Àkọsílẹ̀ Mátíù 6:1-34
6 “Kí ẹ rí i pé ẹ ò ṣe òdodo yín níwájú àwọn èèyàn, torí kí wọ́n lè rí yín;+ àìjẹ́ bẹ́ẹ̀, ẹ ò ní rí èrè kankan lọ́dọ̀ Baba yín tó wà ní ọ̀run.
2 Torí náà, tí o bá ń ṣe ìtọrẹ àánú,* má ṣe fun kàkàkí ṣáájú ara rẹ, bí àwọn alágàbàgebè ṣe ń ṣe nínú àwọn sínágọ́gù àti láwọn ojú ọ̀nà, kí àwọn èèyàn lè kan sáárá sí wọn. Lóòótọ́ ni mo sọ fún yín, wọ́n ti gba èrè wọn ní ẹ̀kúnrẹ́rẹ́.
3 Àmọ́ tí ìwọ bá ń ṣe ìtọrẹ àánú, má ṣe jẹ́ kí ọwọ́ òsì rẹ mọ ohun tí ọwọ́ ọ̀tún rẹ ń ṣe,
4 kí ìtọrẹ àánú tí o ṣe lè wà ní ìkọ̀kọ̀. Baba rẹ tó ń rí ohun tó wà ní ìkọ̀kọ̀ sì máa san ọ́ lẹ́san.+
5 “Bákan náà, tí ẹ bá ń gbàdúrà, ẹ má ṣe bíi ti àwọn alágàbàgebè,+ torí tí wọ́n bá ń gbàdúrà, wọ́n máa ń fẹ́ dúró nínú àwọn sínágọ́gù àti ní ìkóríta àwọn ọ̀nà tó bọ́ sí gbangba, kí àwọn èèyàn lè rí wọn.+ Lóòótọ́ ni mo sọ fún yín, wọ́n ti gba èrè wọn ní ẹ̀kúnrẹ́rẹ́.
6 Àmọ́ tí o bá ń gbàdúrà, lọ sínú yàrá àdáni rẹ, lẹ́yìn tí o bá ti ilẹ̀kùn rẹ, gbàdúrà sí Baba rẹ tó wà ní ìkọ̀kọ̀.+ Baba rẹ tó ń rí ohun tó wà ní ìkọ̀kọ̀ sì máa san ọ́ lẹ́san.
7 Tí o bá ń gbàdúrà, má sọ ohun kan náà ní àsọtúnsọ, bí àwọn èèyàn orílẹ̀-èdè ṣe máa ń ṣe, torí wọ́n rò pé àdúrà àwọn máa gbà torí bí wọ́n ṣe ń lo ọ̀rọ̀ púpọ̀.
8 Torí náà, ẹ má ṣe bíi tiwọn, torí Baba yín mọ àwọn ohun tí ẹ nílò,+ kódà kí ẹ tó béèrè lọ́wọ́ rẹ̀.
9 “Torí náà, ẹ máa gbàdúrà lọ́nà yìí:+
“‘Baba wa tí ń bẹ ní ọ̀run, kí orúkọ+ rẹ di mímọ́.*+
10 Kí Ìjọba rẹ dé.+ Kí ìfẹ́ rẹ+ ṣẹ ní ayé,+ bíi ti ọ̀run.
11 Fún wa ní oúnjẹ òòjọ́ wa lónìí;+
12 kí o sì dárí àwọn gbèsè wa jì wá, bí àwa náà ṣe dárí ji àwọn tó jẹ wá ní gbèsè.+
13 Má sì mú wa wá sínú ìdẹwò,+ ṣùgbọ́n gbà wá* lọ́wọ́ ẹni burúkú náà.’+
14 “Torí tí ẹ bá dárí ẹ̀ṣẹ̀ àwọn èèyàn jì wọ́n, Baba yín ọ̀run náà máa dárí jì yín;+
15 àmọ́ tí ẹ kò bá dárí ẹ̀ṣẹ̀ àwọn èèyàn jì wọ́n, Baba yín ò ní dárí àwọn ẹ̀ṣẹ̀ yín jì yín.+
16 “Tí ẹ bá ń gbààwẹ̀,+ ẹ má fajú ro mọ́ bíi ti àwọn alágàbàgebè, torí wọ́n máa ń bojú jẹ́* kí àwọn èèyàn lè rí i pé wọ́n ń gbààwẹ̀.+ Lóòótọ́ ni mo sọ fún yín, wọ́n ti gba èrè wọn ní ẹ̀kúnrẹ́rẹ́.
17 Àmọ́ tí ìwọ bá ń gbààwẹ̀, fi òróró pa orí rẹ, kí o sì bọ́jú rẹ,
18 kó má bàa hàn sí àwọn èèyàn pé ò ń gbààwẹ̀, Baba rẹ tó wà ní ìkọ̀kọ̀ nìkan ni kó hàn sí. Baba rẹ tó ń rí ohun tó wà ní ìkọ̀kọ̀ sì máa san ọ́ lẹ́san.
19 “Ẹ má to ìṣúra pa mọ́ fún ara yín ní ayé mọ́,+ níbi tí òólá* ti ń jẹ nǹkan run, tí nǹkan ti ń dípẹtà, tí àwọn olè ń fọ́lé, tí wọ́n sì ń jalè.
