Míkà 4:1-13
4 Ní apá ìgbẹ̀yìn àwọn ọjọ́,*Òkè ilé Jèhófà+
Máa fìdí múlẹ̀ gbọn-in sórí àwọn òkè,A sì máa gbé e ga ju àwọn òkè kéékèèké lọ,Àwọn èèyàn á sì máa rọ́ lọ síbẹ̀.+
2 Ọ̀pọ̀ orílẹ̀-èdè máa lọ, wọ́n á sì sọ pé:
“Ẹ wá, ẹ jẹ́ ká lọ sórí òkè Jèhófà,Sí ilé Ọlọ́run Jékọ́bù.+
Ó máa kọ́ wa ní àwọn ọ̀nà rẹ̀,A ó sì máa rìn ní àwọn ọ̀nà rẹ̀.”
Torí òfin* máa jáde láti Síónì,Ọ̀rọ̀ Jèhófà sì máa jáde láti Jerúsálẹ́mù.
3 Ó máa ṣe ìdájọ́ láàárín ọ̀pọ̀ èèyàn,+Ó sì máa yanjú* ọ̀rọ̀ àwọn orílẹ̀-èdè alágbára tí ọ̀nà wọn jìn.
Wọ́n máa fi idà wọn rọ ohun ìtúlẹ̀,Wọ́n sì máa fi ọ̀kọ̀ wọn rọ ohun ìrẹ́wọ́ ọ̀gbìn.+
Àwọn orílẹ̀-èdè kò ní yọ idà sí ara wọn mọ́,Wọn ò sì ní kọ́ṣẹ́ ogun mọ́.+
4 Kálukú wọn máa jókòó* lábẹ́ àjàrà rẹ̀ àti lábẹ́ igi ọ̀pọ̀tọ́ rẹ̀,+Ẹnì kankan ò sì ní dẹ́rù bà wọ́n,+Torí Jèhófà Ọlọ́run àwọn ọmọ ogun ló fi ẹnu ara rẹ̀ sọ ọ́.
5 Gbogbo èèyàn yóò máa rìn ní orúkọ ọlọ́run wọn,Àmọ́ àwa yóò máa rìn ní orúkọ Jèhófà Ọlọ́run wa+ títí láé àti láéláé.
6 Jèhófà kéde pé, “Ní ọjọ́ yẹn,Èmi yóò kó ẹni* tó ń tiro jọ,Èmi yóò sì kó ẹni tó ti fọ́n ká jọ,+Pẹ̀lú àwọn tí mo ti fìyà jẹ.
7 Èmi yóò mú kí ẹni* tó ń tiro ṣẹ́ kù,+Èmi yóò sì sọ ẹni tí wọ́n ti mú lọ sí ọ̀nà tó jìn di orílẹ̀-èdè alágbára;+Jèhófà yóò sì jọba lé wọn lórí ní Òkè Síónì,Láti ìsinsìnyí lọ àti títí láé.
8 Ní ti ìwọ ilé gogoro tí agbo ẹran wà,Òkìtì ọmọbìnrin Síónì,+Ìjọba àkọ́kọ́* yóò wá sọ́dọ̀ rẹ, àní yóò wá,+Ìjọba ọmọbìnrin Jerúsálẹ́mù.+
9 Kí ló wá dé tí o fi ń pariwo?
Ṣé o kò ní ọba ni,Àbí ẹni tó ń gbà ọ́ nímọ̀ràn ti ṣègbé,Tí ara fi ń ro ọ́, bí obìnrin tó ń rọbí?+
10 Máa yí nínú ìrora, ọmọbìnrin Síónì, kí o sì kérora,Bí obìnrin tó ń rọbí,Torí o máa kúrò ní ìlú, wàá sì lọ gbé ní pápá.
O máa lọ jìnnà dé Bábílónì,+Ibẹ̀ ni wàá ti rí ìdáǹdè;+Ibẹ̀ ni Jèhófà yóò ti rà ọ́ pa dà lọ́wọ́ àwọn ọ̀tá rẹ.+
11 Ọ̀pọ̀ orílẹ̀-èdè máa kóra jọ láti dojú ìjà kọ ọ́;Wọ́n á sọ pé, ‘Ẹ jẹ́ kó di aláìmọ́,Ká sì fi ojú wa rí bí èyí ṣe máa ṣẹlẹ̀ sí Síónì.’
12 Àmọ́ wọn ò mọ ohun tí Jèhófà ń rò,Wọn ò sì mọ ohun tó ní lọ́kàn;*Torí ó máa tò wọ́n jọ bí ọkà tí wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ gé sílẹ̀ níbi ìpakà.
13 Dìde, kí o sì pakà, ìwọ ọmọbìnrin Síónì;+Torí èmi yóò sọ ìwo rẹ di irin,Màá sọ àwọn pátákò rẹ di bàbà,Ìwọ yóò sì pa ọ̀pọ̀ èèyàn run.+
Ìwọ yóò fún Jèhófà ní ohun tí wọ́n fi èrú kó jọ,Ìwọ yóò sì fún Olúwa gbogbo ilẹ̀ ayé ní àwọn ohun àmúṣọrọ̀ wọn.”+
Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé
^ Tàbí “Ní àwọn ọjọ́ ìkẹyìn.”
^ Tàbí “ìtọ́ni.”
^ Tàbí “Ó sì máa ṣàtúnṣe.”
^ Tàbí “gbé.”
^ Ní Héb., “obìnrin.”
^ Ní Héb., “obìnrin.”
^ Tàbí “àtijọ́.”
^ Tàbí “ète rẹ̀.”