹnikẹ́ni tó bá sì fi tẹ́ńpìlì búra ń fi tẹ́ńpìlì náà àti Ẹni tó ń gbé inú rẹ̀ búra;+
22 ẹnikẹ́ni tó bá sì fi ọ̀run búra ń fi ìtẹ́ Ọlọ́run àti Ẹni tó jókòó sórí rẹ̀ búra.
23 “Ẹ gbé, ẹ̀yin akọ̀wé òfin àti Farisí, ẹ̀yin alágàbàgebè! torí pé ẹ̀ ń san ìdá mẹ́wàá ewéko míńtì, dílì àti kúmínì,+ àmọ́ ẹ ò ka àwọn ọ̀rọ̀ tó ṣe pàtàkì jù nínú Òfin sí, ìyẹn ìdájọ́ òdodo,+ àánú+ àti òtítọ́. Ó yẹ kí ẹ ṣe àwọn nǹkan yìí, àmọ́ kò yẹ kí ẹ ṣàìka àwọn nǹkan yòókù sí.+
24 Ẹ̀yin afọ́jú tó ń fini mọ̀nà,+ tó ń sẹ́ kòkòrò tín-tìn-tín,*+ àmọ́ tó ń gbé ràkúnmí mì káló!+
25 “Ẹ gbé, ẹ̀yin akọ̀wé òfin àti Farisí, ẹ̀yin alágàbàgebè! torí pé ẹ̀ ń fọ ẹ̀yìn ife àti abọ́ mọ́,+ àmọ́ wọ̀bìà*+ àti ìkẹ́rabàjẹ́ kún inú wọn.+
26 Farisí afọ́jú, kọ́kọ́ fọ inú ife àti abọ́ mọ́, kí ẹ̀yìn rẹ̀ náà lè mọ́.
27 “Ẹ gbé, ẹ̀yin akọ̀wé òfin àti Farisí, ẹ̀yin alágàbàgebè! + torí pé ẹ dà bí àwọn sàréè tí wọ́n kùn lẹ́fun,+ tí wọ́n rẹwà níta lóòótọ́, àmọ́ tó jẹ́ pé àwọn egungun òkú èèyàn àti onírúurú ohun àìmọ́ ló kún inú wọn.
28 Bẹ́ẹ̀ náà lẹ ṣe jẹ́ olódodo lójú àwọn èèyàn, àmọ́ ìwà àgàbàgebè kún inú yín, ẹ sì jẹ́ arúfin.+
29 “Ẹ gbé, ẹ̀yin akọ̀wé òfin àti Farisí, ẹ̀yin alágàbàgebè!+ torí pé ẹ̀ ń kọ́ sàréè àwọn wòlíì, ẹ sì ń ṣe ibojì* àwọn olódodo lọ́ṣọ̀ọ́,+
30 ẹ sì sọ pé, ‘Ká ní a wà láyé nígbà ayé àwọn baba ńlá wa ni, a ò ní lọ́wọ́ sí bí wọ́n ṣe ta ẹ̀jẹ̀ àwọn wòlíì sílẹ̀.’
31 Torí náà, ẹ̀ ń jẹ́rìí ta ko ara yín pé ọmọ àwọn tó pa àwọn wòlíì ni yín.+
32 Tó bá rí bẹ́ẹ̀, ẹ mú kí òṣùwọ̀n àwọn baba ńlá yín kún.
33 “Ẹ̀yin ejò, ọmọ paramọ́lẹ̀,+ báwo lẹ ṣe máa bọ́ nínú ìdájọ́ Gẹ̀hẹ́nà?*+
34 Torí èyí, mò ń rán àwọn wòlíì,+ àwọn amòye àtàwọn tó ń kọ́ni ní gbangba+ sí yín. Ẹ máa pa àwọn kan lára wọn,+ ẹ sì máa kàn wọ́n mọ́gi,* ẹ máa na àwọn kan lára wọn+ nínú àwọn sínágọ́gù yín, ẹ sì máa ṣe inúnibíni sí wọn+ láti ìlú dé ìlú,
35 kí ẹ lè jẹ̀bi ẹ̀jẹ̀ gbogbo àwọn olódodo tí wọ́n ta sílẹ̀ ní ayé, látorí ẹ̀jẹ̀ Ébẹ́lì+ olódodo dórí ẹ̀jẹ̀ Sekaráyà ọmọ Barakáyà, ẹni tí ẹ pa láàárín ibi mímọ́ àti pẹpẹ.+
36 Lóòótọ́ ni mo sọ fún yín, gbogbo nǹkan yìí máa wá sórí ìran yìí.
37 “Jerúsálẹ́mù, Jerúsálẹ́mù, ìlú tó ń pa àwọn wòlíì, tó sì ń sọ àwọn tí a rán sí i lókùúta,+ wo bí mo ṣe máa ń fẹ́ kó àwọn ọmọ rẹ jọ tó lọ́pọ̀ ìgbà, bí ìgbà tí àgbébọ̀ adìyẹ ń kó àwọn ọmọ rẹ̀ jọ sábẹ́ ìyẹ́ rẹ̀! Àmọ́ ẹ ò fẹ́ bẹ́ẹ̀.+
38 Ẹ wò ó! A ti pa ilé yín tì fún yín.*+
39 Torí mò ń sọ fún yín pé, ó dájú pé ẹ ò ní rí mi láti ìsinsìnyí títí ẹ fi máa sọ pé, ‘Ìbùkún ni fún ẹni tó ń bọ̀ ní orúkọ Jèhófà!’”*+
Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé
^ Tàbí “wọ́n fẹ àwọn akóló wọn.”
^ Tàbí “tó dáa jù.”
^ Tàbí “Olùkọ́.”
^ Ìyẹn, “ẹni tó gba ẹ̀sìn Júù.” Wo Àlàyé Ọ̀rọ̀.
^ Wo Àlàyé Ọ̀rọ̀.
^ Tàbí “kòkòrò abìyẹ́ tó ń mùjẹ̀.”
^ Tàbí “ìkónilẹ́rù.”
^ Tàbí “ibojì ìrántí.”
^ Wo Àlàyé Ọ̀rọ̀.
^ Tàbí “mọ́ òpó igi.” Wo Àlàyé Ọ̀rọ̀.
^ Tàbí kó jẹ́, “fi ilé yín sílẹ̀ fún yín ní ahoro.”