Àkọsílẹ̀ Mátíù 28:1-20
28 Lẹ́yìn Sábáàtì, nígbà tí ilẹ̀ ń mọ́ bọ̀ ní ọjọ́ kìíní ọ̀sẹ̀, Màríà Magidalénì àti Màríà kejì wá wo sàréè náà.+
2 Wò ó! ìmìtìtì ilẹ̀ kan tó lágbára ti ṣẹlẹ̀, torí áńgẹ́lì Jèhófà* ti sọ̀ kalẹ̀ láti ọ̀run, ó ti wá yí òkúta náà kúrò, ó sì jókòó sórí rẹ̀.+
3 Ìrísí rẹ̀ rí bíi mànàmáná, aṣọ rẹ̀ sì funfun bíi yìnyín.+
4 Àní ẹ̀rù rẹ̀ ba àwọn ẹ̀ṣọ́ náà, jìnnìjìnnì bá wọn, wọ́n sì kú sára.
5 Àmọ́ áńgẹ́lì náà sọ fún àwọn obìnrin náà pé: “Ẹ má bẹ̀rù, torí mo mọ̀ pé Jésù tí wọ́n kàn mọ́gi lẹ̀ ń wá.+
6 Kò sí níbí, torí a ti jí i dìde, bó ṣe sọ gẹ́lẹ́.+ Ẹ wá wo ibi tí wọ́n tẹ́ ẹ sí.
7 Kí ẹ tètè lọ sọ fún àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ pé a ti jí i dìde, torí ẹ wò ó! ó ń lọ sí Gálílì ṣáájú yín.+ Ẹ máa rí i níbẹ̀. Ẹ wò ó! Mo ti sọ fún yín.”+
8 Torí náà, wọ́n yára kúrò ní ibojì ìrántí náà, bí ẹ̀rù ṣe ń bà wọ́n, tínú wọn sì ń dùn gan-an, wọ́n sáré lọ ròyìn fún àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀.+
9 Wò ó! Jésù pàdé wọn, ó sì sọ pé: “Ẹ ǹlẹ́ o!” Wọ́n sún mọ́ ọn, wọ́n di ẹsẹ̀ rẹ̀ mú, wọ́n sì tẹrí ba* fún un.
10 Jésù wá sọ fún wọn pé: “Ẹ má bẹ̀rù! Ẹ lọ ròyìn fún àwọn arákùnrin mi, kí wọ́n lè lọ sí Gálílì, ibẹ̀ ni wọ́n ti máa rí mi.”
11 Bí wọ́n ṣe ń lọ, àwọn kan lára àwọn ẹ̀ṣọ́ náà+ lọ sínú ìlú, wọ́n sì ròyìn gbogbo ohun tó ṣẹlẹ̀ fún àwọn olórí àlùfáà.
12 Lẹ́yìn tí àwọn yìí kóra jọ pẹ̀lú àwọn àgbààgbà, tí wọ́n sì ti gbìmọ̀ pọ̀, wọ́n fún àwọn ọmọ ogun náà ní ẹyọ fàdákà tó pọ̀,
13 wọ́n sì sọ pé: “Kí ẹ sọ pé, ‘Àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ wá jí i gbé ní òru nígbà tí à ń sùn.’+
14 Tí èyí bá sì dé etí gómìnà, a máa ṣàlàyé ọ̀rọ̀ náà fún un,* kò ní sídìí láti da ara yín láàmú.”
15 Torí náà, wọ́n gba àwọn ẹyọ fàdákà náà, wọ́n sì ṣe ohun tí wọ́n ní kí wọ́n ṣe, ọ̀rọ̀ yìí sì tàn káàkiri láàárín àwọn Júù títí dòní yìí.
16 Àmọ́ àwọn ọmọ ẹ̀yìn mọ́kànlá (11) náà lọ sí Gálílì+ lórí òkè tí Jésù ṣètò pé kí wọ́n ti pàdé.+
17 Nígbà tí wọ́n rí i, wọ́n tẹrí ba* fún un, àmọ́ àwọn kan ń ṣiyèméjì.
18 Jésù sún mọ́ wọn, ó sì sọ fún wọn pé: “Gbogbo àṣẹ ní ọ̀run àti ayé la ti fún mi.+
19 Torí náà, ẹ lọ, kí ẹ máa sọ àwọn èèyàn gbogbo orílẹ̀-èdè di ọmọ ẹ̀yìn,+ ẹ máa batisí wọn+ ní orúkọ Baba àti ti Ọmọ àti ti ẹ̀mí mímọ́,
20 ẹ máa kọ́ wọn pé kí wọ́n máa pa gbogbo ohun tí mo pa láṣẹ fún yín mọ́.+ Ẹ wò ó! Mo wà pẹ̀lú yín ní gbogbo ọjọ́ títí dé ìparí ètò àwọn nǹkan.”*+
Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé
^ Tàbí “forí balẹ̀.”
^ Ní Grk., “yí i lérò pa dà.”
^ Tàbí “forí balẹ̀.”
^ Tàbí “àsìkò náà.” Wo Àlàyé Ọ̀rọ̀.