20 Kàkà bẹ́ẹ̀, ẹ to ìṣúra pa mọ́ fún ara yín ní ọ̀run,+ níbi tí òólá kò ti lè jẹ nǹkan run, tí nǹkan ò ti lè dípẹtà,+ tí àwọn olè kò ti lè fọ́lé, kí wọ́n sì jalè.
21 Torí ibi tí ìṣúra yín bá wà, ibẹ̀ ni ọkàn yín náà máa wà.
22 “Ojú ni fìtílà ara.+ Tí ojú rẹ bá mú ọ̀nà kan,* gbogbo ara rẹ máa mọ́lẹ̀ yòò.*
23 Àmọ́ tí ojú rẹ bá ń ṣe ìlara,*+ gbogbo ara rẹ máa ṣókùnkùn. Tó bá jẹ́ òkùnkùn ni ìmọ́lẹ̀ tó wà nínú rẹ lóòótọ́, òkùnkùn yẹn mà pọ̀ o!
24 “Kò sí ẹni tó lè sin ọ̀gá méjì; àfi kó kórìíra ọ̀kan, kó sì nífẹ̀ẹ́ ìkejì+ tàbí kó fara mọ́ ọ̀kan, kó má sì ka ìkejì sí. Ẹ ò lè sin Ọlọ́run àti Ọrọ̀.+
25 “Torí náà, mo sọ fún yín pé: Ẹ yéé ṣàníyàn+ nípa ẹ̀mí* yín, ní ti ohun tí ẹ máa jẹ tàbí tí ẹ máa mu tàbí nípa ara yín, ní ti ohun tí ẹ máa wọ̀.+ Ṣé ẹ̀mí* ò ṣe pàtàkì ju oúnjẹ lọ ni, tí ara sì ṣe pàtàkì ju aṣọ lọ?+
26 Ẹ fara balẹ̀ kíyè sí àwọn ẹyẹ ojú ọ̀run;+ wọn kì í fúnrúgbìn tàbí kárúgbìn tàbí kí wọ́n kó nǹkan jọ sínú ilé ìkẹ́rùsí, síbẹ̀ Baba yín ọ̀run ń bọ́ wọn. Ṣé ẹ ò wá níye lórí jù wọ́n lọ ni?
27 Èwo nínú yín ló lè fi ìgbọ̀nwọ́* kan kún ìwàláàyè rẹ̀, tó bá ń ṣàníyàn?+
28 Bákan náà, kí ló dé tí ẹ̀ ń ṣàníyàn nípa ohun tí ẹ máa wọ̀? Ẹ kẹ́kọ̀ọ́ lára àwọn òdòdó lílì inú pápá, bí wọ́n ṣe ń dàgbà; wọn kì í ṣe làálàá, wọn kì í sì í rànwú;*
29 àmọ́ mò ń sọ fún yín pé, a ò ṣe Sólómọ́nì+ pàápàá lọ́ṣọ̀ọ́ nínú gbogbo ògo rẹ̀ bí ọ̀kan lára àwọn yìí.
30 Tó bá jẹ́ pé báyìí ni Ọlọ́run ṣe ń wọ ewéko pápá láṣọ, tó wà lónìí, tí a sì sọ sínú ààrò lọ́la, ṣé kò wá ní wọ̀ yín láṣọ jù bẹ́ẹ̀ lọ, ẹ̀yin tí ìgbàgbọ́ yín kéré?
31 Torí náà, ẹ má ṣàníyàn láé,+ kí ẹ wá sọ pé, ‘Kí la máa jẹ?’ tàbí, ‘Kí la máa mu?’ tàbí, ‘Kí la máa wọ̀?’+
32 Torí gbogbo nǹkan yìí ni àwọn orílẹ̀-èdè ń wá lójú méjèèjì. Baba yín ọ̀run mọ̀ pé ẹ nílò gbogbo nǹkan yìí.
33 “Torí náà, ẹ máa wá Ìjọba náà àti òdodo Rẹ̀ lákọ̀ọ́kọ́, gbogbo nǹkan mìíràn yìí la sì máa fi kún un fún yín.+
34 Torí náà, ẹ má ṣàníyàn láé nípa ọ̀la,+ torí ọ̀la máa ní àwọn àníyàn tirẹ̀. Wàhálà ọjọ́ kọ̀ọ̀kan ti tó fún un.
Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé
^ Tàbí “ìtọrẹ fún àwọn aláìní.” Wo Àlàyé Ọ̀rọ̀.
^ Tàbí “kí a bọ̀wọ̀ fún orúkọ rẹ; kí a ka orúkọ rẹ sí mímọ́.”
^ Tàbí “dá wa nídè.”
^ Tàbí “wọn kì í túnra ṣe.”
^ Tàbí “kòkòrò.”
^ Tàbí “bá ríran kedere.”
^ Tàbí “kún fún ìmọ́lẹ̀.”
^ Ní Grk., “bá burú.”
^ Tàbí “ọkàn.”
^ Tàbí “ọkàn.”
^ Wo Àfikún B14.
^ Tàbí “ṣe òwú.”